languageIcon
search
search
Àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe ní ojoojúmọ́ àti alaalẹ́ Àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe ní ojoojúmọ́ àti alaalẹ́ ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 4 Àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ )

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

اللَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ

Wọ́n ṣe kíka ’Āyatul-KursiyySunnah ní ìgbà tí a bá fẹ́ sùn; ìṣọ́ wà níbẹ̀ fún un kúrò lọ́wọ́ èṣù títí tí yóò fi mọ́jú.

Ìtọ́ka rẹ̀ ni : Ìtàn Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – pẹ̀lú ẹni tó máa ń jí nínú Zakāh.  Ó wà nínú Ḥadīth náà pé Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ fún mi pé: “Kín ni ẹni tí ó mú nígbèkùn ṣe lálẹ́ àná”? Mo dáhùn pé: Ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun, ó dá àbá pé òun yóò kọ́ mi ní àwọn gbólóhùn kan tí Ọlọ́hun yóò ṣe mí ní àǹfààní pẹ̀lú rẹ̀, nítorí náà mo dá a sílẹ̀.

Ó sọ pé: “Kín ni àwọn gbólóhùn náà?” Mo dáhùn pé: Ó sọ fún mi pé; nígbà tí ó bá darí síbi ibùsùn rẹ, ka ’Āyatul-Kursiyy, láti ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ títí tí wàá fi parí ’āyah náà {Allāhu lā ’ilāha ’illā huwal-Ḥayyul-Qayyūm (Ọlọ́hun! Kò sí ọlọhun mìíràn tí ó ni ẹ̀tọ́ sí ìjọsìn lẹ́yìn Rẹ̀, Oluṣẹ̀mí (fún ara Rẹ̀), Olùdádúró (fún ara Rẹ̀)}. Ó tún sọ fún mi pé: Olùṣọ́ kò ní yé máa bẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, èṣù kankan kò sì ní súnmọ́ ọ títí tí wàá fi mọ́jú, wọ́n sì jẹ́ ẹni tó le ṣe ojú kòkòrò oore jùlọ. Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Dájúdájú òdodo ni ó sọ fún ọ, ṣùgbọ́n ògbóǹtarìgì òpùrọ́ ni. Ìrẹ Abū Hurayrah! Ṣé ó mọ ẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ láti òru ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn? Ó sọ wí pé: Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó (Ànábì) sọ pé: Èṣù níyẹn”. Al-Bukhārī gbà á wá làìsọ gbogbo àwọn ẹni tó wà ní ojúpọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú òǹkà (2311), An-Nasā’ī sọ gbogbo àwọn ẹni tó wà ní ojúpọ̀nà rẹ̀, nínú As-Sunanul-Kubrā, pẹ̀lú òǹkà (10795).

 

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

Nítorí Ḥadīth tí Abū Mas‘ūd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá  pé; Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun  – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Ẹni kẹ́ni ka ’āyah méjèèjì yìí tó wà ní ìgbẹ̀yìn Sūratul-Baqarah ní òru ọjọ́ kan, àwọn méjèèjì yóò tó oAl-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (4008), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (807). ’Āyah méjèèjì tó wà ní ìgbẹ̀yìn Sūratul-Baqarah kì í ṣe ara àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe nígbà tí a bá fẹ́ sùn bíi ohun tó ṣẹ̀ṣà pẹ̀lú àsìkò yìí, ṣúgbọ́n ó jẹ̀ ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe ní alẹ́. Nítorí náà ẹni tí kò bá ka méjèèjì ní alẹ́, tí ó sì rántí rẹ̀ nígbà tó fẹ́ sùn, kí ó rí i pé òun ka méjèèjì nígbà náà.

Àwọn onímímọ̀ yapa ẹnu nípa ìtumọ̀ (àwọn méjèèjì yóò tó o) :

Àwọn kan sọ pé: Wọn yóò tó o níbi dídìde kírun lóru. Àwọn mìíràn sì wí pé: Wọn yóò tó o lọ́wọ́ èṣù

Àwọn mìíràn sọ pé: Wọn yóò tó o kúrò níbi àwọn àbùjẹkù. Ó sì le túmọ̀ sí gbogbo ìtumọ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí An-Nawawī ­– kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – ti sọ. Wo: Sharḥu An-Nawawī fún tírà Muslim, Ḥadīth (808), àkòrí ọ̀rọ̀ nípa ọlá tí ń bẹ fún Al-Fatiḥah àti àwọn ìgbẹ̀yìn Sūratul-Baqarah...

