Àwọn ẹ̀rí lórí jíjẹ́ Sunnah rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ, nínú rẹ̀ ni: Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Iwọ̀ Mùsùlùmí lórí Mùsùlùmí, mẹ́fà ni”. Wọ́n bi í léèrè pé: Àwọn dà, ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun? Ó sọ wí pé: “Nígbà tí o bá pàdé rẹ̀, sálámà sí i. Nígbà tí ó bá pè ẹ́, dá a lóhùn. Nígbà tó bá béèrè fún ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ̀, gbà á ní ìmọ̀ràn. Nígbà tó bá sín, tí ó sì ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun, kí i (pẹ̀lú kí ó sọ pé: Yarḥamukallāh {Ọlọ́hun yóò kẹ́ ọ}). Nígbà tó bá ṣe àárẹ̀, bẹ̀ ẹ́ wò. Nígbà tó bá kú, tẹ̀lé òkú rẹ̀ (lọ sí itẹ́)”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2162).
– Ṣùgbọ́n dídáhùn rẹ̀: Dandan ni. Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, tó sọ pé: “Nígbà tí wọ́n bá ki yín pẹ̀lú kíkí kan, ẹ yáa kí wọn pẹ̀lú èyí tó dára jù ú lọ tàbí kí ẹ dá a padà. Dájúdájú Ọlọ́hun jẹ́ Olùṣèṣirò gbogbo nǹkan” [An-Nisā’: 86].
Ìpìlẹ̀ níbi àṣẹ pípa ni pé, ọ̀ranyàn ni kí á mú un lò, ní òpin ìgbà tí kò bá ti sí ohun tí yóò gbé e kúrò níbi jíjẹ́ ọ̀ranyàn. Àwọn onímímọ̀, tí kì í ṣe ẹyọ̀kan mọ, gba ìpanupọ̀ àwọn onímímọ̀ lórí jíjẹ́ ọ̀ranyàn dídáhùn sálámà wá. Nínú wọn ni: Ibn Ḥazm, Ibn ‘Abdil-Barr, àgbà Àlùfáà, Taqiyyud-dīn àti ẹni tó yàtọ̀ sí wọn – kí Ọlọ́hun kẹ́ gbogbo wọn –. Wo: Al-’Ādābush-shar‘iyyah (1/356), àtẹ̀jáde Mu’assasatur-Risālah.
Èyí tó lọ́lá jùlọ nínú ọ̀rọ̀ tí a le fi sálámà, tí a le fi dáhùn rẹ̀, tí ó sí jẹ́ wí pé òun ni ó pé jùlọ ni: (As-salāmu ‘alaykum waraḥmatul-Lāhi wabarakātuh {Àlááfíà kí ó máa bẹ fún yín, àti ìkẹ́ Ọlọ́hun àti àlùbáríkà Rẹ̀}). Dájúdájú èyí ni ìkíni tó dára jùlọ, tó sì pé jùlọ.
Ibn Al-Qayyim – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ìlànà rẹ̀, – ẹni tó gbà lérò ni Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ni kí sálámà parí síbi: (Wabarakātuh {àti àlùbáríkà Rẹ̀})”. Wo: Zādul-Ma‘ād (2/417).
Sunnah ni fífọ́n sálámà ká; kódà ó jẹ́ Sunnah tí wọ́n ṣe wá ní ojú kòkòrò rẹ̀ pẹ̀lú ọlá tó tóbi; nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Mo fi Ẹni tí ẹ̀mí mi wà lọ́wọ́ Rẹ̀ búra; ẹ kò le wọ ọgbà ìdẹ̀ra Al-Jannah títí tí ẹ ó fi gbágbọ́ lódodo, ẹ kò sì le gbàgbọ́ lódodo títí tí ẹ ó fi fẹ́ràn ara yín. Ṣé kí n tọ́ka yín sí nǹkankan tó jẹ́ wí pé tí ẹ bá ṣe é, ẹ ó fẹ́ràn ara yìn? Ẹ máa fọ́n sálámà ká láàrin ara yín” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (54).
