Sunnah ni, ní àsìkò ìyálẹ̀ta, kí ẹrúsìn Ọlọ́hun kí ìrun (àsìkò ìyálẹ̀ta)
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
a. Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ààyò mi – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún mi pẹ̀lú nǹkan mẹ́ta: Gbígbà ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú gbogbo oṣù, òpó-ìrun méjì ní àsìkò ìyálẹ̀ta, àti pé kí n máa kírun wítìrí síwájú kí n tó sùn”. Bákan náà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún Abū Ad-Dardā’– kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –. Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ fún Abū Dharr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –. An-Nasā’ī gbà á wá nínú As-sunanul-Kubrā {2712}), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tó ní àlááfíà nínú (Aṣ-Ṣaḥīḥah, 2166).
b. Ḥadīth tí Abū Dharr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, pé dájúdájú ó sọ pé: “Ẹni kẹ́ni nínú yín yóò jí ní àárọ̀, lẹ́ni tí títọrẹ àánú jẹ́ ọ̀ranyàn lórí gbogbo oríkèé ara rẹ̀, nítorí náà gbogbo àfọ̀mọ́ tó bá ṣe fún Ọlọ́hun, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tó bá ṣe, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo lā ilāha illallāh tó bá se, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo gbígbé Ọlọ́hun tóbi rẹ̀, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo àṣẹ dáadáa tó bá pa, ìtọrẹ-àánú ni. Gbogbo kíkọ̀ nípa ohun tí ọkàn kọ̀ rẹ̀, ìtọrẹ-àánú ni. Òpó-ìrun méjì tí ó bá kí ní àsìkò ìyálẹ̀ta sì ti tó fún gbogbo èyí”. Muslim pẹ̀lú òǹkà (720).
Sulāmah, nínú èdè Yorùbá, ni: Àwọn egungun ara tó pín lọ́tọ̀tọ̀.
Àlàyé wá nínù Ṣaḥīḥu Muslim, nínú Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé dájúdájú wọ́n dá gbogbo ènìyàn lórí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́ta oríkèé ara. Àti pé dájúdájú ẹni kẹ́ni tó bá ṣe ìtọrẹ-àánú tí ó tó iye òǹkà yìí, dájúdájú yóò máa rín lọ́jọ́ náà lẹ́ni tó ti la ẹ̀mi ara rẹ̀ kúrò níbi iná Jahannam.
Àsìkò rẹ̀
Àsìkò ìrun ìyálẹ̀ta máa ń bẹ̀rẹ̀ láti: Ìgbà tí òòrùn bá ti gbéra sókè tó déédé òduwọ̀n ọ̀kọ̀ – ohun tí a gbà lérò ni pé: Lẹ́yìn ìgbà tí àsìkò tí wọ́n kọ̀ fún wa láti kírun bá ti lọ.
Ó sì máa ń parí: Nígbà tó bá kù díẹ̀ kí òòrùn yẹ àtàrí – ohun tí a gbà lérò ni: Nǹkan bíi ìṣẹ́jú mẹ́wàá síwájú ìrun ọ̀sán ní àfojúdá –.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth ti ‘Amr ọmọ ‘Absah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: “Kí ìrun àárọ̀, lẹ́yìn náà kóra ró níbi kíkí ìrun, nígbà tí òòrùn bá yọ títí tí yóò gbéra sókè ..., lẹ́yìn náà kírun, nítorí pé ìrun yìí jẹ́ ohun tí àwọn Malā’kah máa ń jẹ́rìí sí, tí wọ́n sì máa kópa níbẹ̀, títí tí òjìji yóò fi tó déédé ọ̀kọ̀, lẹ́yìn náà kóra ró níbi kíkí ìrun, nítorí pé dájúdájú nígbà náà ni wọ́n máa ko iná Jahannam...” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (832).
Àsìkò rẹ̀ tó lọ́lá jùlọ
Àsìkò rẹ̀ tó lọ́lá jùlọ : Wà ní ìgbẹ̀yìn àsìkò rẹ̀, èyí ni ìgbà tí ìyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ yóò máa gbóná mọ́ àwọn ọmọ ràkúnmí lára, nítorí lílekoko gbígbóná òòrùn.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth ti Zaynd ọmọ ’Arqam – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, sọ wí pé: “Ìrun àwọn ẹni tó máa ń ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́hun, ni ìrun tí a máa ń kí nígbà tí ìyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ yóò máa gbóná mọ́ àwọn ọmọ ràkúnmí lára, nítorí lílekoko gbígbóná òòrùn” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (748).
Ibn Bāz– kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ́ – sọ́ wí pé: “Ìtumọ̀ tarmaḍu ni: Kí gbígbóná òòrùn le koko fún un, ìtumọ̀ fiṣāl ni: Àwọn ọmọ rákúnmín. Ó sì jẹ́ ara àwọn ìrun, èyí tó jẹ́ wí pé kíkí i ní ìgbẹ̀yìn àsìkò rẹ̀ ní ó lọ́lá jùlọ.
Iye òǹkà òpó-ìrun rẹ̀
Èyí tó kéré jùlọ nínú ìrun àsìkò ìyálẹ̀ta ni: Òpó-ìrun méjì; nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, èyí tó wà nínú Ṣaḥīḥu méjèèjì: “Ààyò mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún mi pẹ̀lú nǹkan mẹ́ta, – ó sì sọ nínú rẹ̀ pé: Àti òpó-ìrun méjì ní àsìkò ìyálẹ̀ta”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1981), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (721).
Ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jùlọ nínú ìrun àsìkò ìyálẹ̀ta, ohun tó ní àlááfíà ni pé: Dájúdájú kò sí ààlà kankan fún èyí tó pọ̀ jùlọ nínú rẹ̀, ní ìyapa sí ẹni tó fi ààlà sí pé kò gbọdọ̀ ju òpó-ìrun mẹ́jọ lọ. Nítorí náà ó ní ẹ̀tọ́ kí ó dé bi tí Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, bá ràn án lọ́wọ́ dé lórí rẹ̀. Nítorí Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – máa ń kírun òpó-ìrun mẹ́rin ní àsìkò ìyálẹ̀ta, ó sì máa ń ṣe àlékún bí Ọlọ́hun bá ti fẹ́”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (719).
Kàn sí wa
Sí wa
Yóò dùn mọ́wa kí á rí àwọn ìpè rẹ àti àwọn ìbéèrè rẹ ní ìgbà kíìbà