‘Umar ọmọ Abū Salamah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: “Mo jẹ́ ọ̀dọ́mọdé nínú ilé Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ọwọ́ mi sì máa ń bọ́síhìn-ín bọ́sọ́hùn-ún nínú abọ oúnjẹ, ni Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bá sọ fún mi pé: “Ìrẹ ọ̀dọ́mọkùnrin! Dá orúkọ Ọlọ́hun, máa fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹun, sì máa jẹ́ nínú ohun tó súnmọ́ ọ”. Jíjẹun mi kò yẹ̀ lórí ìṣesí yìí láti ìgbà náà lọ”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5376), Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2022).
Tí ó bá gbàgbé láti dárúkọ Ọlọ́hun, dájúdájú wọ́n ṣe é ní Sunnah fún un, nígbà tó bá rántí, kí ó sọ pé: “Bismillāhi ’awwalahū wa’ākhirah (Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ àti ní ìparí rẹ̀)”.
Nítorí Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yìn bá fẹ́ jẹun, kí ó dárúkọ Ọlọ́hun. Ṣùgbọ́n tó bá gbàgbé láti dárúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, kí ó yáa sọ pé: “Bismillāhi ’awwalahū wa’ākhirah (Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Orúkọ Ọlọ́hun ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ àti ní ìparí rẹ̀)”. Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3767), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1858), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà, gẹ́gẹ́ bí ó ti síwájú.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Ḥadīth yìí tọ́ka sí wí pé ọwọ́ ọ̀tún ni èèyàn gbọdọ̀ máa fi jẹun, nítorí kí ó má baà ṣe jọ èṣù. Nítorí pé tí Mùsùlùmí kò bá dárúkọ Ọlọ́hun, èṣù yóò bá a kópa níbi oúnjẹ rẹ̀. Tí ó bá sì jẹun, tàbí ó mu nǹkan pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀, yóò jọ èṣù pẹ̀lú èyí, nítorí pé dájúdájú èṣù máa ń jẹun, ó sì máa ń mu nǹkan pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Umar – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹnì kankan nínú yín kò gbọdọ̀ máa jẹun pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ mu nǹkan pẹ̀lú rẹ̀, nítorí pé dájúdájú èṣù máa ń jẹun pẹ̀lú ọwọ́ òsì rẹ̀, ó sì máa ń mu nǹkan pẹ̀lú rẹ̀”. Ó sọ pé: Nāfi‘u máa ń fi kún un pé: “Kò gbọdọ̀ máa gba nǹkan pẹ̀lú rẹ̀, kò sì gbọdọ̀ máa fún èèyàn ní nǹkan pẹ̀lú rẹ̀”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2020).
Èṣù máa ń ṣe ojú kòkòrò láti wọ àwọn ilé, nítorí kí ó le sùn síbẹ̀, kí ó sì bá àwọn onílé kópa níbi oúnjẹ àti ohun mímu. Jābir ọmọ ‘Abdullāh – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà á wá pé; dájúdájú òun gbọ́ tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Nígbà tí èèyàn bá wọ ilé rẹ̀, tí ó bá dárúkọ Ọlọ́hun, nígbà tó fẹ́ wọlé àti nígbà tó fẹ́ jẹun, èṣù yóò sọ (fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀) pé: Kó sì ibùgbé fun yín, kò sì sí oúnjẹ alẹ́. Ṣùgbọ́n tó bá wọlé, tí kò sì dárúkọ Ọlọ́hun nígbà tó fẹ́ wọlé, èṣù yóò sọ (fún àwọn ọmọ-ogun rẹ̀) pé: “Ẹ ti rí ibùgbé”. Tí kò bá sì dárúkọ Ọlọ́hun nígbà tó fẹ́ jẹun, yóò sọ pé: “Ẹ ti rí ibùgbé, ẹ sì ti rí oúnjẹ alẹ́” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2018).
‘Umar ọmọ Abū Salamah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: “Mo jẹ́ ọ̀dọ́mọdé nínú ilé Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ọwọ́ mi sì máa ń bọ́síhìn-ín bọ́sọ́hùn-ún nínú abọ oúnjẹ, ni Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bá sọ fún mi pé: “Ìrẹ ọ̀dọ́mọkùnrin! Dá orúkọ Ọlọ́hun, máa fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹun, sì máa jẹ́ nínú ohun tó súnmọ́ ọ”. Jíjẹun mi kò yẹ̀ lórí ìṣesí yìí láti ìgbà náà lọ”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5376), Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2022).
