/Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 3 Àwọn Sunnah )
Ìtumọ̀ Sunnah
Sunnah túmọ̀ sí: Ohun tí a fẹ́ àti ohun tí ẹ̀sìn Islām pè wá sí ṣíṣe é
Nítorí náa Sunnah ni: Ohun tí Ọlọ́hun, Ọba Aṣòfin, pàṣẹ rẹ̀ ní ọ̀nà tí kò pọn dandan rẹ̀. Àǹfààní rẹ̀ ni pé: Dájúdájú wọn yóò san ẹni tó bá ṣe é ní ẹ̀san rere, ṣùgbọ́n wọn kò ní jẹ ẹni tó bá pa á tì níyà.
Àwọn àpèjúwe díẹ̀ nínú níní àkàkún Sunnah àwọn ẹni ìsiwájú
1/ Muslim, nínú Ṣaḥīḥu rẹ̀, gba Ḥadīth wá láti ọ̀dọ̀ An-Nu‘mān ọmọ Sālim, òun náà gbà á wá láti ọ̀dọ̀ ‘Amr ọmọ Aws – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì –, ó sọ wí pé: ‘Anbasah ọmọ Abī Sufyān bá mi sọ̀rọ̀, ó wí pé: Mo gbọ́ tí Umm Ḥabībah ń sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé:“Ẹni kẹ́ni tí ó bá kí òpó-ìrun méjìlà ní ọjọ́ kan àti òru rẹ̀, wọn yóò kọ́ ilé fún un nínú ọgbà-ìdẹ̀ra Àlùjáńnà, nítorí pé ó kí wọn” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1727). Umm Ḥabībah sọ wí pé: Mi ó fi kíkí wọn sílẹ̀ láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa wọn láti ọ̀dọ̀ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. ‘Anbasah náà sọ wí pé: Mi ó fi kíkí wọn sílẹ̀ láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa wọn láti ọ̀dọ̀ Umm Ḥabībah.
‘Amr ọmọ ’Aws náà sì sọ wí pé: Mi ó fi kíkí wọn sílẹ̀ láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa wọn láti ọ̀dọ̀ ‘Anbasah.
An-Nu‘mān ọmọ Sālim náà tún sọ wí pé: Mi ó fi kíkí wọn sílẹ̀ láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa wọn láti ọ̀dọ̀ ‘Amr ọmọ Aws.
2/ Ḥadīth ti ‘Aliyy – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: Dájúdájú Fāṭimah ráhùn nípa ohun tí ojú rẹ̀ ń rí nípa àpá ọmọlọ tí ó ń wà lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn ọrọ̀-ogun kan sì ti tẹ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – lọ́wọ́. Nítorí náà ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n kò bá a nílé. Ó bá ‘Ā’ishah pàdé, ó sì ṣe àlàyé fún un. Nígbà tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – padà dé, ‘Ā’ishah ṣàlàyé fún un nípa wíwá tí Fāṭimah wá bá a. Nítorí náà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – wá sí ọ̀dọ̀ wa, a sì ti fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lórí ibùsùn wa, ni a bá fẹ́ dìde láti lọ pàde rẹ̀, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sì sọ wí pé: “Ẹ dúró sí ààyè tí ẹ̀yin méjèèjì wà”. Ó sì jókòó sí ààrin wa títí tí mo fi fura mọ títutù gìgísẹ̀ rẹ̀ ní àyà mi, lẹ́yìn náà ó wí pé: Ṣé kí ń kọ yín ní ohun tí ó ní oore ju ohun tí ẹ̀yin méjèèjí béèrè fún lọ? Nígba tí ẹ bá ti fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lórí ibùsùn yín tán, kí ẹ gbé Ọlọ́hun tóbi (pẹ̀lú sísọ pé: Allāhu ’Akbar) nígbà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, kí ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Un (pẹ̀lú sísọ pé: Subḥānallāh)nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, kí ẹ sì ṣe ẹyìn fún Un (pẹ̀lú sísọ pé: Al-ḥamdulillāh)nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Èyí lóore fun yín ju ọmọ-ọ̀dọ̀ lọ”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3705), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2727).
Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn: ‘Aliyy – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: Mi ó fi ṣíṣe é sílẹ̀ láti ìgbà tí mo ti gbọ́ ọ láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Wọ́n bi í léèrè pé: Ṣé kódà ní alẹ́ ọjọ́ ogun Ṣifīn? Ó dáhùn pé: Kódà ní alẹ́ ọjọ́ ogun Ṣifīn” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5362), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2727).
Ohun tí a sì ti mọ̀ ni pé dájúdájú alẹ́ ọjọ́ ogun Ṣifīn jẹ́ alẹ́ ọjọ́ tí ogun wáyé, tí ‘Aliyy –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- sì jẹ́ adarí ogun níbẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ àìrójú kò bá a kúrò níbi lílo Sunnah yìí.
3/ Ibn ‘Umar – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – máa ń kírun sí òkú lára, lẹ́yìn náà yóò kúrò níbẹ̀, kò sì ní tẹ̀lé e (lọ sí itẹ́), ó máa ń lérò pé èyí gan-an ni títẹ̀lé Sunnah tí ó pé. Kò sì mọ̀ nípa ọlá tí ó wá (nínú àwọn ẹ̀gbàwá) nípa títẹ̀lé e títí tí wọn yóò fi sin ín. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ḥadīth tí Abū Hurayrah– kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá dé etígbọ̀ọ́ rẹ̀, ó ṣe àbàmọ̀ lórí Sunnah tí ó bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Wáá ronú sí pé; kín ni ohun tí ó ṣe?
Ibn ‘Umar – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – jan òkúta wẹẹrẹ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀, lẹ́yìn náà ó wí pé: Dájúdájú a ti ṣe àṣeètó níbi àwọn ẹ̀san ńlá-ńlá tó pọ̀. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1324), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (945).
An-Nawawī – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ẹ̀kọ́ wà níbẹ̀ nípa ohun tí àwọn sàábé wà lórí rẹ̀ nínú ṣíṣe ojúkòkòrò tìtẹ̀lé àwọn àṣẹ Ọlọ́hun nígbà tí ó bá dé ọ̀dọ̀ wọn, àti bíbanújẹ́ lórí ohun tí ó bá bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ nínú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọn kò mọ títóbi ipò rẹ̀ tẹ́lẹ̀” Wo: Al-Minhāj (7/15).
Díẹ̀ nínú àwọn àǹfààní títẹ̀lé Sunnah
Títẹ̀lé Sunnah – ìrẹ ọmọ-ìyá mi nínú ẹ̀sìn Islām, tí ó jẹ́ olólùfẹ̀ẹ́ mi – ní àwọn àǹfààní tó pọ̀, nínú rẹ̀ ni:
1/ Dídé ipò nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́hun, nítorí pé pẹ̀lú wíwá ìsúnmọ́ Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n, pẹ̀lú kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ, ni ẹrúsìn Ọlọ́hun fi máa ń rí ìfẹ́ Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n.
Ibn Al-Qayyim – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ọlọ́hun kò ní fẹ́ràn rẹ àyàfi nígbà tí o bá tẹ̀lé olólùfẹ̀ẹ́ Rẹ̀, ní ìkọ̀kọ̀ àti gbangba, tí ó gba ìró tí ó múwá gbọ́, tí ó tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, tí ó dáhùn ìpèpè rẹ̀, tí o mọ̀ọ́mọ̀ gbé ọlá fún un, tí o bọ́pá-bọ́sẹ̀ níbi ìdájọ́ ẹni tí ó yàtọ̀ sí i nítorí ìdájọ́ rẹ̀, àti kúrò níbi ìfẹ́ ẹni tí ó yàtọ̀ sí i nítorí ìfẹ́ rẹ̀, àti kúrò níbi títẹ̀lé ẹni tí ó yàtọ̀ sí i nítorí títẹ̀lé àṣẹ rẹ̀. Tí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe káàárẹ̀, ṣẹ́rí padà láti ibi tí ó bá fẹ́, kí ó sì lọ wá ìmọ́lẹ̀, nítorí pé o kò sí lórí nǹkankan”. Wo: Madārijus-Sālikīn (3/37).
2/ Rírí wíwàpẹ̀lúni Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – ẹrúsìn Ọlọ́hun, nítorí náà Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, yóò fi í ṣe kòǹgẹ́ oore, kò sì ní máa fi àwọn oríkèé ara rẹ̀ ṣe nǹkankan àyàfi ohun tí yóò yọ́ Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n, nínú, nítorí pé nígbà tí ó bá ti rí ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, dájúdájú yóò rí ìwàpẹ̀lúni Rẹ̀.
3/ Gbígba àdúà ẹrúsìn Ọlọ́hun, èyí tí ó kó rírí ìfẹ́ Ọlọ́hun sínú. Nítorí pé ẹni kẹ́ni tí ó bá wá sísúnmọ́ Ọlọ́hun pẹ̀lú kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ, dájúdájú yóò rí ìfẹ́ Ọlọ́hun, ẹni kẹ́ni tí ó bá sì ti rí ìfẹ́ Ọlọ́hun, dájúdájú yóò rí gbígbà àdúà.
Ìtọ́ka àwọn àǹfààní mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí nìyí:
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú Ọlọ́hun sọ wí pé: Ẹni kẹ́ni tí ó bá mú àyànfẹ́ Mi kankan ní ọ̀tá, dájúdájú mo ti kéde fún un pé màá gbógun tì í. Àti pé ẹrúsìn Mi kò le wá ìsúnmọ́ Mi pẹ̀lú nǹkankan tí ó wù Mí ju ohun tí mo ṣe lọ́ranyàn lé e lórí lọ. Àti pé ẹrúsìn Mi kò ní yé máa súnmọ́ Mi pẹ̀lú kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ títí tí màá fi fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà tí mo bá ti fẹ́ràn rẹ̀ tán, màá ṣọ́ ìgbọràn rẹ̀, èyí tí ó fi ń gbọ́ràn, àti ìríran rẹ̀, èyí tí ó fi ń ríran, àti ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó fi ń gbá nǹkan mú, àti ẹsẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó fi ń rìn. Tí ó bá tọrọ nǹkan ní ọ̀dọ̀ Mi, dájúdájú màá fún un, tí ó bá sì wá ìṣọ́ ní ọ̀dọ̀ Mi, dájúdájú màá ṣọ́ ọ. Mi ò da ohun kankan tí mo fẹ́ ṣe wò rí, bíi dída gbígba ẹ̀mí olùgbàgbọ́ òdodo wò Mi, ò kórìíra ikú, Èmi náà sì kórìíra ṣíṣe àìda sí i”Al-Bukhārī ni ó gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6502).
Pípé àdínkù tí ó bá wà níbi àwọn ìrun ọ̀ranyàn, nítorí pé kíkí àwọn ìrun àkígbọrẹ máa ń pé àwọn àbùjẹkù tí ó bá wà níbi àwọn ìrun ọ̀ranyàn.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Abū Hurayrah –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- gbà wá, ó sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Dájúdájú àkọ́kọ́ ohun tí wọn yóò ṣe ìṣirò ẹrúsìn Ọlọ́hun lórí rẹ̀ ní ọjọ́ Ìgbéǹde, nínú iṣẹ́ rẹ̀ ni ìrun. Tí ó bá dára, dájúdájú ó ti jèrè, ó sì ti là, tí ó bá sì bàjẹ́, dájúdájú ó ti pòfo, ó sì ti ṣòfò. Tí nǹkankan bá dínkù nínú ìrun ọ̀ranyàn rẹ̀, Ọlọ́hun, Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n, yóò sọ wí pé: “Ẹ wò ó; ṣé ẹrúsìn Mi ní nǹkankan nínú iṣẹ́ àṣegbọrẹ? Wọn yóò sì pé ohun tí ó bá dínkù nínú ọ̀ranyàn rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, lẹ́yìn náà gbogbo iṣẹ́ rẹ yóò wá lórí èyí” Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (9494), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (864), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (413), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 1/405).
Kàn sí wa
Sí wa
Yóò dùn mọ́wa kí á rí àwọn ìpè rẹ àti àwọn ìbéèrè rẹ ní ìgbà kíìbà