Bíi kí ó máa siyèméjì nípa gbígbọ́ ẹni tí a sálámà sí, nígbà tó sálámà sí i ní àkọ́kọ́. Wọ́n fẹ́ kí ó pààrà rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mejí, tí kò bá gbọ́, kí ó sọ ọ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta. Bẹ́ẹ̀ náà ni tó bá wọlé tọ àkójọpọ̀ àwọn èèyàn tó pọ̀, bíi kí ó wọlé tọ àwọn èèyàn tó wà ní ibùjokòó tó tóbi, tí àwọn èèyàn tó pọ̀ wà níbẹ̀. Tí ó bá sálámà ní ẹ̀ẹ̀kan nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wolé, ẹnì kankan kò ní gbọ́ ọ àyàfi àwọn tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ibùjokòó náà. Nítorí náà ó bùkáátà sí kó sálámà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, nítorí kí ó le kárí gbogbo ẹni tó wà ní ibùjokòó náà.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pé: “Dájúdájú nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀, ó máa ń pààrà rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta, títí tí wọn yóò fi gbọ́ ohun tó ń sọ yé. Tí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn kan, tó sì sálámà sí wọn, yóò sálámà sí wọn ní ẹ̀ẹ̀mẹta” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (95).
A ó rí i fàyọ láti inu Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, èyí tó síwájú; jíjẹ́ Sunnah pípààrà ọ̀rọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta tí bùkáátà bá pèpè fún pípààrà rẹ̀, bíi kí ó sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n kò gbọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ yé, wón ṣe é ní Sunnah fún un kí ó pààrà rẹ̀, tí wọn kò bá tún gbọ́ ọ yé, yóò tún un pààrà ní ẹ̀ẹ̀kẹta.
Nítorí Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – pé: “Dájúdájú ọkùnrin kan bí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – léèrè pé: Ìwà wo ní ó dára jùlọ nínú ẹ̀sìn Islām? Ó sọ wí pé: “Kí o máa fún èèyàn ní oúnjẹ jẹ, kí ó sì máa sálámà sí ẹni tí ó mọ̀ àti ẹni o kò mọ̀”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (12), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (39).
Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni tó gun nǹkan ni yóò sálámà sí ẹni tó ń fi ẹsẹ̀ rìn, ẹni tó ń fi ẹsẹ̀ rìn yóò sálámà sí ẹni tó jòkòó, àwọn tó kéré ní òǹkà yóò sálámà sí àwọn tó pọ̀ ní òǹkà” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6233), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2160). Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Al-Bukhārī gbà á wá : “Ọmọdé yóò sálámà sí àgbàlagbà, ẹni tó ń rékọjá yóò sálámà sí ẹni tó jòkòó, àwọn tó kéré ní òǹkà yóò sálámà sí àwọn tó pọ̀ ní òǹkà” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6234).
Ṣùgbọ́n yíyapa ẹni tó dára jùlọ láti bẹ̀rẹ̀ sálámà kò túmọ̀ sí pé ó jẹ́ ohun tí a kórìíra. Kódà kò sí ohun tó burúkú níbẹ̀. Ṣùgbọ́n ó yapa ohun tó dára jùlọ, bíi kí àgbàlagbà sálámà sí ọmọdé tàbí kí ẹni tó ń rìn sálámà sí ẹni tó gun nǹkan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nítorí Ḥadīth tí ’Anas ọmọ Mālik – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: “Dájúdájú òun ń rìn lọ pẹ̀lú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ó sì rékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọdè, ó sì sálámà sí wọn”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6247), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2168).
Níbi mímáa sálámà sí àwọn ọmọdè: Jíjẹ́ kí ẹ̀mí ní ìtẹríba wà níbẹ̀ àti jíjẹ́ kí àwọn ọmọdè bá àmì ẹ̀sìn yìí sáábà àti títa á jí nínú ẹ̀mí wọn.
Èyí yóò wọnú ẹ̀rí gbogboogbò tó wà fún sísálámà. Èyí yóò wáyé lẹ́yìn tó bá rin pákò tán. Nítorí Sunnah ni rírin pákò nígbà tí a bá wọlé. Èyí ni ààyè kẹrin nínú àwọn ààyè tí rírin pákò ti jẹ́ Sunnah tí ó kanpá, èyí ni ìgbà tí a bá wọlé. Nítorí Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, èyí tó wà ní ọ̀dọ̀ Muslim. Ó sọ wí pé: “Dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, nígbà tí ó bá wọ inú ilé rẹ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú rínrin pákò” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (253). Tí ó bá ti bẹ̀rẹ̀ wíwọ inú ilé pẹ̀lú pákò rínrìn, yóò wọlé, yóò sì sálámà sí àwọn ara ilé, títí tí ó fi jẹ́ wí pé dájúdájú apákan nínú àwọn onímímọ̀ sọ wí pé: Nínú Sunnah ni kí ó sálámà nígbà tí o bá wọlé, èyíkéyìí ilé, kódà kí ó má sí ẹnì kankan nínú rẹ̀, nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga, tó sọ wí pé: {Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá wọ àwọn ilé kan, ẹ yáa kí ara yín ni kíkí kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun tí ó ní ìbùkún, tí ó dára. Bayìí ni Ọlọ́hun ṣe ń ṣàlàyé àwọn àmì fun yín nítorí kí ẹ le ṣe làákàyè}. [An-Nūr: 61].
