brightness_1
Nínú Sunnah ni kí á bẹ̀rẹ̀ bàtà wíwọ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún
Nínú Sunnah, nígbà tí Mùsùlùmí bá fẹ́ wọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, ni kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún. Nínú Sunnah, nígbà tí ó bá fẹ́ bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, ni kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ òsì.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Nígbà tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá fẹ́ wọ bàtà, kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún, nígbà tó bá fẹ́ bọ́ ọ, kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ òsì. Ẹsẹ̀ ọ̀tún ni ó gbọdọ̀ jẹ́ àkọ́kọ́ tí a ó wọ̀ nínú ẹsẹ̀ méjèèjì, òun ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a ó bọ́ gbẹ̀yìn nínú àwọn méjèèjì”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5856).
Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn ti Mùslim gbà wá: “Ẹni kẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ máa rìn pẹ̀lú bàtà ẹsẹ̀ kan. Kí ó wọ méjèèjì papọ̀ tàbí kí bọ́ àwọn méjèèjì lápapọ̀”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2097).
Sunnah mẹ́ta wà nínú Ḥadīth méjèèjì yìí:
1. Kí á máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún, nígbà tí a bá fẹ́ wọ̀ bàtà.
2. Kí á máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ òsì, nígbà tí a bá fẹ́ bọ́ bàtà.
3. Kí á máa wọ bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì papọ̀, tàbí kí á bọ́ méjèèjì lápapọ̀, kí á má baà máa rìn pẹ̀lú bàtà ẹsẹ̀ kan.