Nítorí Ḥadīth tí Jābir – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Dájúdájú èṣù máa ń wá bá ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú yín níbi gbogbo nǹkan nínú ìṣesí rẹ̀, títí tó fi jẹ́ pé ó máa ń wá bá a nígbà tó bá ń jẹun. Nítorí náà tí òkèlè oúnjẹ bá jábọ́ lọ́wọ́ ẹni kẹ́ni nínú yín, kí ó nu ohun tó wà lára rẹ̀ nínú ìdọ̀tí dànù, lẹ́yìn náà kí ó jẹ ẹ́, kí ó má fi sílẹ̀ fún èṣù. Nígbà tó bá jẹun tán, kí ó lá àwọn ìka ọwọ́ rẹ̀, nítorí pé dájúdájú kò mọ ara èwo, nínú oúnjẹ rẹ̀, ni àlùbáríkà yóò wà” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2023).
Ẹni tó bá ronú jinlẹ̀ sí Ḥadīth yìí, yóò rí i pé èṣù máa ń ṣe ojú kòkòrò láti bá èèyàn kópa níbi gbógbó ọ̀ràn rẹ̀, nítorí kí ó le yọ àlùbáríkà kúrò nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, kí ó sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ìṣesí rẹ̀ jẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Nínú ohun tó ń tọ́ka sí ṣíṣe ojú kòkòrò rẹ̀ lórí dídúnní mọ́ ẹrúsìn Ọlọ́hun níbi gbogbo ọ̀ràn rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú èṣù máa ń wà pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú yín níbi gbogbo nǹkan nínú ìṣesí rẹ̀”.
Lílá a ni : Kí ó fi etí ahọ́n rẹ̀ lá a. Sunnah ni kí òun gan-an-gan lá a, tábí kí ẹlòmíràn yàtọ̀ sí i bá a lá a, bíi ìyàwó rẹ̀ ní àpèjúwe. Kòdà Sunnnah ni kí ó má nu ohun tó bá yí i lọ́wọ́ nù, pẹ̀lú aṣọ ìléwọ́, tàbí ohun tó jọ ọ́, títí tí yóò fi lá a.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Jābir – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, èyí tí ó ti síwájú .
Nínú Ṣaḥīḥu méjèèjì, nínú Ḥadīth tí Ibn ‘Abbās – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá ń jẹun, kò gbọdọ̀ nu ọwọ́ rẹ̀ nù títí tí yóò fi lá a tàbí kí wọ́n bá a lá a” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5457), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2033).
Ohun tí a gbà lérò pẹ̀lú lílá abọ́ ni: Kí ẹni tí ń jẹun mọ́ abala ibi tí ó ti jẹun. Ní àpèjúwe: Ẹni tó bá ń jẹ ìrẹsì, dájúdájú Sunnah ni kí ó má fi nǹkankan sílẹ̀ ní abala ọ̀dọ̀ rẹ̀ tó ti ń jẹun. Nítorí náà yóò fá ohun tó bá ṣẹ́kù ní abala ọ̀dọ̀ rẹ̀ jọ, yóò sì jẹ ẹ́. Dájúdájú o le jẹ́ pé ara èyí tó ṣẹ́kù yìí ni àlùbáríkà wà.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, gbà wá, ó sọ wí pé: “Ó (Ànábí) – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – tún pa wá láṣẹ kí á máa lá abọ́” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2033). Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tí Muslim gbà wá, nínú Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá: “Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú yín sì lá abọ́ rẹ̀”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2035).
Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ìtumọ̀ èyí ni pé: Kí ó fa ohun tó bá lẹ̀ mọ́ ọn nínú oúnjẹ jọ pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ rẹ̀, kí ó sì lá a, èyí bákan náà wà lára Sunnah tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ nínú àwọn èèyàn ti gbàgbé rẹ̀, pẹ̀lú ìbànújẹ́, títí kan àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn bákan náà” Wo: Sharḥu Riyāḍiṣ-ṣāliḥīn (1/892).
Sunnah ni kí ó máa jẹun pẹ̀lú ìka mẹ́ta. Èyí wà fún ohun tí a máa ń fi ìka mẹ́ta gbé, bíi dàbínù, ní àpèjúwe. Wọ́n ṣe é ní Sunnah kí ó máa jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìka mẹ́ta.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Ka‘b ọmọ Mālik – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – máa ń jẹun pẹ̀lú ìka mẹ́ta, ó sì máa ń lá ọwọ́ rẹ̀ síwájú kí ó tó nù ún nù”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2032).
