Nínú Sunnah ni kí á bẹ̀rẹ̀ bàtà wíwọ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún
Nínú Sunnah, nígbà tí Mùsùlùmí bá fẹ́ wọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, ni kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún. Nínú Sunnah, nígbà tí ó bá fẹ́ bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì, ni kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ òsì.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Nígbà tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá fẹ́ wọ bàtà, kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún, nígbà tó bá fẹ́ bọ́ ọ, kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ òsì. Ẹsẹ̀ ọ̀tún ni ó gbọdọ̀ jẹ́ àkọ́kọ́ tí a ó wọ̀ nínú ẹsẹ̀ méjèèjì, òun ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a ó bọ́ gbẹ̀yìn nínú àwọn méjèèjì”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5856).
Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn ti Mùslim gbà wá: “Ẹni kẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ máa rìn pẹ̀lú bàtà ẹsẹ̀ kan. Kí ó wọ méjèèjì papọ̀ tàbí kí bọ́ àwọn méjèèjì lápapọ̀”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2097).
Sunnah mẹ́ta wà nínú Ḥadīth méjèèjì yìí:
1. Kí á máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún, nígbà tí a bá fẹ́ wọ̀ bàtà.
2. Kí á máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ òsì, nígbà tí a bá fẹ́ bọ́ bàtà.
3. Kí á máa wọ bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì papọ̀, tàbí kí á bọ́ méjèèjì lápapọ̀, kí á má baà máa rìn pẹ̀lú bàtà ẹsẹ̀ kan.
Nínú Sunnah ni mímáa wọ aṣọ funfun
Ohun tí a gbà lérò ni kí ó máa wọ̀, nínú àwọn àwọ̀ tí yóò wà lára aṣọ rẹ̀ (èyí tó jẹ́ fúnfún), nítorí pé dájúdájú Sunnah ni. Nítorí Ḥadīth tí Ibn ‘Abbās – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì –gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹ máa wọ, nínú àwọn aṣọ yín, èyí tó funfun, nítorí pé dájúdájú ó jẹ́ ara aṣọ yín tó ní oore jùlọ, ẹ sì máa fi sin òkú yín”. Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (2219), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3878), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (994), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 1/267).
Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Èyí kó wíwọ àwọn aṣọ funfun sínú: Bóyá ẹ̀wù ni, ìró ni tàbí sòkòtò. Gbogbo rẹ̀ wà lára aṣọ tó pàtàkì kó jẹ́ funfun. Nítorí pé dájúdájú òun ni ó lọ́lá jùlọ. Ṣùgbọ́n tó bá wọ aṣọ tó jẹ àwọ̀ mìíràn, kò sì aburú níbẹ̀, pẹ̀lú májẹ̀mu pé kí ó má jẹ́ ara ohun tó ṣẹ̀ṣà pẹ̀lú àwọ́n obìnrin”. Wo: Sharḥu Riyāḍiṣ-ṣāliḥīn (2/1087), èyí tí Àlùfáà wa àgbà yìí ṣe.
Nínú Sunnah ni mímáa lo lọ́fínńdà
Nítorí Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Nínú gbogbo ohun tí ń bẹ láyé, wọ́n fi ìfẹ́ àwọn obìnrin àti lọ́fínńdà sími lọ́kàn, wọ́n sì fi ìtutù ojú mi síbi ìrun kíkí”. Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (12293), An-Nasā’ī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3940), Al-Albānī, nínú Ṣaḥīḥun- Nasā’ī, sọ wí pé: “Ó jẹ́ Ḥadīth tí ó dára, tí ó sì ní àlááfìà”.
Ṣùgbọ́n sísọ ẹ̀gbàwá yìí pẹ̀lú gbólóhùn: “Wọ́n fi ìfẹ́ nǹkan mẹ́ta sí mi lọ́kàn nínú ilé ayé yín yìí”, jẹ́ ohun tó lẹ.
– Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – máa ń kórìíra kí wọ́n máa rí òórùn burúkú lára rẹ̀: Dájúdájú ó wá, lọ́dọ̀ Al-Bukhārī, nínú Ḥadīth tó gùn, láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, ó sọ pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – jẹ́ ẹni tí ó máa ń le lára rẹ̀ kí wọ́n rí òórùn burukú lára rẹ̀”. Al-Bukhārīgbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6872), ìtumọ̀ èyí ni òórùn tí kó dára.
Wọ́n kórìíra dídá lọ́fínńdà padà.
Nítorí Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: “Dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – kì í dá lọ́fínńdà padà”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2582).
Nínú Sunnah ni mímáa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú apá ọ̀tún, nígbà tí a bá fẹ́ yarun
Ohun tí a gbá lérò pẹ̀lú yíya ìrun ni: Fífi ìyarun yà á. Dájúdájú nínú Sunnah ni kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú apá ọ̀tún, lẹ́yìn náà apá òsì.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí ‘Ā’ishah –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- gbà wá, ó sọ wí pé: “Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – jẹ́ ẹni tí bíbẹ̀rẹ̀ ṣíṣe nǹkan pẹ̀lú ọ̀tún kún lójú, níbi wíwọ bàtà rẹ̀, yíyarun rẹ̀, ìmọ́ra rẹ̀ àti gbogbo ìṣesí rẹ̀ pátápátá”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (168), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (228).
Kàn sí wa
Sí wa
Yóò dùn mọ́wa kí á rí àwọn ìpè rẹ àti àwọn ìbéèrè rẹ ní ìgbà kíìbà