Ibn Ḥajar – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ pé: “Ó sì jẹ́ ara ohun tó wọnú ẹ̀rí gbogboogbò tó wà fún sísálámà sí ara ẹni fún ẹni tó bá wọ ààyè tí kò sí ẹnì kankan níbẹ́, nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, Ọba tí ọlá Rẹ̀ ga, tó sọ wí pé: {Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ bá wọ àwọn ilé kan, ẹ yáa sálámà sí ara yín ni}...” Wo: Fatḥul-Bārī, Ḥadīth (6235), àkòrí ọ̀rọ̀ nípa fífọ́n sálámà ká.
Àǹfààní kan: Àkójọpọ̀ gbogbo ohun tó síwájú yìí dá lórí pé dájúdájú wọ́n ṣe Sunnah mẹ́ta ní ìlànà fún wa nígbà tí a bá fẹ́ wọlé:
Àkọ́kọ́ : Dídárúkọ Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – pàápàá jùlọ ní alẹ́ .
Nítorí Ḥadīth tí Jābir ọmọ ‘Abdullāh – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá pé; dájúdájú òun gbọ́ tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Nígbà tí èèyàn bá wọ ilé rẹ̀, tí ó bá dárúkọ Ọlọ́hun, nígbà tó fẹ́ wọlé àti nígbà tó fẹ́ jẹun, èṣù yóò sọ (fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀) pé: Kó sì ibùgbé fun yín, kò sì sí oúnjẹ alẹ́. Ṣùgbọ́n tó bá wọlé, tí kò sì dárúkọ Ọlọ́hun nígbà tó fẹ́ wọlé, èṣù yóò sọ (fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀) pé: “Ẹ ti rí ibùgbé”. Tí kò bá sì dárúkọ Ọlọ́hun nígbà tó fẹ́ jẹun, yóò sọ pé: “Ẹ ti rí ibùgbé, ẹ sì ti rí oúnjẹ alẹ́” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2018).
Ìkejì : Pákò rírìn. Nítorí Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá. Dájúdájú mímẹ́nu bà á àti àlàyé àwọn tó gbà á wá ti síwájú.
Ìkẹta : Sísálámà sí àwọn ara ilé .
Báyìí ni Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ti máa ń ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Ḥadīth tí Al-Miqdād ọmọ Al-’Aswad – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ nínú rẹ̀ pé: “... A máa ń fún wàrà, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wa yóò sì mu ìpín rẹ̀, a ó sì gbé ìpín ti Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – fún un. Ó sọ pé: Yóò sì dé lálẹ́, yóò sì sálámà ní ọ̀nà tí kò ní jí ẹni tó sùn sílẹ̀, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí ẹni tí kò sùn gbọ́ ọ.
Sunnah ni fífi sálámà jíṣẹ, bíi kí ẹnì kan sọ fún ọ pé: “Bá mi sálámà sí lágbájá”, dájúdájú nínú Sunnah ni kí ó fi sálámà yìí jíṣẹ́ fún ẹni tí wọ́n fi rán ọ sí .
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Nítorí Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ fún un pé: “Dájúdájú Jibrīl ń sálámà sí ọ”. Ó sọ pé: Mo sì wí pé: Wa‘alyhis-salám waraḥmtullāh (kí ọlà àti ìkẹ́ Ọlọ́hun máa bá òun náà”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3217), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2447).
Ń bẹ nínú Ḥadīth yìí pé a máa ń fi sálámà jíṣẹ́ fún ẹni tí wọ́n fi i rán wa sí, gẹ́gẹ́ bí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ti fi sálámà Jibrīl jíṣẹ́ fún ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –. A ó tún mú jíjẹ́ Sunnah fífi sálámà rán èèyàn nínú Ḥadīth tó síwájú yìí bákan náà.
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Nígbà tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá dé ibi ìjokòó, kí ó sálámà. Nígbà tí ó bá fẹ́ dìde kúrò níbẹ̀, kí ó sálámà. Dájúdájú àkọ́kọ́ kò pàtàkì ju ìkejì lọ” Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (9664), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5208), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2706), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 1/132).
Èyí ni ohun tí àwọn sàábé – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí wọn – máa ń ṣe àmúlò rẹ̀. Ẹ̀rí èyí ni : Ḥadīth tí Qatābah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Mo bi ’Anas léèré pé: Ṣé mímá bọ ara ẹni lọ́wọ́ wà nígbà ayé àwọn sàábé Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bí? Ó dáhùn pé: Bẹ́ẹ̀ ni”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6263).
