brightness_1
Wíwí ohun tí apèrun ń wí tẹ̀lé e
Sunnah ni fún ẹni tí ó bá gbọ́ ìpè-ìrun kí ó máa sọ irú ohun tí apèrun ń sọ, àyàfi nígbà tí apèrun bá wí pé: Ḥayya ‘alaṣ-ṣalāh (ẹ yára wá kírun), tàbí ḥayya ‘alal-falāḥ (ẹ yára wá jèrè), yóò wí pé: “Lā ḥawla walā quwwata ’illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun)”.
Nítorí Hadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr, ọmọ́ Al-‘Āṣ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá pé: Dájúdájú òun gbọ́ tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Nígbà tí ẹ bá gbọ́ tí apèrun ń pèrun, ẹ máa sọ irú ohun tí ó ń sọ...” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (384). Àti Hadīth tí ‘Umar ọmọ Al-Khaṭṭāb – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: Nígbà tí apèrun bá sọ wí pé: Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), tí ẹni kẹ́ni nínú yín sì sọ wí pé: Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illallāh (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), tí òun náà sì sọ wí pé: ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illallāh (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: ’Ashhadu ’anna Muḥammadan Rasūlullāh (Mo jẹ́rìí pé Ànábì Muḥammad, níti pàápàá, jẹ́ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun), tí òun náà sì sọ wí pé: ’Ashhadu ’anna Muḥammadan Rasūlullāh (Mo jẹ́rìí pé Ànábì Muḥammad, níti pàápàá, jẹ́ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Ḥayya ‘alaṣ-ṣalāh (Ẹ yára wá kírun), tí òun náà sì sọ wí pé: Lā ḥawla walā quwwata ’illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Ḥayya ‘alal-falāḥ (ẹ yára wá jèrè), tí òun náà sì sọ wí pé: Lā ḥawla walā quwwata ’illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), tí òun náà sì sọ wí pé: Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Lā ’ilāha ’illallāh, (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), tí òun náà sì sọ wí pé: Lā ’ilāha ’illallāh, (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), tí ó jẹ́ wí pé ó ti ọkàn rẹ̀ wá, dájúdájú yóò wọ ọgbà-ìdẹ̀ra Al-Jannah” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (385).
Nígbà tí apèrun bá ń pe àwọn èèyàn síbi ìrun àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́ (pẹ̀lú gbólóhùn: Aṣ-ṣalātu khayrun min-nawm), dájúdájú òun náà yóò sọ irú ohun tí apèrun ń sọ: “Aṣ-ṣalātu khayrun min-nawm (ìrun kíkí lóore ju oorun lọ)”.