Nínú Sunnah ni kí ó mumi nínú ife pẹ̀lú gẹ̀ẹ́ mẹ́ta, kí ó sì mí síta lẹ́yìn gbogbo gẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan .
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, gbà wá, ó sọ wí pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – máa ń mí síta nígbà tó bá ń mumi ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì máa ń sọ wí pé: “Dájúdájú òun ni ó rẹ̀ǹgbẹ júlọ, òun ni ó le la èèyàn níbi ìrora òǹgbẹ jùlọ, òun ni ó sì lọ tìrín tìrín ní ọ̀fun jùlọ”. ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: “Èmi náà máa ń mí síta ohun mímu ní ẹ̀ẹ̀mẹta” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5631), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2028).
Ohun tí wọ́n gbà lérò pẹ̀lú mímí sí ife omi ni: Mímí nígbà tí ó bá ń mumi lọ́wọ́ láti inú ife. Èyí túmọ̀ sí pé: Kí ó mí sí ìta ife, nítorí pé mímí sínú ife jẹ́ ohun tí a kórìíra nínú ẹ̀sìn Islām. Nítorí Ḥadīth tí Abū Qatādah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, nínú Ṣaḥīḥu méjèèjì, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá ń mumi, kò gbọdọ̀ máa mí sínú ife omi” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5630), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (267).
Ìtọ́ka Sunnah yìí ni:
Ḥadīth tí ’Anas ọmọ Mālik – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú Ọlọ́hun máa ń yọ́nú sí i fún ẹrúsìn Rẹ̀, kí ó jẹun tán, kí ó ṣe ọpẹ́ àti ẹyìn fún Un lórí rẹ̀, kí ó mu nǹkan tán, kí ó ṣe ọpẹ́ àti ẹyìn fún Un lórí rẹ̀”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2743).
Ṣíṣe ọpẹ́ àti ẹyìn fún Ọlọ́hun ní àwọn ẹ̀rọ-ọ̀rọ̀ ọlọ́kan-ò-jọ̀kan, nínú rẹ̀ ni :
a. “Al-ḥamdu lillāhi kathīran ṭayyiban mubārakan fīh, ghayra makfiyyin walā muwadda‘, walā mustaghnan ‘anhu Rabbanā (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe, ní ọpẹ́ tó pọ̀, tó sì dára, tí Ọlọ́hun fi ìbùkún sí i, tí kò ṣe é dú tán, tí kò sì ṣe é patì. Tí a kò sì le rọrọ̀ kúrò níbẹ̀, Ìrẹ Ọlọ́hun Ọba wa!)” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5458).
“Al-ḥamdu lillāhil-ladhī kafānā, wa’arwānā, ghayra makfiyyin walā makfūr (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe, Ẹni tí Ó tó wa, tí Ó sì rẹ̀ wá lóǹgbẹ, ní ọpẹ́ tí kò ṣe é dú tán, tí a kò sì ní ṣe àìmoore rẹ̀(” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5459).
(Ní ọpẹ́ tí kò ṣe é dú tán): Èyí túmọ̀ sí pé kò bùkáátà sí ẹnì kankan, Òun ni Ẹni tó ń fún àwọn ẹrúsìn rẹ̀ ní oúnjẹ, tí Ó sì ǹ tó wọn. (Tí kò sì ṣe é patì), pẹ̀lú fífún háràfí dāl ní àmìn ààrin (fatḥah), àti ṣíṣe àdìpèlé rẹ̀, èyí túmọ̀ sí: Tí a kò patì. (Tí Ó tó wa), wọ́n yọ ọ́ láti ibi kí nǹkan tó èèyàn. (Tí Ó rẹ̀ wá lóǹgbẹ), wọ́n yọ ọ́ láti ibi kí èèyàn mu nǹkan kí òǹgbẹ rẹ̀ sì lọ. (Tí a kò sì ní ṣe àìmoore nípa rẹ̀), èyí túmọ̀ sí pé: A kò ní tako ọlá Rẹ̀ àti ìdẹ̀ra Rẹ̀.
Nínú Sunnah ni kí á kó ara jọ papọ̀ láti jẹun, kí á má fọ́n yẹ́lẹyẹ̀lẹ níbẹ̀ .
