1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
اللَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ
Wọ́n ṣe kíka ’Āyatul-Kursiyy ní Sunnah ní ìgbà tí a bá fẹ́ sùn; ìṣọ́ wà níbẹ̀ fún un kúrò lọ́wọ́ èṣù títí tí yóò fi mọ́jú.
Ìtọ́ka rẹ̀ ni : Ìtàn Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – pẹ̀lú ẹni tó máa ń jí nínú Zakāh. Ó wà nínú Ḥadīth náà pé Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ fún mi pé: “Kín ni ẹni tí ó mú nígbèkùn ṣe lálẹ́ àná”? Mo dáhùn pé: Ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun, ó dá àbá pé òun yóò kọ́ mi ní àwọn gbólóhùn kan tí Ọlọ́hun yóò ṣe mí ní àǹfààní pẹ̀lú rẹ̀, nítorí náà mo dá a sílẹ̀.
Ó sọ pé: “Kín ni àwọn gbólóhùn náà?” Mo dáhùn pé: Ó sọ fún mi pé; nígbà tí ó bá darí síbi ibùsùn rẹ, ka ’Āyatul-Kursiyy, láti ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ títí tí wàá fi parí ’āyah náà {Allāhu lā ’ilāha ’illā huwal-Ḥayyul-Qayyūm (Ọlọ́hun! Kò sí ọlọhun mìíràn tí ó ni ẹ̀tọ́ sí ìjọsìn lẹ́yìn Rẹ̀, Oluṣẹ̀mí (fún ara Rẹ̀), Olùdádúró (fún ara Rẹ̀)}. Ó tún sọ fún mi pé: Olùṣọ́ kò ní yé máa bẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, èṣù kankan kò sì ní súnmọ́ ọ títí tí wàá fi mọ́jú, wọ́n sì jẹ́ ẹni tó le ṣe ojú kòkòrò oore jùlọ. Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Dájúdájú òdodo ni ó sọ fún ọ, ṣùgbọ́n ògbóǹtarìgì òpùrọ́ ni. Ìrẹ Abū Hurayrah! Ṣé ó mọ ẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ láti òru ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn? Ó sọ wí pé: Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó (Ànábì) sọ pé: Èṣù níyẹn”. Al-Bukhārī gbà á wá làìsọ gbogbo àwọn ẹni tó wà ní ojúpọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú òǹkà (2311), An-Nasā’ī sọ gbogbo àwọn ẹni tó wà ní ojúpọ̀nà rẹ̀, nínú As-Sunanul-Kubrā, pẹ̀lú òǹkà (10795).
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
Nítorí Ḥadīth tí Abū Mas‘ūd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Ẹni kẹ́ni tó bá ka ’āyah méjèèjì yìí tó wà ní ìgbẹ̀yìn Sūratul-Baqarah ní òru ọjọ́ kan, àwọn méjèèjì yóò tó o” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (4008), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (807). ’Āyah méjèèjì tó wà ní ìgbẹ̀yìn Sūratul-Baqarah kì í ṣe ara àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe nígbà tí a bá fẹ́ sùn bíi ohun tó ṣẹ̀ṣà pẹ̀lú àsìkò yìí, ṣúgbọ́n ó jẹ̀ ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe ní alẹ́. Nítorí náà ẹni tí kò bá ka méjèèjì ní alẹ́, tí ó sì rántí rẹ̀ nígbà tó fẹ́ sùn, kí ó rí i pé òun ka méjèèjì nígbà náà.
Àwọn onímímọ̀ yapa ẹnu nípa ìtumọ̀ (àwọn méjèèjì yóò tó o) :
Àwọn kan sọ pé: Wọn yóò tó o níbi dídìde kírun lóru. Àwọn mìíràn sì wí pé: Wọn yóò tó o lọ́wọ́ èṣù
Àwọn mìíràn sọ pé: Wọn yóò tó o kúrò níbi àwọn àbùjẹkù. Ó sì le túmọ̀ sí gbogbo ìtumọ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí An-Nawawī – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – ti sọ. Wo: Sharḥu An-Nawawī fún tírà Muslim, Ḥadīth (808), àkòrí ọ̀rọ̀ nípa ọlá tí ń bẹ fún Al-Fatiḥah àti àwọn ìgbẹ̀yìn Sūratul-Baqarah...
