brightness_1
Dídárúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ oúnjẹ
‘Umar ọmọ Abū Salamah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: “Mo jẹ́ ọ̀dọ́mọdé nínú ilé Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ọwọ́ mi sì máa ń bọ́síhìn-ín bọ́sọ́hùn-ún nínú abọ oúnjẹ, ni Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bá sọ fún mi pé: “Ìrẹ ọ̀dọ́mọkùnrin! Dá orúkọ Ọlọ́hun, máa fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹun, sì máa jẹ́ nínú ohun tó súnmọ́ ọ”. Jíjẹun mi kò yẹ̀ lórí ìṣesí yìí láti ìgbà náà lọ”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5376), Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2022).
Tí ó bá gbàgbé láti dárúkọ Ọlọ́hun, dájúdájú wọ́n ṣe é ní Sunnah fún un, nígbà tó bá rántí, kí ó sọ pé: “Bismillāhi ’awwalahū wa’ākhirah (Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ àti ní ìparí rẹ̀)”.
Nítorí Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yìn bá fẹ́ jẹun, kí ó dárúkọ Ọlọ́hun. Ṣùgbọ́n tó bá gbàgbé láti dárúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kí ó yáa sọ pé: “Bismillāhi ’awwalahū wa’ākhirah (Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ àti ní ìparí rẹ̀)”. Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3767), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1858), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà, gẹ́gẹ́ bí ó ti síwájú.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Ḥadīth yìí tọ́ka sí wí pé ọwọ́ ọ̀tún ni èèyàn gbọdọ̀ máa fi jẹun, nítorí kí ó má baà ṣe jọ èṣù. Nítorí pé tí Mùsùlùmí kò bá dárúkọ Ọlọ́hun, èṣù yóò bá a kópa níbi oúnjẹ rẹ̀. Tí ó bá sì jẹun, tàbí ó mu nǹkan pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀, yóò jọ èṣù pẹ̀lú èyí, nítorí pé dájúdájú èṣù máa ń jẹun, ó sì máa ń mu nǹkan pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Umar – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹnì kankan nínú yín kò gbọdọ̀ máa jẹun pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ mu nǹkan pẹ̀lú rẹ̀, nítorí pé dájúdájú èṣù máa ń jẹun pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀, ó sì máa ń mu nǹkan pẹ̀lú rẹ̀”. Ó sọ pé: Nāfi‘u máa ń fi kún un pé: “Kò gbọdọ̀ máa gba nǹkan pẹ̀lú rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ máa fún èèyàn ní nǹkan pẹ̀lú rẹ̀”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2020).
Èṣù máa ń ṣe ojú kòkòrò láti wọ àwọn ilé, nítorí kí ó le sùn síbẹ̀, kí ó sì bá àwọn onílé kópa níbi oúnjẹ àti ohun mímu. Jābir ọmọ ‘Abdullāh – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà á wá pé; dájúdájú òun gbọ́ tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Nígbà tí èèyàn bá wọ ilé rẹ̀, tí ó bá dárúkọ Ọlọ́hun, nígbà tó fẹ́ wọlé àti nígbà tó fẹ́ jẹun, èṣù yóò sọ (fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀) pé: Kó sì ibùgbé fun yín, kò sì sí oúnjẹ alẹ́. Ṣùgbọ́n tó bá wọlé, tí kò sì dárúkọ Ọlọ́hun nígbà tó fẹ́ wọlé, èṣù yóò sọ (fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀) pé: “Ẹ ti rí ibùgbé”. Tí kò bá sì dárúkọ Ọlọ́hun nígbà tó fẹ́ jẹun, yóò sọ pé: “Ẹ ti rí ibùgbé, ẹ sì ti rí oúnjẹ alẹ́” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2018).