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Jābir ọmọ ‘Abdil-Lāh – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá, ó sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Oúnjẹ èèyàn kan ti tó fún èèyàn méjì, oúnjẹ èèyàn méjì ti tó fún èèyàn mẹ́rin, oúnjẹ èèyàn mẹ́rin sì ti tó fún èèyàn mẹ́jọ” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2059).
Nínú Sunnah ni kí èèyàn yin oúnjẹ tí ó kún un lójú. Ṣùgbọ́n kò sí iyèméjì níbi pé kò gbọdọ̀ máa yìn ín pẹ̀lú ohun tí kò sí nínú rẹ̀.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Jābir ọmọ ‘Abdil-Lāh – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé: Dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bèèrè fún omi-ọbẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ara ilé rẹ̀, wọ́n sì wí pé: Kò sí nǹkankan ní ọ̀dọ̀ wa àyàfi ìkẹ̀tẹ́. Ó sì bèèrè fún un, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi i jẹun, ó sì ń wí pé: “Ìkẹ̀tẹ́ má dára jọjọ ní omi-ọbẹ̀ o, ìkẹ̀tẹ́ má dára jọjọ ní omi-ọbẹ̀ o” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2052). Ìkẹ̀tẹ́ jẹ́ ara àwọn ìran omi-ọbẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn Lárúbáwá, ó sì jẹ́ ohun tó dùn, kò kan, gẹ́gẹ́ bíi ìkẹ̀tẹ́ tó wà lọ́dọ̀ wa láyé òde-òní.
Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ –sọ wí pé: “Èyí bákan náà ń bẹ nínú ìlànà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Dájúdájú nígbà tí oúnjẹ bá kún un lójú, yóò ròyìn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà, ní àpèjúwe, ni kí ó yin búrẹ́dì. Kí ó sọ pé: Búrẹ́dì àwọn ọmọ ìdílé lágbájá má dára jọjọ o, tàbí ohun tó jọ èyí. Bákan náà èyí jẹ́ Sunnah Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Wo: Sharḥu Riyāḍiṣ-ṣāliḥīn (2/1057).
Ẹni kẹ́ni tó bá wòye sí ìṣesí wa ní ayé òde-òní, yóò rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn ń kó sínú ohun tó yapa Sunnah Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Wọn kò fi mọ lórí pípa Sunnah tì nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n tún yapa rẹ̀ bákan náà. Èyí ń wáyé pẹ̀lú bí wọ́n ṣe máa ń tàbùkù oúnjẹ àti bí wọ́n ṣe máa ń bẹnu ẹ̀tẹ́ lù ú ní àwọn ìgbà mìíràn. Èyí jẹ́ ohun tó yapa ìlànà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Nínú Ṣaḥīḥu méjèèjì, nínú Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ pé: “ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – kò tàbùkù oúnjẹ kankan rí, tí ó bá wù ú jẹ, yóò jẹ ẹ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóò pa á tì”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3563), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2064).
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ Busr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – wá sí ọ̀dọ̀ bàbá mi, ó sọ pé: Ni a bá gbé oúnjẹ̀ àti wàrà fún un, ó jẹ nínú rẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n gbé dàbínù wá fún un, ó sì ń jẹ nínú rẹ̀, ó sì ń ju kóro rẹ̀ sí ààrin ìka rẹ̀ méjèèjì, ó sì ń pa ìka ìfábẹ̀lá àti ọba ààrin papọ̀. Lẹ́yìn náà wọ́n gbé nǹkan mímu wá fún un, ó mu ún, lẹ́yìn náà ó gbé e fún ẹni tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀. Ó sọ pé: Ni bàbá mi bá sọ, nígbà tó ti gbá ìjánú nǹkan ìgùn rẹ̀ mú, pé: Bẹ Ọlọ́hun fún wa, ó sì wí pé: “Allāhumma bārik lahum fī mā razaqtahum, waghfir lahum, warḥamhum (Ìrẹ Ọlọ́hun! Bá wọn fi àlùbáríkà sí ohun tí Ó fún wọn, ṣe àforíjìn fún wọn, kí Ó sì kẹ́ wọ” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2042).
(Al-Waṭbah) ni: Oúnjẹ tó kó àwọn dàbínù roboto, wàrà gbígbẹ tí wọ́n ti lọ̀ àti òróró sínú.