3 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: “Nígbà tí Ànábí – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bá bọ́ sórí ìbùsùn rẹ̀, ní gbogbo alẹ́, yóò tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ méjèèjì papọ̀, lẹ́yìn náà yóò tutọ́ sí wọn, yóò sí ké sí àwọn méjèèjì: {Qul Huwallāhu ’Aḥad},{Qul ’a‘ūdhu biRabbil-falaq} àti {Qul ’a‘ūdhu biRabbin-nās}, lẹ́yìn náà yóò fi méjèèjì pa ohun tí ó bá lágbara nínú ara rẹ̀, yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orí rẹ̀, ojú rẹ̀ àti iwájú ara rẹ̀, yóò ṣe bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta” Al-Bukhārī gbà á wá (5017).
A ó ṣe àǹfààní níbi Ḥadīth tó síwájú yìí pé: Dájúdájú Ànábí – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – máa ń lo Sunnah yìí ní gbogbo òru, nítorí ọ̀rọ̀ tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ pé: “Ní gbogbo òru”, àti pé dájúdájú ẹni tó bá fẹ́ lo Sunnah yìí yóò pa àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ méjèèjì papọ̀, lẹ́yìn náà yóò tutọ́ sí wọn pẹ̀lú kíké Sūratul-’Ikhlāṣ, àti Sūrah méjèèjì tí a fi máa ń wá ìṣọ́, lẹ́yìn náà yóò pa ohun tí ó bá lágbara nínú ara rẹ̀, yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orí rẹ̀ àti ojú rẹ̀, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta.
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
Nítorí Ḥadīth tí ‘Urwah ọmọ Nawfal gbà wá láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – pé: “Dájúdájú Ànábí – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ fún Nawfal pé: “Ka {Qul Yā ’ayyuhal-Kāfirūn}, lẹ́yìn náà sùn nígbà tí o bá parí rẹ̀, nítorí pé dájúdájú ó jẹ́ ìbọ́pá-bọ́sẹ̀ kúrò níbi ẹbọ” Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (21934), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5055), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3403), Al-Albānī – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sì kà á sí ẹ̀gbàwá tó dára.
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
اللَّهُمَّ خَلَقْتَ نَفْسِي وَأَنْتَ تَوَفَّاهَا، لَكَ مَمَاتُهَا وَمَحْيَاهَا، إِنْ أَحْيَيْتَهَا فَاحْفَظْهَا، وَإِنْ أَمَتَّهَا فَاغْفِرْ لَهَا، اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ الْعَافِيَةَ
“Allāhumma khalaqta nafsī wa’Anta tawaffāhā, laka mamātuhā wamaḥyāhā ’in ’aḥyaytahā faḥfaẓhā, wa’in amattahā faghfir lahā. Allāhumma ’innī ’as’alukal-‘āfiyah (Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú Ìwọ ni O dá ẹ̀mí mi, Ìwọ náà ni Oó sì pa á. Ìwọ ni O ni ikú rẹ̀ àti ìṣẹ̀mí rẹ̀. Tí O bá yè é, yáa ṣọ́ ọ. Tí O bá sì pa á, yáa ṣe àforíjìn fún un. Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń tọrọ àlááfíà ní ọ̀dọ̀ Rẹ)”. Muslim gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (2712).
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
