brightness_1
Nínú ohun tí ó bá Sunnah mu ni kí ó kírun òru ní àsìkò rẹ̀ tí ó lọ́lá jùlọ
Tí wọ́n bá bi wá pé: Àsìkò wo ni ó lọ́lá jùlọ fún ìrun òru?
Ìdáhùn nìyí: Nínú ohun tí a ti mọ̀ ni wí pé, dájúdájú àsìkò ìrun Witr máa ń bẹ̀rẹ̀ láti ẹ̀yìn ìrun alẹ́ títí ìgbà tí àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́ yóò fi yọ. Nítorí náà àsìkò ìrun Witr wà láàrin ìrun alẹ́ àti yíyọ àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –máa ń kí, láàrin ìgbà tí ó bá ti kírun alẹ́ tán sí ìgbà tí àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́ yóò fi yọ; òpó ìrun mọ́kànlá, ó máa ń sálámà láàrin gbogbo òpó ìrun méjì, yóò sì fi ẹyọ̀nka ṣe ìrun Witr” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2031), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (736).
Nípa àsìkò tó lọ́lá jùlọ fún ìrun òru, èyí ni: Ìdámẹ́ta òru, lẹ́yìn ìlàjì rẹ̀.
Ohun tí a gbà lérò ni: Kí ènìyàn pín òru sí ìlàjì, ìlàjì, kí ó sì dìde kírun òru níbi ìdámẹ́ta nínú ìlàjì òru kejì, kí ó sì sùn ní ìgbẹ̀yìn òru. Ìtumọ̀ èyí ni pé: Yóò dìde kírun òru níbi ìdámẹ́fà kẹrin àti ìkarùn-ún, yóò sì sùn níbi ìdámẹ́fà ẹlẹ́ẹ̀kẹfà.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú ààwẹ̀ tí Ọlọ́hun fẹ́ràn jùlọ ni ààwẹ̀ Ànábì Dāwūd, ìrun tí Ọlọ́hun sì fẹ́ràn jùlọ ni ìrun Ànábì Dāwūd – kí ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ó máa ń fi ìlàjì òru sùn, yóò sì fi ìdámẹ́ta rẹ̀ dìde kírun, yóò tún fi ìdámẹ́fà rẹ̀ sùn, ó sì máa ń fi ọjọ́ kan gba ààwẹ̀, yóò fi ọjọ́ kejì ṣínu” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3420), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1159).
– Tí ènìyàn bá fẹ́ lo Sunnah yìí, báwo ni yóò ti ṣe ìṣirò òru rẹ̀?
Yóò ṣírò àsìkò rẹ̀ láti ìgbà tí òòrùn bá ti wọ̀ títí tí àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́ yóò fi yọ. Lẹ́yìn náà yóò pín in sí ọ̀nà mẹ́fà, ìpín mẹ́ta àkọ́kọ́, èyí ni ìdáméjì àkọ́kọ́ nínú òru, yóò dìde kírun lẹ́yìn rẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé: Yóò dìde kírun níbi ìdámẹ́fà kẹrin àti ìkarùn-ún. Nítorí pé dájúdájú èyí ni a ó kà sí ìdámẹ́ta òru. Lẹ́yín náà yóò sùn níbi ìdámẹ́fà ìgbẹ̀yìn, èyí ni ìdámẹ́fà kẹfà. Ìdí nìyí, tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – fi sọ wí pé: “Àsìkò sààrì kò bá a (Ànábì) – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ní ọ̀dọ̀ mi rí, àyàfi kí ó máa sùn lọ́wọ́” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3420), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1159).
Èyí ni ọ̀nà tí Mùsùlùmí yóò tọ̀ tí yóò fi wà ní àsìkò tí ó lọ́lá jùlọ fún kíkírun ní òru, gẹ́gẹ́ bí ó ti wá nínú Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá, èyí tí ó ti síwájú.
Kókó ọ̀rọ̀ yìí, ní ṣókí, ni pé: Jíjẹ́ èyí tí ó lọ́lá jùlọ àsìkò dídìde kírun lóru wà lórí ìpele mẹ́ta:
Ìpele Àkọ́kọ́: Kí èèyàn fi ìlàjì òru àkọ́kọ́ sùn, lẹ́yìn náà yóò fi ìdámẹ́ta rẹ̀ dìde kírun, lẹ́yìn náà yóò fi ìdámẹ́fà rẹ̀ sùn – gẹ́gẹ́ bíi àlàyé tí ó ti siwájú –.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr, ọmọ ‘Āṣ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá, èyí tí ó ti síwájú láìpẹ́.
Ìpele Kejì: Kí èèyàn dìde kírun níbi ìdámẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn nínú òru.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ọlọ́hun Ọba wa, Oníbùkún, Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga, máa ń sọ̀kalẹ̀, ní gbogbo òru, sí sánmà ilé-ayé, nígbà tí ó bá ṣẹ́kù ìdámẹ́ta tí ó gbẹ̀yìn nínú òru, yóò máa sọ wí pé: Tani yóò pè Mí, máa sì dá a lóhùn, tani yóò tọrọ nǹkan lọ́dọ̀ Mi, máa sì fún un, tani yóò tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Mi, máa sì ṣe àforíjìn fún un” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1145), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (758). Bẹ́ẹ̀ náà ni Ḥadīth tí Jābir – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó ń bọ̀ lọ́nà.
Tí ó bá ń bẹ̀rù pé òun le má jí dìde ní ìgbẹ̀yìn òru, kí ó rí i pé òun kírun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, tàbí ní ìgbàkíìgbà tí ó bá rọ̀ ọ́ lọ́rùn ní òru, èyí ni ìpele kẹta.
Ìpele Kẹta: Kí ó kírun ní ìbẹ̀rẹ̀ òru, tàbí ní ìgbàkíìgbà tí ó bá rọ̀ ọ́ lọ́rùn ní òru.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Jābir – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù pé òun kò ní jí dìde kírun ní ìgbẹ̀yìn òru, kí ó rí i pé òun kírun Witr ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹní tí ó bá ń rankàn pé òun yóò jí dìde kírun ní ìgbẹ̀yìn rẹ̀, kí ó kírun Witr ní ìgbẹ̀yìn òru, nítorí pé dájúdájú ìrun ìgbẹ̀yìn òru jẹ́ ohun tí àwọn Malā’kah máa ń kópa níbẹ̀, èyí ni ó sì lọ́lá jùlọ” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (755).
Bákan náà, a ó gbé àsọtẹ́lẹ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, fún Abū Dharr, lórí rẹ̀. (An-Nasā’ī gbà á wá nínú As-sunanul-Kubrā {2712}), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Aṣ-Ṣaḥīḥah, 2166). Àti fún Abū Ad-Dardā’ (Aḥmad gbà á wá pẹ̀lú òǹkà {27481}), àti (Abū Dāwūd pẹ̀lú òǹkà {1433}), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Ṣaḥīḥu Abī Dāwūd, 5/177). Àti fún Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (737). Kálukú wọn sọ wí pé: “Ààyò mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún pẹ̀lú nǹkan mẹ́ta”, ó sì dárúkọ nínú rẹ̀: “Àti pé kí n máa kírun Witr síwájú kí n tó sùn”.