brightness_1
Nínú Sunnah ni : Mímáa sálámà
Àwọn ẹ̀rí lórí jíjẹ́ Sunnah rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ, nínú rẹ̀ ni: Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Iwọ̀ Mùsùlùmí lórí Mùsùlùmí, mẹ́fà ni”. Wọ́n bi í léèrè pé: Àwọn dà, ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun? Ó sọ wí pé: “Nígbà tí o bá pàdé rẹ̀, sálámà sí i. Nígbà tí ó bá pè ẹ́, dá a lóhùn. Nígbà tó bá béèrè fún ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ̀, gbà á ní ìmọ̀ràn. Nígbà tó bá sín, tí ó sì ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun, kí i (pẹ̀lú kí ó sọ pé: Yarḥamukallāh {Ọlọ́hun yóò kẹ́ ọ}). Nígbà tó bá ṣe àárẹ̀, bẹ̀ ẹ́ wò. Nígbà tó bá kú, tẹ̀lé òkú rẹ̀ (lọ sí itẹ́)”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2162).
– Ṣùgbọ́n dídáhùn rẹ̀: Dandan ni. Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, tó sọ pé: “Nígbà tí wọ́n bá ki yín pẹ̀lú kíkí kan, ẹ yáa kí wọn pẹ̀lú èyí tó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà. Dájúdájú Ọlọ́hun jẹ́ Olùṣèṣirò gbogbo nǹkan” [An-Nisā’: 86].
Ìpìlẹ̀ níbi àṣẹ pípa ni pé, ọ̀ranyàn ni kí á mú un lò, ní òpin ìgbà tí kò bá ti sí ohun tí yóò gbé e kúrò níbi jíjẹ́ ọ̀ranyàn. Àwọn onímímọ̀, tí kì í ṣe ẹyọ̀kan mọ, gba ìpanupọ̀ àwọn onímímọ̀ lórí jíjẹ́ ọ̀ranyàn dídáhùn sálámà wá. Nínú wọn ni: Ibn Ḥazm, Ibn ‘Abdil-Barr, àgbà Àlùfáà, Taqiyyud-dīn àti ẹni tó yàtọ̀ sí wọn – kí Ọlọ́hun kẹ́ gbogbo wọn –. Wo: Al-’Ādābush-shar‘iyyah (1/356), àtẹ̀jáde Mu’assasatur-Risālah.
Èyí tó lọ́lá jùlọ nínú ọ̀rọ̀ tí a le fi sálámà, tí a le fi dáhùn rẹ̀, tí ó sí jẹ́ wí pé òun ni ó pé jùlọ ni: (As-salāmu ‘alaykum waraḥmatul-Lāhi wabarakātuh {Àlááfíà kí ó máa bẹ fún yín, àti ìkẹ́ Ọlọ́hun àti àlùbáríkà Rẹ̀}). Dájúdájú èyí ni ìkíni tó dára jùlọ, tó sì pé jùlọ.
Ibn Al-Qayyim – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ìlànà rẹ̀, – ẹni tó gbà lérò ni Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ni kí sálámà parí síbi: (Wabarakātuh {àti àlùbáríkà Rẹ̀})”. Wo: Zādul-Ma‘ād (2/417).
Sunnah ni fífọ́n sálámà ká; kódà ó jẹ́ Sunnah tí wọ́n ṣe wá ní ojú kòkòrò rẹ̀ pẹ̀lú ọlá tó tóbi; nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Mo fi Ẹni tí ẹ̀mí mi wà lọ́wọ́ Rẹ̀ búra; ẹ kò le wọ ọgbà ìdẹ̀ra Al-Jannah títí tí ẹ ó fi gbágbọ́ lódodo, ẹ kò sì le gbàgbọ́ lódodo títí tí ẹ ó fi fẹ́ràn ara yín. Ṣé kí n tọ́ka yín sí nǹkankan tó jẹ́ wí pé tí ẹ bá ṣe é, ẹ ó fẹ́ràn ara yìn? Ẹ máa fọ́n sálámà ká láàrin ara yín” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (54).