Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ó bá ṣe pé wọ́n mọ ohun tí ń bẹ nínú mímáa tètè yára lọ sí Mọṣáláṣí (nínú oore) ni, dájúdájú wọn kò bá gbìyànjú láti gbawájú mọ́ ara wọn lọ́wọ́ lọ síbẹ̀” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (615), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (437).
Tahjīr, ní èdè Yorùbá, ni: Títètè yára lọ sí Mọṣáláṣí.
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ìrun ọkùnrin, pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn Mùsùlùmí, yóò lékún ju ìrun tí ó kí nínú ilé rẹ̀ àti ní ọjá rẹ̀ lọ, ní ìlọ́po ogún lé díẹ̀, èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé tí ẹni kẹ́ni nínú wọn bá ṣe àlùwàlá, tí ó sì ṣe àlúwàlá rẹ̀ dáadáa, lẹ́yìn náà tí ó wá sí Mọṣáláṣí, tí ohun kankan kò gbé e dìde bíkòṣe ìrun, tí kò gba nǹkankan lérò bíkòṣe ìrun, kò ní gbé ìgbésẹ̀ kan àyàfi kí wọ́n fi gbé ipò rẹ̀ ga, kí wọ́n sì fi pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kan rẹ́ títí tí yóò fi wọ Mọṣáláṣí. Nígbà tí ó bá wọ Mọṣáláṣí tán, yóò máa gba ẹ̀san ẹni tí ó wà lórí ìrun, ní òpin ìgbà tí ó bá ti jẹ́ wí pé ìrun ni ó ń dá a dúró. Àti wí pé àwọn Malā’ikah yóò máa tọrọ ìkẹ́ àti ìgẹ́ Ọlọ́hun fún ẹni kẹ́ni nínú yín, ní òpin ìgbà tí ó bá sì wà ní ibùjokòó rẹ̀ tí ó ti kírun. Wọn yóò máa wí pé: Ìrẹ Ọlọ́hun! Kẹ́ ẹ. Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣe àforíjìn fún un. Ìrẹ Ọlọ́hun! Gba ìrònúpìwàdà rẹ̀. Ní òpin ìgbà tí kò bá ti ṣe ẹnìkankan ní ṣùtá níbẹ̀, ní òpin ìgbà tí kò bá ti ṣe ẹ̀gbin níbẹ̀” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (649).
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ó sọ wí pé: “Nígbà tí ẹ bá gbọ́ gbígbé ìrun dìde, ẹ lọ kírun, kí ẹ sì dúnní mọ́ ṣíṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti ìwà-ìrẹ̀lẹ̀, ẹ má ṣe sáré, ohun tí ẹ bá bá, ẹ kí i, ohun tí ó bá sì bọ́ mọ́ yín lọ́wọ́, ẹ pé e” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (636), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (602).
An-Nawawī – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: ... ohun tí wọ́n gbà lérò pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ni: Fífi ara balẹ̀ níbi ìrìn àti jíjìnnà sí mímáaa ṣaré. Nígbà tí ìwà-ìrẹ̀lẹ̀: Wà níbi ìrísí, bíi rírẹ ojú nílẹ̀, rírẹ ohùn nílẹ̀ àti mímá máa wòhín-wọ̀hún”. Àlàyé Ṣaḥīḥu Muslim ti An-Nawawī, Ḥadīth (602), àkòrí ọ̀rọ̀ nípa jíjẹ́ ohun tí a fẹ́ mímáa lọ síbi ìrun pẹ̀lú ìwà-ìrẹ̀lẹ̀ àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti kíkọ̀ nípa wíwá kí i pẹ̀lú pípọ̀sẹ̀sẹ̀.
Nítorí Ḥadīth tí Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, dájúdájú ó sọ wí pé: “Nínú Sunnah, nígbà tí ó bá fẹ́ wọ Mọṣáláṣí ni kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá fẹ́ jáde, kí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì” Al-Ḥākim ni ó gbà á wá (1/338), ó sì kà á sí ẹ̀gbẹ̀wí tí ó ní àlááfíà ní ìbámu sí májẹ̀mu Muslim.
Nítorí Ḥadīth tí Abū Ḥumayd tàbí Abū Usayd gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá fẹ́ wọ Mọṣáláṣí, kí ó sọ wí pé: Allāhummaftaḥ lī abwāba raḥmatik (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣí àwọn ilẹ̀kùn àánú Rẹ fún mi), nígbà tí ó bá fẹ́ jáde, kí ó sọ wí pé: Allāhumma ’innī ’as’aluka min faḍlik (Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń tọrọ, ní ọ̀dọ̀ Rẹ, nínú Ọlá Rẹ). Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (713).
Èyí yóò wáyé, tí ó bá jẹ́ wí pé ó tètè wá kírun, dájúdájú wọ́n ṣe é ní Sunnah fún un kí ó má jókòó títí tí yóò fi kí òpó-ìrun méjì. Nítorí Ḥadīth tí Abū Qatādah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, dájúdájú ó sọ wí pé: Ḥumayd tàbí Abū Usayd gbà wá, ó sọ wí pé: Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá wọ Mọṣáláṣí, kò gbọdọ̀ jókòó títí tí yóò fi kí òpó-ìrun méjì”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1163), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (714).
