languageIcon
search
search
beforeFajronColorIcon Àwọn Sunnah tó ní àsìkò/ Àsìkò ìyálẹ̀ta/ ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 4 Àwọn Sunnah )
brightness_1 Sunnah ni, ní àsìkò ìyálẹ̀ta, kí ẹrúsìn Ọlọ́hun kí ìrun (àsìkò ìyálẹ̀ta)

Ẹ̀rí rẹ̀ ni :

a. Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ààyò mi – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún mi pẹ̀lú nǹkan mẹ́ta: Gbígbà ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú gbogbo oṣù, òpó-ìrun méjì ní àsìkò ìyálẹ̀ta, àti pé kí n máa kírun wítìrí síwájú kí n tó sùn”. Bákan náà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún    Abū Ad-Dardā’– kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –. Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún Abū Dharr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –. An-Nasā’ī gbà á wá nínú As-sunanul-Kubrā {2712}), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tó ní àlááfíà nínú (Aṣ-Ṣaḥīḥah, 2166).

b. Ḥadīth tí Abū Dharr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, pé dájúdájú ó sọ pé: “Ẹni kẹ́ni nínú yín yóò jí ní àárọ̀, lẹ́ni tí títọrẹ àánú jẹ́ ọ̀ranyàn lórí gbogbo oríkèé ara rẹ̀, nítorí náà gbogbo àfọ̀mọ́ tó bá ṣe fún Ọlọ́hun, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tó bá ṣe, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo lā ilāha illallāh tó bá se, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo gbígbé Ọlọ́hun tóbi rẹ̀, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo àṣẹ dáadáa tó bá pa, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo kíkọ̀ nípa ohun tí ọkàn kọ̀ rẹ̀, ìtọrẹ-àánú ni.  Òpó-ìrun méjì tí ó bá kí ní àsìkò ìyálẹ̀ta sì ti tó fún gbogbo èyí”. Muslim pẹ̀lú òǹkà (720).

Sulāmah, nínú èdè Yorùbá, ni: Àwọn egungun ara tó pín lọ́tọ̀tọ̀.

Àlàyé wá nínù Ṣaḥīḥu Muslim, nínú  Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé dájúdájú wọ́n dá gbogbo ènìyàn lórí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́ta oríkèé ara. Àti pé dájúdájú ẹni kẹ́ni tó bá ṣe ìtọrẹ-àánú tí ó tó iye òǹkà yìí, dájúdájú yóò máa rín lọ́jọ́ náà lẹ́ni tó ti la ẹ̀mi ara rẹ̀ kúrò níbi iná Jahannam.