 

.......

3 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

اللَّهُمَّ رَبَّ السَّمَاوَاتِ وَرَبَّ الأَرْضِ وَرَبَّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ، رَبَّنَا وَرَبَّ كُلِّ شَيْءٍ، فَالِقَ الْحَبِّ وَالنَّوَى، وَمُنْزِلَ التَّوْرَاةِ وَالإِنْجِيلِ وَالْفُرْقَانِ، أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ كُلِّ شَيْءٍ أَنْتَ آخِذٌ بِنَاصِيَتِهِ، اللَّهُمَّ أَنْتَ الأَوَّلُ فَلَيْسَ قَبْلَكَ شَيْءٌ ، وَأَنْتَ الآخِرُ فَلَيْسَ بَعْدَكَ شَيْءٌ، وَأَنْتَ الظَّاهِرُ فَلَيْسَ فَوْقَكَ شَيْءٌ، وَأَنْتَ الْبَاطِنُ فَلَيْسَ دُونَكَ شَيْءٌ، اقْضِعَنَّا الدَّيْنَ وَأَغْنِنَا مِنَ الْفَقْرِ

Allāhumma Rabbas-samāwāti waRabaal-’arḍ waRabbal-‘arshil-‘aẓīm, Rabbanā warabba kulli shay’, Fāliqal-ḥabbi wan-nawā, WaMunzilat-Tawrati wal-’Injīli wal-furqān, ’a‘ūdhu bika min sharri kulli shay’in ’Anta ’ākhidhun bināṣiyatih. Allāhumma ’Antal-’Awwal, falaysa qablaka shay’, wa’Antal-’Ākhir, falaysa ba‘daka shay’, wa’Antaẓ-Ẓāhir falaysa fawqaka shay’, wa’Antal-bāṭin, falaysa dūnaka shay’, iqḍi ‘annad-dayna wa’aghninā minal-faqr (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba àwọn sánmà, Ọlọ́hun Ọba ilẹ̀, Ọlọ́hun Ọba Ìtẹ́-ọlá tí ó tóbi, Ọlọ́hun Ọba wa àti Ọlọ́hun Ọba gbogbo nǹkan. Olùmú hóró ìrúgbìn àti kóro èso dàbínù hù jàde, Olùsọ At-Tawrah, Al-Injīl àti Al-Qur’ān tí ń ṣe òpinyà láààrin irọ́ àti òdodo kalẹ̀. Mo ń wá ìṣọ̀ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú gbogbo nǹkan tí Ìwọ yóò gbá àṣóńṣó rẹ̀ mú. Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Àkọ̀kọ́, kò sí nǹkankan síwájú Rẹ, Ìwọ ni Ìgbẹ̀yìn, kò sí nǹkankan lẹ́yìn Rẹ, Ìwọ ni Ẹni Gíga, kò sí nǹkankan lókè Rẹ, Ìwọ ni Ẹni sísúnmọ, kò sí nǹkankan tí ó súnmọ́ jù Ọ́ lọ. Bá wa san gbèsè wa, sì rọ̀ wá lọ́rọ̀ kúrò níbi òsì)” Muslim gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (2713).

.......

100 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

سبحان الله (33)، الحمد لله (33)، الله أكبر (34) م

Nínú Sunnah ni kí ó ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun nígbà  mẹtàlélọ́gbọ̀n, kí ó ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – nígbà mẹtàlélọ́gbọ̀n, kí ó sì gbé Ọlọ́hun tóbi nígbà mẹrìnlélọ́gbọ̀n, nígbà tó bá fẹ́ sùn. Èyí ní ọlá tó tóbi, òhun náà sì ni pé:  Dájúdájú ó máa ń fún ara èèyàn lágbara nínú ojú ọjọ́ rẹ̀.

Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth ti ‘Aliyy –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: Dájúdájú Fāṭimah ráhùn nípa ohun tí ojú rẹ̀ ń rí nípa àpá ọmọlọ tí ó ń wà lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn ọrọ̀-ogun kan sì ti tẹ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – lọ́wọ́. Nítorí náà ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò bá a nílé. Ó bá ‘Ā’ishah pàdé, ó sì ṣe àlàyé fún un. Nígbà tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – padà dé, ‘Ā’ishah ṣàlàyé fún un nípa wíwá tí Fāṭimah wá bá a. Nítorí náà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – wá sí ọ̀dọ̀ wa, a sì ti fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lórí ibùsùn wa, ni a bá fẹ́ dìde láti lọ pàde rẹ̀, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sì sọ wí pé: “Ẹ dúró sí ààyè tí ẹ̀yin méjèèjì wà”. Ó sì jókòó sí ààrin wa títí tí mo fi fura mọ títutù gìgísẹ̀ rẹ̀ ní àyà mi, lẹ́yìn náà ó wí pé: Ṣé kí ń kọ yín ní ohun tí ó ní oore ju ohun tí ẹ̀yin méjèèjí béèrè fún lọ? Nígba tí ẹ bá ti fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lórí ibùsùn yín tán, kí ẹ gbé Ọlọ́hun tóbi (pẹ̀lú sísọ pé: Allāhu ’Akbar) nígbà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, kí ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Un (pẹ̀lú sísọ pé: Subḥānallāh) nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, kí ẹ sì ṣe ẹyìn fún Un (pẹ̀lú sísọ pé: Al-ḥamdulillāh) nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Èyí lóore fun yín ju ọmọ-ọ̀dọ̀ lọ”.  Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3705), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2727).

Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn: ‘Aliyy – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- sọ wí pé: Mi ó fi ṣíṣe é sílẹ̀ láti ìgbà tí mo ti gbọ́ ọ láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Wọ́n bi í léèrè pé: Ṣé kódà ní alẹ́ ọjọ́ ogun Ṣifīn? Ó dáhùn pé: Kódà ní alẹ́ ọjọ́ ogun ṢifīnAl-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5362), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2727).

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْلَمْتُ وَجْهِي إِلَيْكَ، وَفَوَّضْتُ أَمْرِي إِلَيْكَ، وَأَلْجَأْتُ ظَهْرِي إِلَيْكَ، رَغْبَةً وَرَهْبَةً إِلَيْكَ. لاَ مَلْجَأَ وَلاَ مَنْجَا مِنْكَ إِلاَّ إِلَيْكَ، آمَنْتُ بِكِتَابِكَ الَّذِي أَنْزَلْتَ، وَبِنَبِيِّكَ الَّذِي أَرْسَلْتَ

Allāhumma ’innī ’aslamtu wajhī ’ilayk, wafawwaḍtu ’amrī ’ilayk, wa’alja’tu ẓahrī ’ilayk, raghbatan warahbatan ’ilayk, lā malja’ walā manjā minka ’illa ’ilayk, ’amantu bikitābikal-ladhī ’anzalt, wabinabiyyikal-ladhī ’arsalt (Ìrẹ Ọlọ́hun! Mo jọ̀wọ́ àdojúkọ mi sílẹ̀ fún Ọ, mo sì fa ọ̀rọ̀ mi lé Ọ lọ́wọ́, mo sì fi ẹ̀yìn (ọ̀ràn) mi tí sí Ọ, níti ìrankàn wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ àti ìbẹ̀rù Rẹ. Kò sí ọ̀nà àbáyọ, kò sì sí àsálà mọ́ Ọ lọ́wọ́ àyàfi wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Mo gba Tírà Rẹ eléyìí tí O sọ̀kalẹ̀ gbọ́ lódodo àti Òjíṣẹ́ Rẹ eléyìí tí O rán níṣẹ́)”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (247), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2710). Ní ìparí Ḥadīth yìí, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Jẹ́ kí wọ́n jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wàá sọ gbẹ̀yìn. Tí o bá wáá kú ní òru ọjọ́ rẹ yìí, o kú lórí Àdámọ́ ẹ̀sìn Ọlọ́hun”. Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Muslim gbà wá: Tí ilẹ̀ bá sì mọ́ bá ọ láyé, ilẹ̀ yóò mọ́ bá ọ lórí dáadáa”.  

