Ḥudhayfah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: “Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – nígbà tí ó bá dìde lóru, máa ń gbo ẹnu rẹ̀ ṣùkùṣùkù pẹ̀lú pákò” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (245), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (255). Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Muslim gbà wá: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – nígbà tí ó bá dìde lóru láti kírun, máa ń gbo ẹnu rẹ̀ ṣùkùṣùkù pẹ̀lú pákò”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (255). Ìtumọ̀ gbígbo ṣùkùṣùkù ni: Gbígbo ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àwọn eyín pẹ̀lú pákò.
Ohun ni ohun tí ó wá nínú Ṣaḥīḥul-Bukhārī, nínú Ḥadīth tí Ḥudhayfah –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, nígbà tí ó bá fẹ́ sùn, máa ń sọ wí pé: “Bismikallāhumma ’amūtu wa’aḥyā (Pẹ̀lú Orúkọ Rẹ, Ìrẹ Ọlọ́hun, ni màá fi kú, ni màá sì fi ṣẹ̀mí)”. Nígbà tí ó bá jí dìde lójú-oorun, yóò wí pé: “Al-ḥamdu lillāhil-ladhī ’aḥyānā ba‘da mā ’amātanā wa-’ilayhin-nushūr (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe, Ẹni tí Ó sọ wá di alààyè lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti gba ẹ̀mí wa, àti pé ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni Ìgbéǹde yóò jẹ́)” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6324), Muslim sì gbà á wá, nínú Ḥadīth Al-Barā’ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – pẹ̀lú òǹkà (2711).
Èyí jẹ́ Sunnah mẹ́ta, èyí tí ó wá nínú Ḥadīth tí Ibn ‘Abbās – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá, èyí tí Al-Bukhārī àti Muslim panupọ̀ gbà wá pé: “Dájúdájú òun (Ibn ‘Abbās) sùn, ní òru ọjọ́ kan, ní ọ̀dọ̀ Maymūnah, ìyàwó Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ó sì jẹ́ arábìnrin ìyá rẹ̀. Mo sùn sí ìbú ìrọ̀rí, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – àti ará-ilé rẹ̀ sì sùn sí òòró rẹ̀. Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sùn títí tí òru fi dá sí méjì, tàbí àsìkò díẹ̀ síwájú rẹ̀, tàbí àsìkò díẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀. Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – jí dìde lójú-oorun, ó sì jókòó, ó ń nu orípa oorun nù kúró ní ojú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà ó ké àwọn āyah mẹ́wàá tí ó gbẹ̀yìn Sūrah ’Āl-‘Imrān. Lẹ́yìn náà ó lọ síbi korobá omi tí wọ́n gbékọ́, ó sé àlùwàlá lára omi tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì ṣe àlùwàlá rẹ̀ dáadáa, lẹ́yìn náà ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ síní kírun”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (183), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (763).
Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Muslim gbà wá (763): “Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – dìde ní ìgbẹ̀yìn òru, lẹ́yìn náà ó jáde, ó sì bojú wo sánmà, lẹ́yìn náà ó ké āyah yìí, èyí tí ó wà nínú Sūrah ’Āl-‘Imrān: {Dájúdájú nibi ṣíṣẹ̀dá àwọn sánmà àti ilẹ̀ àti níbi yíyapa òru àti ọ̀sán, dájúdájú àwọn àmì ń bẹ níbẹ̀ fún àwọn onílàákàyè... } [’Āl-‘Imrān: 190].
- “Ó ń nu orípa oorun nù kúró ní ojú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀” túmọ̀ sí wí pé: Ó ń fi ọwọ́ rẹ̀ pá ẹyinjú rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó le nu orípa oorun nù. (Shannu) ni: Korobá omi.
Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Muslim gbà wá, àlàyè ohun tí ẹni tí ó bá fẹ́ lo Sunnah yìí yóò ké wà níbẹ̀, dájúdájú yóò bẹ̀rẹ̀ láti ibi ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, tí Ó sọ wí pé: {Dájúdájú nibi ṣíṣẹ̀dá àwọn sánmà àti ilẹ̀ àti níbi yíyapa òru àti ọ̀sán} títí dé ìparí Sūrah ’Āl-‘Imrān.

Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá jí ní ojú oorun, kí ó má ṣe ti ọwọ́ rẹ̀ bọ igbá-omi títí tí yóò fi fọ̀ ọ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta, nítorí pé dájúdájú kò mọ ibi tí ọwọ́ rẹ̀ sùn” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (162), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (278).
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá jí ní ojú oorun, kí ó fín omi símú ní ẹ̀ẹ̀mẹta, nítorí pé dájúdájú èṣù máa ń sùn sórí igi imú rẹ̀” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3295), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (238). Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Al-Bukhārī gbà wá: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá jí ní ojú oorun, tí ó sì fẹ́ ṣe àlùwàlá, kí ó rí i pé òun fín omi símú ní ẹ̀ẹ̀mẹta...” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3295).
Nítorí Ḥadīth tí Ibn ‘Abbās –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì- gbà wá, èyí tí ó ti síwájú, nígbà tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – fẹ́ kírun, ó dìde lọ síbi korobá tí wọ́n gbékọ́, ó sì ṣe àlùwàlá nínú rẹ̀.
Nígbà tí a bá dé ibi ọ̀rọ̀ nípa àlùwàlá, a ó kóra ró díẹ̀ láti ṣàlàyè àwọn Sunnah kan nípa àlùwàlá, ní ṣókí àti pẹ̀lú òǹkà, kì í ṣe ní ìfọ́síwẹ́wẹ́ àti àkótán, nítorí pé ohun tí a ti mọ̀ ni, a ó kàn rán ara wa létí nípa rẹ̀ láti pé àwọn Sunnah.