اللَّهُمَّ رَبَّ السَّمَاوَاتِ وَرَبَّ الأَرْضِ وَرَبَّ الْعَرْشِ الْعَظِيمِ، رَبَّنَا وَرَبَّ كُلِّ شَيْءٍ، فَالِقَ الْحَبِّ وَالنَّوَى، وَمُنْزِلَ التَّوْرَاةِ وَالإِنْجِيلِ وَالْفُرْقَانِ، أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ كُلِّ شَيْءٍ أَنْتَ آخِذٌ بِنَاصِيَتِهِ، اللَّهُمَّ أَنْتَ الأَوَّلُ فَلَيْسَ قَبْلَكَ شَيْءٌ ، وَأَنْتَ الآخِرُ فَلَيْسَ بَعْدَكَ شَيْءٌ، وَأَنْتَ الظَّاهِرُ فَلَيْسَ فَوْقَكَ شَيْءٌ، وَأَنْتَ الْبَاطِنُ فَلَيْسَ دُونَكَ شَيْءٌ، اقْضِعَنَّا الدَّيْنَ وَأَغْنِنَا مِنَ الْفَقْرِ
“Allāhumma Rabbas-samāwāti waRabaal-’arḍ waRabbal-‘arshil-‘aẓīm, Rabbanā warabba kulli shay’, Fāliqal-ḥabbi wan-nawā, WaMunzilat-Tawrati wal-’Injīli wal-furqān, ’a‘ūdhu bika min sharri kulli shay’in ’Anta ’ākhidhun bināṣiyatih. Allāhumma ’Antal-’Awwal, falaysa qablaka shay’, wa’Antal-’Ākhir, falaysa ba‘daka shay’, wa’Antaẓ-Ẓāhir falaysa fawqaka shay’, wa’Antal-bāṭin, falaysa dūnaka shay’, iqḍi ‘annad-dayna wa’aghninā minal-faqr (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba àwọn sánmà, Ọlọ́hun Ọba ilẹ̀, Ọlọ́hun Ọba Ìtẹ́-ọlá tí ó tóbi, Ọlọ́hun Ọba wa àti Ọlọ́hun Ọba gbogbo nǹkan. Olùmú hóró ìrúgbìn àti kóro èso dàbínù hù jàde, Olùsọ At-Tawrah, Al-Injīl àti Al-Qur’ān tí ń ṣe òpinyà láààrin irọ́ àti òdodo kalẹ̀. Mo ń wá ìṣọ̀ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú gbogbo nǹkan tí Ìwọ yóò gbá àṣóńṣó rẹ̀ mú. Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Àkọ̀kọ́, kò sí nǹkankan síwájú Rẹ, Ìwọ ni Ìgbẹ̀yìn, kò sí nǹkankan lẹ́yìn Rẹ, Ìwọ ni Ẹni Gíga, kò sí nǹkankan lókè Rẹ, Ìwọ ni Ẹni sísúnmọ, kò sí nǹkankan tí ó súnmọ́ jù Ọ́ lọ. Bá wa san gbèsè wa, sì rọ̀ wá lọ́rọ̀ kúrò níbi òsì)” Muslim gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (2713).
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
بِاسْمِكَ رَبِّ وَضَعْتُ جَنْبِي وَبِكَ أَرْفَعُهُ إِنْ أَمْسَكْتَ نَفْسِي فَارْحَمْهَا وَإِنْ أَرْسَلْتَهَا فَاحْفَظْهَا بِمَا تَحْفَظُ بِهِ عِبَادَكَ الصَّالِحِينَ
“Bismika Rabbī waḍa‘tu janbī wabika ’arfa‘uh, ’in ’amsakta nafsī farḥamhā, wa’in ’arsaltahā faḥfaẓhā bimā taḥfadhu bihi ‘ibādakaṣ-ṣālihīn (Pẹ̀lú Orúkọ Rẹ, Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba mi, ni mo fi fi ẹ̀gbẹ́ mi lélẹ̀, pẹ̀lú Agbára Rẹ ni màá sì fi gbé e dìde. Tí O bá gba ẹ̀mí mi; yáa kẹ́ ẹ, tí O bá sì dá a padà sáyé, yáa ṣọ́ ọ pẹ̀lú ohun tí O fi máa ń ṣọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ tí wọ́n jẹ́ ẹni dáadáa)” Al-Bukhārī gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (6302), Muslim gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (2714).
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
الْحَمْدُ للّهِ الَّذِي أَطْعَمَنَا وَسَقَانَا، وَكَفَانَا وَآوَانَا، فَكَمْ مِمَّنْ لاَ كَافِيَ لَهُ وَلاَ مُؤْوِي
“Al-ḥamdu lillāhil-ladhī ’aṭ‘amanā wasaqānā, wakafānā, wa’āwānā, fakam mimman lā kāfiya lahu walā mu’wī (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe. Ẹni tí Ó fún wa ni oúnjẹ́ jẹ, tí Ó fún wa ni omi mu, tí Ó tó wa, tí Ó tún ṣe ibùgbé fún wa. Mélòómélòó ni ẹni tí kò ní ẹni tí yóò tó o, tí kò sì ní ẹni tí yóò fún un ní ibùgbé). Ó wà nínú Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – nígbà tó bá bọ́ sórí ibùsùn rẹ̀ máa ń sọ pé: “Al-ḥamdu lillāh ...” Muslim gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (2715).