Nítorí Ḥadīth tí Abū Dharr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ pé: Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Má ṣe fojú rénà nǹkankan nínú dáadáa, kódà kó jẹ́ wí pé wàá pàdé ọmọ-ìyá rẹ̀ nínú ẹ̀sìn Islām pẹ̀lú títújúká” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6226). Ó wà lọ́dọ̀ At-Tirmidhī nínú Ḥadīth tí Abū Dharr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Rírẹ́rìn-ín múṣẹ́ rẹ̀ níwájú ọmọ-ìyá rẹ̀ nínú ẹ̀sìn Islām, ìtọrẹ-àánú ni fún ọ”. At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1956), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Aṣ-Ṣaḥīḥah 572).
Bóyá nígbà tí a bá pàdé ni, tàbí a jókòó papọ̀, tàbí níbi èyíkéyìí ìṣesí wa, mímáa sọ gbólóhùn dáadáa jẹ́ Sunnah, nítorí pé ìtọrẹ-àánú ni.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Gbólóhùn dáadáa, ọrẹ-àánú ni”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2979), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1009).
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ dáadáa máa ń jáde lórí ahọ́n àwọn èèyàn, tí ó bá jẹ́ wí pé wọ́n rankàn ẹ̀san rere lọ́dọ̀ Ọlọ́hun lórí rẹ̀ ni, dájúdájú wọn ò bá san wọ́n lẹ́san dáadáa tó pọ̀ lórí rẹ̀, wọn ì bá sì rí ìpín dáadáa tó pọ̀ gbà lórí àwọn ìtọrẹ-àánú yìí.
Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Gbólóhùn dáadáa, bíi kí ó sọ fún un pé: Báwo ni nǹkan? Báwo ni àwọn arákùnrin rẹ̀?
Báwo ni àwọn ara ilé rẹ̀? Àti ohun tó jọ èyí. Nítorí pé èyí wà lára àwọn gbólóhùn dáadáa, èyí tí yóò máa ti ìdùnnú bọ ọkàn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Gbogbo gbólóhùn dáadáa, ìtọrẹ-àánú ni yóò jẹ́ fún ọ ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun àti ẹ̀san rere àti láádá”. Wo: Sharḥu Riyāḍiṣ-ṣāliḥīn (2/996), èyí tí Àlùfáà wa àgbà yìí ṣe, àkòrí ọ̀rọ̀ nípa jíjẹ́ ohun tí a fẹ́ sísọ ọ̀rọ̀ dáadáa, àti títújúká nígbà tí a bá pàdé.
Àwọn ẹ̀gbàwà Ḥadīth tó wá nípa àwọn ọlá tí ń bẹ fún àwọn ìjokòó ìrántí Ọlọ́hun àti gbígbà wá níyànjú lórí rẹ̀ pọ̀, nínú èyí ni, Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú Ọlọ́hun ní àwọn Malā’ikah kan, wọ́n máa ń rọkiriká àwọn ojú-ọ̀nà, wọ́n máa ń wá àwọn tó máa ń rántí Ọlọ́hun kiri. Nígbà tí wọ́n bá rí àwọn èèyàn kan tí wọ́n ń rántí Ọlọ́hun, wọn yóò máa pe ara wọ pé: Ẹ máa bọ̀ níbi bùkáátà yín. Ó sọ wí pé: Wọn yóò sì bò wọ́n dáru pẹ̀lú ìyẹ́ wọn títí dé sánmà ilé ayé....” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6408), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2689).
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tó bá jókòó sí ibùjokòó kan, tí àṣìṣe rẹ̀ sì pọ̀ níbẹ̀, tí ó wá sọ síwájú kí ó tó dìde kúrò níbi ibùjokòó rẹ̀ náà pé: Subḥānakallāhumma wabiḥamdika ’ashhadu ’an lā ilāha illā ’Anta astaghfiruka wa’atūbu ’ilayk (Mímọ́ ni fún Ọ, Ìrẹ Ọlọ́hun, mo tún ṣe ọpẹ́ àti ẹyìn fún Ọ; mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ nìkan. Mò ń tọrọ àforíjìn Rẹ̀, mo sì ronúpìwàdà lọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀), àyàfi kí wọ́n ṣe àforíjìn ohun tó bá ṣẹlẹ̀ (nínú àṣìṣe) níbi ibùjokòó rẹ̀ náà fún un”. At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3433), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 2/1065).