Ìrun Sunnah tí a máa ń kí síwájú ìrun ọ̀ranyàn, tí to láti dípo ìrun tí a fi máa ń kí Mọṣáláṣí, tí ó bá jẹ́ ìrun ọ̀ranyàn tí ó ní ìrun Sunnah tí a máa ń kí síwájú rẹ̀, bíi ìrun àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́ àti ìrun ọ̀sán, tàbí ìrun Sunnah tí a máa ń kí ní àsìkò ìyálẹ̀ta, tí ó bá wọ Mọṣáláṣí ní àsìkò ìyálẹ̀ta, tàbí ìrun Witr, tí ó bá jẹ́ wí pé ó kí i ní Mọṣáláṣí, tàbí ìrun ọ̀ranyàn, nítorí pé ohun tí wọ́n gbà lérò pẹ̀lú kíkí Mọṣáláṣí ni: Kí ó má jókòó títí tí yóò fi kírun. Nítorí ohun tí ó wà nínú rẹ̀, nínú mímáa gbé àwọn Mọṣáláṣí ró pẹ̀lú ìrun kíkí, nítorí kí ó má ṣe máa wá síbẹ̀ láìkírun kankan.
Sunnah ni ó jẹ́ fún àwọn ọkùnrin kí wọ́n máa yára wá sí sááfú àkọ́kọ́, ohun ní ó lọ́lá jùlọ nínú àwọn sááfú, ṣùgbọ́n fún àwọn obìnrin, èyí tí ó lọ́lá jùlọ nínú rẹ̀ ni èyí tí ó bá gbẹ̀yìn nínú rẹ̀.
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Èyí tí ó lóore jùlọ nínú sááfú àwọn ọkùnrin ni àkọ́kọ́ rẹ̀, èyí tí ó burú jùlọ nínú rẹ̀ ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó lóore jùlọ nínú sááfú àwọn obìnrin ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀, èyí tí ó burú jùlọ nínú rẹ̀ ni àkọ́kọ́ rẹ̀” Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (440). Ìtumọ̀ pé òhun ni ó lóore jùlọ ni pé: Òhun ní ẹ̀san rere àti ọlá rẹ̀ pọ̀ jùlọ. Ìtumọ̀ pé òhun ni ó burú jùlọ ni pé: Òhun ní ẹ̀san rere àti ọlá rẹ̀ kéré jùlọ.
Ḥadīth yìí wà fún ìgbà tí àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin bá kírun papọ̀, tí kò sì sí gàgá kankan, bóyá ògiri ni tàbí ohun tí ó jọ ọ́, láàrin wọn. Nígbà náà èyí tí ó lóore jùlọ nínú sááfú àwọn obìnrin ni ìgbẹ̀yìn rẹ̀, nítorí pé dájúdájú ohun ní ó fi wọ́n pamọ́ jùlọ kúrò níbi kí àwọn ọkùnrin máa wò wọ́n. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé gàgá, bóyá ògiri ni tàbí ohun tí ó jọ ọ́, wà láàrin wọn, tàbí gẹ́gẹ́ bí ò ti wà níbi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Mọṣáláṣí wa, ní ayé òde-òní, pẹ̀lú pé wọ́n ṣẹ̀ṣà ààyè ìkírun tí ó dá wà fún àwọn obìnrin nìkan, nínú irú ìṣesí báyìí, èyí tí yóò lọ́lá jùlọ nínú sááfú àwọn obìnrin ni àkọ́kọ́ rẹ̀, nítorí pé ohun tí ó le fa kí wọ́n súnmọ́ àwọn ọkùnrin kò sí mọ́, nítorí pé ìdájọ́ máa ń rìn pẹ̀lú ìdí rẹ̀, bóyá ó ń bẹ ni tàbí kò sí. Àti nítorí ẹ̀rí gbogboogbò tí ó wá lórí lílọ́lá sááfú àkọ́kọ́ nínú àwọn Ḥadīth kan, nínú rẹ̀ ni:
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ó bá jẹ́ wí pé àwọn èèyàn mọ ohun tí ń bẹ níbi ìrun pípè àti sááfú àkọ́kọ́ (nínú ọlá) ni, lẹ́yìn náà tí wọn kò rí ọ̀nà débẹ̀ àyàfi pẹ̀lú kí wọ́n muje, dájúdájú wọn ì bá muje. Tí ó bá sì jẹ́ wí pé wọ́n mọ ohun tí ń bẹ nínú mímáa tètè yára lọ sí Mọṣáláṣí (nínú oore) ni, dájúdájú wọn kò bá gbìyànjú láti gbawájú mọ́ ara wọn lọ́wọ́ lọ síbẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ wí pé wọ́n mọ ohun tí ń bẹ nínú kíkí ìrun alẹ́ – ‘Ishā’ – àti ìrun àárọ̀ (nínú oore) ni, dájúdájú wọn kò bá wá kí méjèèjì, kódà kó jẹ́ wí pé wọ́n yóò rákòrò wá síbẹ̀ ni” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (615), Muslim sì gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (437).
Ohun tí ó lọ́lá jùlọ fún ẹni tí ń kírun lẹ́yìn Imām, nípa bí yóò ti to sááfú fún ìrun, ní sááfú àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́ bíi àlàyé tí ó ti síwájú, lẹ́yìn náà yóò ṣe ojú kòkòrò láti wà níbi tí yóò ti súnmọ́ Imām, ibi tí ó bá súnmọ́ Imām jùlọ nínú ẹ̀bá méjèèjì; ọ̀tún tàbí òsì, òhun ni ó lọ́lá jùlọ.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Àwọn onímímọ̀ àti làákàyè nínú yín ni kí wọ́n máa pọwọ́ lé mi” Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (874), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (228). Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀; “kí wọ́n máa pọwọ́ lé mi” ni: Kí wọ́n máa súnmọ́ mi. Ẹ̀rí wà nínú èyí pé sísúnmọ́ Imām jẹ́ ohun tí a fẹ́ níbi ẹ̀bá tí ó wulẹ̀ kí ó jẹ́.