100 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
سبحان الله (33)، الحمد لله (33)، الله أكبر (34) م
Nínú Sunnah ni kí ó ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun nígbà mẹtàlélọ́gbọ̀n, kí ó ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – nígbà mẹtàlélọ́gbọ̀n, kí ó sì gbé Ọlọ́hun tóbi nígbà mẹrìnlélọ́gbọ̀n, nígbà tó bá fẹ́ sùn. Èyí ní ọlá tó tóbi, òhun náà sì ni pé: Dájúdájú ó máa ń fún ara èèyàn lágbara nínú ojú ọjọ́ rẹ̀.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth ti ‘Aliyy –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: Dájúdájú Fāṭimah ráhùn nípa ohun tí ojú rẹ̀ ń rí nípa àpá ọmọlọ tí ó ń wà lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn ọrọ̀-ogun kan sì ti tẹ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – lọ́wọ́. Nítorí náà ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò bá a nílé. Ó bá ‘Ā’ishah pàdé, ó sì ṣe àlàyé fún un. Nígbà tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – padà dé, ‘Ā’ishah ṣàlàyé fún un nípa wíwá tí Fāṭimah wá bá a. Nítorí náà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – wá sí ọ̀dọ̀ wa, a sì ti fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lórí ibùsùn wa, ni a bá fẹ́ dìde láti lọ pàde rẹ̀, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sì sọ wí pé: “Ẹ dúró sí ààyè tí ẹ̀yin méjèèjì wà”. Ó sì jókòó sí ààrin wa títí tí mo fi fura mọ títutù gìgísẹ̀ rẹ̀ ní àyà mi, lẹ́yìn náà ó wí pé: Ṣé kí ń kọ yín ní ohun tí ó ní oore ju ohun tí ẹ̀yin méjèèjí béèrè fún lọ? Nígba tí ẹ bá ti fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lórí ibùsùn yín tán, kí ẹ gbé Ọlọ́hun tóbi (pẹ̀lú sísọ pé: Allāhu ’Akbar) nígbà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, kí ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Un (pẹ̀lú sísọ pé: Subḥānallāh) nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, kí ẹ sì ṣe ẹyìn fún Un (pẹ̀lú sísọ pé: Al-ḥamdulillāh) nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Èyí lóore fun yín ju ọmọ-ọ̀dọ̀ lọ”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3705), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2727).
Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn: ‘Aliyy – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- sọ wí pé: Mi ó fi ṣíṣe é sílẹ̀ láti ìgbà tí mo ti gbọ́ ọ láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Wọ́n bi í léèrè pé: Ṣé kódà ní alẹ́ ọjọ́ ogun Ṣifīn? Ó dáhùn pé: Kódà ní alẹ́ ọjọ́ ogun Ṣifīn” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5362), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2727).
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْلَمْتُ وَجْهِي إِلَيْكَ، وَفَوَّضْتُ أَمْرِي إِلَيْكَ، وَأَلْجَأْتُ ظَهْرِي إِلَيْكَ، رَغْبَةً وَرَهْبَةً إِلَيْكَ. لاَ مَلْجَأَ وَلاَ مَنْجَا مِنْكَ إِلاَّ إِلَيْكَ، آمَنْتُ بِكِتَابِكَ الَّذِي أَنْزَلْتَ، وَبِنَبِيِّكَ الَّذِي أَرْسَلْتَ
“Allāhumma ’innī ’aslamtu wajhī ’ilayk, wafawwaḍtu ’amrī ’ilayk, wa’alja’tu ẓahrī ’ilayk, raghbatan warahbatan ’ilayk, lā malja’ walā manjā minka ’illa ’ilayk, ’amantu bikitābikal-ladhī ’anzalt, wabinabiyyikal-ladhī ’arsalt (Ìrẹ Ọlọ́hun! Mo jọ̀wọ́ àdojúkọ mi sílẹ̀ fún Ọ, mo sì fa ọ̀rọ̀ mi lé Ọ lọ́wọ́, mo sì fi ẹ̀yìn (ọ̀ràn) mi tí sí Ọ, níti ìrankàn wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ àti ìbẹ̀rù Rẹ. Kò sí ọ̀nà àbáyọ, kò sì sí àsálà mọ́ Ọ lọ́wọ́ àyàfi wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Mo gba Tírà Rẹ eléyìí tí O sọ̀kalẹ̀ gbọ́ lódodo àti Òjíṣẹ́ Rẹ eléyìí tí O rán níṣẹ́)”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (247), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2710). Ní ìparí Ḥadīth yìí, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Jẹ́ kí wọ́n jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wàá sọ gbẹ̀yìn. Tí o bá wáá kú ní òru ọjọ́ rẹ yìí, o kú lórí Àdámọ́ ẹ̀sìn Ọlọ́hun”. Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Muslim gbà wá: “Tí ilẹ̀ bá sì mọ́ bá ọ láyé, ilẹ̀ yóò mọ́ bá ọ lórí dáadáa”.