Ohun tí a gbà lérò ni pé; tó bá mu nǹkan tán, nínú Sunnah ni kí ó fún ẹni tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀ ní nǹkan mu síwájú ẹni tó wá ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ .
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí ’Anas ọmọ Mālik – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – wá bá wa ní ilé wa, ó sì bèèrè fún nǹkan mímu, nítorí náà a fún wàrà àgùntàn kan fún un, lẹ́yìn náà mo pọn fún un nínú omi kanga mi yìí. Ó sọ wí pé: Mo gbé e fún Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun mu, Abū Bakr wà ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀, ‘Umar wà níwájú rẹ̀, lárúbáwá oko kan sí wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀. Nígbà tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun mu tirẹ̀ tán, ‘Umar sọ wí pé: Abū Bakr nìyí, ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun, ó ń fi í hàn án. Ni Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun bá gbé e fún lárúbáwá oko náà, ó sì fi Abū Bakr àti ‘Umar sílẹ̀, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sì sọ wí pé: “Àwọn ara apá ọ̀tún, àwọn ara apá ọ̀tún, àwọn ara apá ọ̀tún”’ ’Anas ọmọ Mālik – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: “Èyí jẹ́ Sunnah, èyí jẹ́ Sunnah, èyí jẹ́ Sunnah”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2571), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2029).
Wọ́n ṣe é ní Sunnah fún ẹni tó bá ń fún àkójọpọ̀ àwọn èèyàn ní nǹkan mu kí ó jẹ́ òun ni yóò mu gbẹ̀yìn .
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Abū Qatādah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, èyí tó gùn, ó wà nínú rẹ̀ pé: “….Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bẹ̀rẹ̀ sí máa ṣẹ́ ẹ, èmi sì ń fún wọn mu, títí tí kò fi ṣẹ́kù ẹnì kankan yàtọ̀ sí èmi àti Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Ó sọ pé: Lẹ́yìn náà Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ṣẹ́ ẹ, ó sì sọ fún mi pé: “Mu”. Mo dáhùn pé: Mi ò ní mu títí wàá fi mu, ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun. Ó sọ wí pé: “Dájúdájú ẹni tó bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan mu, òun ní í mu gbẹ̀yìn nínú wọn”. Ó sọ pé: Nítorí náà mo mu, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun náà sì mu ....” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (681).
Àǹfààní kan : Nínú Sunnah, fún ẹni tó bá mu wàrà ni kí ó fi omi yọ ẹnu rẹ̀ ṣùkùṣùkù, lẹ́yìn tó bá mu wàrà tán, nítorí kí ó le fọ ohun tó bá wà lẹ́nu rẹ̀ nínú ọ̀rá tó máa ń wà nínú wàrà dànù. Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Ibn ‘Abbās – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá pé: “Dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – mu wàrà, ó sì bèèrè fún omi, ó sì yọ ẹnu rẹ̀ ṣùkùṣùkù, ó sì wí pé: “Dájúdájú ó ní ọ̀rá” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (211), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (358).
Wọ́n ṣe bíbo igbà omi tí wọ́n ṣí sílẹ̀ ní Sunnah, nígbà tí òru bá bẹ̀rẹ̀ sí í ru àti dídé – pípa á dé – ife ìmumi tí ó bá ní ọmọrí àti dídárúkọ Ọlọ́hun nígbà tí a bá fẹ́ ṣe èyí.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ḥadīth tí Jābir ọmọ ‘Abdillāh – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá, ó sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Ẹ bo igbá omi, ẹ dé ife, nítorí pé dájúdájú òru kan wà nínú ọdún, àlùbá máa ń sọ̀kalẹ̀ nínú rẹ̀, kò ní rékọjá pẹ̀lú igbá omi tí kò sí gàgá kankan lórí rẹ̀ tàbí ife ìmumi tí kò sí ọmọrí lórí rẹ̀ àyàfi kí díẹ̀ nínú àlùbá náà sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2014). Nínú ẹ̀gbàwá tó wà lọ́dọ̀ Bukhārī, nínú Ḥadīth tí Jābir – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá bákan náà: “Ẹ máa dé àwọn korobá omi yín, ẹ sì dárúkọ Ọlọ́hun sí i, ẹ sì bo àwọn igbá oúnjẹ́ yín, ẹ sì dárúkọ Ọlọ́hun sí i, kó dà kí ó jẹ́ wí pé ẹ ó kan fi nǹkankan dá a lórí kọjá lásán” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5623).