Nínú Ḥadīth yìí, àlàyé nípa Sunnah mìíràn wà níbẹ̀, èyí ni: Kí ó jẹ́ kí ìrántí Ọlọ́hun jẹ́ ohun tí yóò sọ gbẹ̀yìn síwájí kí ó tó sùn. Ẹ̀bùn tó tóbi wà níbẹ̀, tí ó bá jẹ́ wí pé wọ́n kádàrá kí ó kù ní òru ọjọ́ rẹ̀ yìí. Nítorí pé dájúdájú yóò wà nínú àwọn tó kú lórí Àdámọ́ ẹ̀sìn Ọlọ́hun, èyí tó túmọ̀ sí pé: Dájúdájú ó kú lórí Sunnah, lórí ìlànà ẹ̀sìn Ànábì Ibrāhīm – kí ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ní ẹni tó ṣẹ́rí kúrò níbi ẹbọ. Tí ó bá sì jí sáyé, dájúdájú yóò jí sáyé lórí dáadáa níbi arísìkí rẹ̀ àti iṣẹ́ rẹ̀. Ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó kó gbogbo nǹkan sínú, ó kó ohun tó síwájú àti ohun tó yàtọ̀ sí i sínú – Ọlọ́hun ni Ó mọ̀ jùlọ –.

 

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

اللَّهُمَّ أَنْتَ رَبِّي لَا إِلَهَ إِلَّا أَنْتَ خَلَقْتَنِي وَأَنَا عَبْدُكَ وَأَنَا عَلَى عَهْدِكَ وَوَعْدِكَ مَا اسْتَطَعْتُ أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ مَا صَنَعْتُ أَبُوءُ لَكَ بِنِعْمَتِكَ عَلَيَّ وَأَبُوءُ لَكَ بِذَنْبِي فَاغْفِرْ لِي فَإِنَّهُ لَا يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلَّا أَنْتَ

Nínú ohun tó pàtàkì kí a pe àkíyèsí ara wa sí ni: Ìrántí Ọlọ́hun pàtàkì, èyí tó máa ń ṣe sábàbí ọlá tó tóbi, Ọlọ́hun, Ọba tí Ó ga, Ọba tí Ó tóbi – gbígbọn-n-gbọ́n ni fún títóbi Rẹ̀ –. Èyí ni ohun tó wá nínú Ṣaḥīḥul-Bukhārī, nínú Ḥadīth Shaddād ọmọ ’Aws – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pé: “Ọ̀gá àdúà tí a fi máa ń tọrọ àforíjìn ni kí ó sọ pé: Allāhumma ’Anta Rabbī lā ’ilāha ’illā ’Ant, khalaqtanī wa’ana ‘abduk, wa’ana ‘alā ‘ahdika wawa‘dika mastaṭa‘t, ’a‘ūdhu bika min sharri mā ṣana‘t, ’abū’u laka bini‘matika ‘alayy, wa’abū’u bidhanbī, faghfir lī fa’innahu lā yaghfirudh-dhunūba ’illā ’Ant  (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Ọlọ́hun Ọba mi, kò sí Ọlọ́hun kan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ nìkan. O dá mi, àti pé èmi jẹ́ ẹrúsìn fún Ọ. Èmi sì ń bẹ lórí ìpínhùn Rẹ àti àdéhùn Rẹ bí mo ti lágbára mọ. Mo wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú ohun tí mo ṣe. Mo gbà fún Ọ pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ tí O se fún mi, mo sì mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ṣe àforíjì fún mi. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó le ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àyàfi Ìwọ nìkan). Ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo sí i ní alẹ́, tí ó wá kú ní òru ọjọ́ náà, síwájú kí ó tó jí ní àárọ̀, yóò wọ ÀlùjánńnàAl-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6306).

.......