brightness_1
Díẹ̀ nínú àwọn àǹfààní títẹ̀lé Sunnah
Títẹ̀lé Sunnah – ìrẹ ọmọ-ìyá mi nínú ẹ̀sìn Islām, tí ó jẹ́ olólùfẹ̀ẹ́ mi – ní àwọn àǹfààní tó pọ̀, nínú rẹ̀ ni:
1/ Dídé ipò nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́hun, nítorí pé pẹ̀lú wíwá ìsúnmọ́ Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n, pẹ̀lú kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ, ni ẹrúsìn Ọlọ́hun fi máa ń rí ìfẹ́ Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n.
Ibn Al-Qayyim – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ọlọ́hun kò ní fẹ́ràn rẹ àyàfi nígbà tí o bá tẹ̀lé olólùfẹ̀ẹ́ Rẹ̀, ní ìkọ̀kọ̀ àti gbangba, tí ó gba ìró tí ó múwá gbọ́, tí ó tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, tí ó dáhùn ìpèpè rẹ̀, tí o mọ̀ọ́mọ̀ gbé ọlá fún un, tí o bọ́pá-bọ́sẹ̀ níbi ìdájọ́ ẹni tí ó yàtọ̀ sí i nítorí ìdájọ́ rẹ̀, àti kúrò níbi ìfẹ́ ẹni tí ó yàtọ̀ sí i nítorí ìfẹ́ rẹ̀, àti kúrò níbi títẹ̀lé ẹni tí ó yàtọ̀ sí i nítorí títẹ̀lé àṣẹ rẹ̀. Tí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe káàárẹ̀, ṣẹ́rí padà láti ibi tí ó bá fẹ́, kí ó sì lọ wá ìmọ́lẹ̀, nítorí pé o kò sí lórí nǹkankan”. Wo: Madārijus-Sālikīn (3/37).
2/ Rírí wíwàpẹ̀lúni Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – ẹrúsìn Ọlọ́hun, nítorí náà Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, yóò fi í ṣe kòǹgẹ́ oore, kò sì ní máa fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ ṣe nǹkankan àyàfi ohun tí yóò yọ́ Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n, nínú, nítorí pé nígbà tí ó bá ti rí ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, dájúdájú yóò rí ìwàpẹ̀lúni Rẹ̀.
3/ Gbígba àdúà ẹrúsìn Ọlọ́hun, èyí tí ó kó rírí ìfẹ́ Ọlọ́hun sínú. Nítorí pé ẹni kẹ́ni tí ó bá wá sísúnmọ́ Ọlọ́hun pẹ̀lú kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ, dájúdájú yóò rí ìfẹ́ Ọlọ́hun, ẹni kẹ́ni tí ó bá sì ti rí ìfẹ́ Ọlọ́hun, dájúdájú yóò rí gbígbà àdúà.
Ìtọ́ka àwọn àǹfààní mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí nìyí:
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú Ọlọ́hun sọ wí pé: Ẹni kẹ́ni tí ó bá mú àyànfẹ́ Mi kankan ní ọ̀tá, dájúdájú mo ti kéde fún un pé màá gbógun tì í. Àti pé ẹrúsìn Mi kò le wá ìsúnmọ́ Mi pẹ̀lú nǹkankan tí ó wù Mí ju ohun tí mo ṣe lọ́ranyàn lé e lórí lọ. Àti pé ẹrúsìn Mi kò ní yé máa súnmọ́ Mi pẹ̀lú kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ títí tí màá fi fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà tí mo bá ti fẹ́ràn rẹ̀ tán, màá ṣọ́ ìgbọràn rẹ̀, èyí tí ó fi ń gbọ́ràn, àti ìríran rẹ̀, èyí tí ó fi ń ríran, àti ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó fi ń gbá nǹkan mú, àti ẹsẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó fi ń rìn. Tí ó bá tọrọ nǹkan ní ọ̀dọ̀ Mi, dájúdájú màá fún un, tí ó bá sì wá ìṣọ́ ní ọ̀dọ̀ Mi, dájúdájú màá ṣọ́ ọ. Mi ò da ohun kankan tí mo fẹ́ ṣe wò rí, bíi dída gbígba ẹ̀mí olùgbàgbọ́ òdodo wò Mi, ò kórìíra ikú, Èmi náà sì kórìíra ṣíṣe àìda sí i” Al-Bukhārī ni ó gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6502).
Pípé àdínkù tí ó bá wà níbi àwọn ìrun ọ̀ranyàn, nítorí pé kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ máa ń pé àwọn àbùjẹkù tí ó bá wà níbi àwọn ìrun ọ̀ranyàn.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Abū Hurayrah –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- gbà wá, ó sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Dájúdájú àkọ́kọ́ ohun tí wọn yóò ṣe ìṣirò ẹrúsìn Ọlọ́hun lórí rẹ̀ ní ọjọ́ Ìgbéǹde, nínú iṣẹ́ rẹ̀ ni ìrun. Tí ó bá dára, dájúdájú ó ti jèrè, ó sì ti là, tí ó bá sì bàjẹ́, dájúdájú ó ti pòfo, ó sì ti ṣòfò. Tí nǹkankan bá dínkù nínú ìrun ọ̀ranyàn rẹ̀, Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n, yóò sọ wí pé: “Ẹ wò ó; ṣé ẹrúsìn Mi ní nǹkankan nínú iṣẹ́ àṣegbọrẹ? Wọn yóò sì pé ohun tí ó bá dínkù nínú ọ̀ranyàn rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, lẹ́yìn náà gbogbo iṣẹ́ rẹ yóò wá lórí èyí” Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (9494), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (864), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (413), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 1/405).