brightness_1
Sunnah ni ó jẹ́ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n máa yára wá sí sááfú àkọ́kọ́
Sunnah ni ó jẹ́ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n máa yára wá sí sááfú àkọ́kọ́, ohun ní ó lọ́lá jùlọ nínú àwọn sááfú, ṣùgbọ́n fún àwọn obìnrin, èyí tí ó lọ́lá jùlọ nínú rẹ̀ ni èyí tí ó bá gbẹ̀yìn nínú rẹ̀.
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Èyí tí ó lóore jùlọ nínú sááfú àwọn ọkùnrin ni àkọ́kọ́ rẹ̀, èyí tí ó burú jùlọ nínú rẹ̀ ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó lóore jùlọ nínú sááfú àwọn obìnrin ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀, èyí tí ó burú jùlọ nínú rẹ̀ ni àkọ́kọ́ rẹ̀” Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (440). Ìtumọ̀ pé òhun ni ó lóore jùlọ ni pé: Òhun ní ẹ̀san rere àti ọlá rẹ̀ pọ̀ jùlọ. Ìtumọ̀ pé òhun ni ó burú jùlọ ni pé: Òhun ní ẹ̀san rere àti ọlá rẹ̀ kéré jùlọ.
Ḥadīth yìí wà fún ìgbà tí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin bá kírun papọ̀, tí kò sì sí gàgá kankan, bóyá ògiri ni tàbí ohun tí ó jọ ọ́, láàrin wọn. Nígbà náà èyí tí ó lóore jùlọ nínú sááfú àwọn obìnrin ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀, nítorí pé dájúdájú ohun ní ó fi wọ́n pamọ́ jùlọ kúrò níbi kí àwọn ọkùnrin máa wò wọ́n. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé gàgá, bóyá ògiri ni tàbí ohun tí ó jọ ọ́, wà láàrin wọn, tàbí gẹ́gẹ́ bí ò ti wà níbi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Mọṣáláṣí wa, ní ayé òde-òní, pẹ̀lú pé wọ́n ṣẹ̀ṣà ààyè ìkírun tí ó dá wà fún àwọn obìnrin nìkan, nínú irú ìṣesí báyìí, èyí tí yóò lọ́lá jùlọ nínú sááfú àwọn obìnrin ni àkọ́kọ́ rẹ̀, nítorí pé ohun tí ó le fa kí wọ́n súnmọ́ àwọn ọkùnrin kò sí mọ́, nítorí pé ìdájọ́ máa ń rìn pẹ̀lú ìdí rẹ̀, bóyá ó ń bẹ ni tàbí kò sí. Àti nítorí ẹ̀rí gbogboogbò tí ó wá lórí lílọ́lá sááfú àkọ́kọ́ nínú àwọn Ḥadīth kan, nínú rẹ̀ ni:
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ó bá jẹ́ wí pé àwọn èèyàn mọ ohun tí ń bẹ níbi ìrun pípè àti sááfú àkọ́kọ́ (nínú ọlá) ni, lẹ́yìn náà tí wọn kò rí ọ̀nà débẹ̀ àyàfi pẹ̀lú kí wọ́n muje, dájúdájú wọn ì bá muje. Tí ó bá sì jẹ́ wí pé wọ́n mọ ohun tí ń bẹ nínú mímáa tètè yára lọ sí Mọṣáláṣí (nínú oore) ni, dájúdájú wọn kò bá gbìyànjú láti gbawájú mọ́ ara wọn lọ́wọ́ lọ síbẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ wí pé wọ́n mọ ohun tí ń bẹ nínú kíkí ìrun alẹ́ – ‘Ishā’ – àti ìrun àárọ̀ (nínú oore) ni, dájúdájú wọn kò bá wá kí méjèèjì, kódà kó jẹ́ wí pé wọ́n yóò rákòrò wá síbẹ̀ ni” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (615), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (437).