Nínú Ḥadīth yìí, àlàyé nípa Sunnah mìíràn wà níbẹ̀, èyí ni: Kí ó jẹ́ kí ìrántí Ọlọ́hun jẹ́ ohun tí yóò sọ gbẹ̀yìn síwájí kí ó tó sùn. Ẹ̀bùn tó tóbi wà níbẹ̀, tí ó bá jẹ́ wí pé wọ́n kádàrá kí ó kù ní òru ọjọ́ rẹ̀ yìí. Nítorí pé dájúdájú yóò wà nínú àwọn tó kú lórí Àdámọ́ ẹ̀sìn Ọlọ́hun, èyí tó túmọ̀ sí pé: Dájúdájú ó kú lórí Sunnah, lórí ìlànà ẹ̀sìn Ànábì Ibrāhīm – kí ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ní ẹni tó ṣẹ́rí kúrò níbi ẹbọ. Tí ó bá sì jí sáyé, dájúdájú yóò jí sáyé lórí dáadáa níbi arísìkí rẹ̀ àti iṣẹ́ rẹ̀. Ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó kó gbogbo nǹkan sínú, ó kó ohun tó síwájú àti ohun tó yàtọ̀ sí i sínú – Ọlọ́hun ni Ó mọ̀ jùlọ –.
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
اللَّهُمَّ أَنْتَ رَبِّي لَا إِلَهَ إِلَّا أَنْتَ خَلَقْتَنِي وَأَنَا عَبْدُكَ وَأَنَا عَلَى عَهْدِكَ وَوَعْدِكَ مَا اسْتَطَعْتُ أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ مَا صَنَعْتُ أَبُوءُ لَكَ بِنِعْمَتِكَ عَلَيَّ وَأَبُوءُ لَكَ بِذَنْبِي فَاغْفِرْ لِي فَإِنَّهُ لَا يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلَّا أَنْتَ
Nínú ohun tó pàtàkì kí a pe àkíyèsí ara wa sí ni: Ìrántí Ọlọ́hun pàtàkì, èyí tó máa ń ṣe sábàbí ọlá tó tóbi, Ọlọ́hun, Ọba tí Ó ga, Ọba tí Ó tóbi – gbígbọn-n-gbọ́n ni fún títóbi Rẹ̀ –. Èyí ni ohun tó wá nínú Ṣaḥīḥul-Bukhārī, nínú Ḥadīth tí Shaddād ọmọ ’Aws – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pé: “Ọ̀gá àdúà tí a fi máa ń tọrọ àforíjìn ni kí ó sọ pé: Allāhumma ’Anta Rabbī lā ’ilāha ’illā ’Ant, khalaqtanī wa’ana ‘abduk, wa’ana ‘alā ‘ahdika wawa‘dika mastaṭa‘t, ’a‘ūdhu bika min sharri mā ṣana‘t, ’abū’u laka bini‘matika ‘alayy, wa’abū’u bidhanbī, faghfir lī fa’innahu lā yaghfirudh-dhunūba ’illā ’Ant (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Ọlọ́hun Ọba mi, kò sí Ọlọ́hun kan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ nìkan. O dá mi, àti pé èmi jẹ́ ẹrúsìn fún Ọ. Èmi sì ń bẹ lórí ìpínhùn Rẹ àti àdéhùn Rẹ bí mo ti lágbára mọ. Mo wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú ohun tí mo ṣe. Mo gbà fún Ọ pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ tí O se fún mi, mo sì mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ṣe àforíjì fún mi. Dájúdájú kò sí ẹni tí ó le ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àyàfi Ìwọ nìkan). Ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo sí i ní alẹ́, tí ó wá kú ní òru ọjọ́ náà, síwájú kí ó tó jí ní àárọ̀, yóò wọ Àlùjánńnà” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6306).
1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
Abū Ad-Dardā’ gbà á wá láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pé ó sọ pé: »Ṣé ẹnì kankan nínú yín yóò kágara láti ké ìlàta Al-Qur’ān ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo bí? «Wọ́n (àwọn sàábé) sọ wí pé: Báwo ni yóò ṣe ké ìlàta Al-Qur’ān? Ó dáhùn pé: » Qul Huwallāhu ’Aḥad ṣe déédé ìlàta Al-Qur’ān «
Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (811), Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5015), nínú Ḥadīth tí Abū Sa‘īd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá.