Sunnah ni fún ẹni tí ó bá gbọ́ ìpè-ìrun kí ó máa sọ irú ohun tí apèrun ń sọ, àyàfi nígbà tí apèrun bá wí pé: Ḥayya ‘alaṣ-ṣalāh (ẹ yára wá kírun), tàbí ḥayya ‘alal-falāḥ (ẹ yára wá jèrè), yóò wí pé: “Lā ḥawla walā quwwata ’illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun)”.
Nítorí Hadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr, ọmọ́ Al-‘Āṣ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá pé: Dájúdájú òun gbọ́ tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Nígbà tí ẹ bá gbọ́ tí apèrun ń pèrun, ẹ máa sọ irú ohun tí ó ń sọ...” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (384). Àti Hadīth tí ‘Umar ọmọ Al-Khaṭṭāb – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: Nígbà tí apèrun bá sọ wí pé:Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar(Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), tí ẹni kẹ́ni nínú yín sì sọ wí pé: Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illallāh (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), tí òun náà sì sọ wí pé: ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illallāh(Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: ’Ashhadu ’anna Muḥammadan Rasūlullāh (Mo jẹ́rìí pé Ànábì Muḥammad, níti pàápàá, jẹ́ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun), tí òun náà sì sọ wí pé:’Ashhadu ’anna Muḥammadan Rasūlullāh (Mo jẹ́rìí pé Ànábì Muḥammad, níti pàápàá, jẹ́ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Ḥayya ‘alaṣ-ṣalāh (Ẹ yára wá kírun), tí òun náà sì sọ wí pé: Lā ḥawla walā quwwata ’illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Ḥayya ‘alal-falāḥ (ẹ yára wá jèrè), tí òun náà sì sọ wí pé: Lā ḥawla walā quwwata ’illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar(Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), tí òun náà sì sọ wí pé:Allāhu ’Akbar, Allāhu ’Akbar(Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ, Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ), lẹ́yìn náà tí ó bá sọ wí pé: Lā ’ilāha ’illallāh, (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), tí òun náà sì sọ wí pé: Lā ’ilāha ’illallāh, (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh), tí ó jẹ́ wí pé ó ti ọkàn rẹ̀ wá, dájúdájú yóò wọ ọgbà-ìdẹ̀ra Al-Jannah” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (385).
Nígbà tí apèrun bá ń pe àwọn èèyàn síbi ìrun àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́ (pẹ̀lú gbólóhùn: Aṣ-ṣalātu khayrun min-nawm), dájúdájú òun náà yóò sọ irú ohun tí apèrun ń sọ: “Aṣ-ṣalātu khayrun min-nawm (ìrun kíkí lóore ju oorun lọ)”.
Sísọ Ìrántí Ọlọ́hun tí ń bọ̀ yìí, lẹ́yìn ìjẹrìí méjèèjì
Ó jẹ́ Sunnah kí á sọ, lẹ́yìn ìgbà tí apèrun bá ti sọ: “’Ashhadu ’anna Muḥammadan Rasūlullāh” kejì; ohun tí ó wá nínú Ḥadīth tí Sa‘d – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá láti ọ̀dọ̀ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pé ó sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ, nígbà tí ó bá gbọ́ apèrun, pé: ’Ashhadu ’an lā ilāha illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, wa’anna Muḥammadan ‘abduhu warasūluh, raḍītu billāhi Rabban wabiMuḥammadin rasūlan wabil-’Islāmi dīnā(Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Mo sì jẹ́rìí pé Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun Muḥammad, níti pàápàá, jẹ́ ẹrúsìn Rẹ̀ àti Ìránṣẹ́ Rẹ̀. Mo yọ́nú sí Ọlọ́hun Allāh ní Ọlọ́hun Ọba, àti sí Muḥammad ní Ìránṣẹ́, àti sí ẹ̀sìn Islām ní ẹ̀sìn), wọn yóò fi orí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jìn ín” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (386).
Ṣíṣe àsàlátù fún Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – lẹ́yìn ìrun pípè
Nítorí Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá, ó sọ wí pé:Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Nígbà tí ẹ bá gbọ́ apèrun tí ó ń pèrun, ẹ máa sọ irú ohun tí ó ń sọ, lẹ́yìn náà ẹ ṣe àsàlátù fún mi, nítorí pé dájúdájú ẹni kẹ́ni tí ó bá ṣe àsàlátù kan ṣoṣo fún mi, Ọlọ́hun yóò tóri rẹ̀ ṣe àsàlátù mẹ́wàá padà fún un. Lẹ́yìn náà ẹ tọrọ ipò Al-Wasīlah fún mi, nítorí pé ó jẹ́ ipò kan nínú ọgbà-ìdẹ̀ra Àlùjáńnà, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ àyàfi fún ẹníkan ṣoṣo nínú àwọn ẹrúsìn Ọlọ́hun, mo sì ǹ rankàn kí ó jẹ́ wí pé èmi ni ẹni náà. Nítorí náà ẹni kẹ́ni tí ó bá tọrọ ipò Al-Wasīlah fún mi, ìṣìpẹ̀ mi ti di ẹ̀tọ́ fún un” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (384).
Èyí tí ó lọ́lá jùlọ nínú àwọn ìran àsàlátù niAṣ-ṣalātul-Ibrāhīmiyyah: “Allāhumma ṣalli ‘alā Muḥammad, wa‘alā ’āli Muḥammad, kamā ṣallayta ‘alā Ibrāhīm... (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣe ìkẹ̀ fún Ànábì Muḥammad àti fún àwọn ará ilé Ànábì Muḥammad, gẹ́gẹ́ bí O ti ṣe ìkẹ̀ fún Ànábì Ibrāhīm..)”.
Sísọ àdúà tí ó wá lẹ́yìn pípe ìrun
Nítorí Ḥadīth tí Jābir – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ, nígbà tí ó ń gbọ́ ìpè ìrun, pé: “Allāhumma Rabba hādhihid-da‘watit-tāmmah, waṣ-ṣalātil-qā’imah ’āti Muḥammadan al-wasīlata wal-faḍīlah, wab‘athhu maqāman maḥmūdanil-ladhī wa‘attah (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ọlọ́hun Ọba tí Ó ni ìpèpè tí ó pé yìí, àti ìrun tí a gbé nàró. Fún (Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun) Muḥammad ní Al-Wasīlah (ààyè gíga kan nínú ọgbà-ìdẹ̀ra) àti àgbéga (lórí gbogbo ẹ̀dá), sì gbé e dìde ní ààyè ẹyìn eléyìí tí O bá a ṣe àdéhùn), ìṣìpẹ̀ mi ti di ẹ̀tọ́ fún un ní ọjọ́ Ìgbéǹde” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (614).
Ṣíṣe àdúà lẹ́yìn pípe ìrun
Nítorí Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá pé: “Dájúdájú ọkùnrin kan sọ wí pé: Ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, dájúdájú àwọn apèrun ti gba ọlá mọ́ wa lọ́wọ́, ni Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – bá sọ wí pé: “Máa sọ bí wọ́n ti ń sọ, tí ó bá wá parí, tọrọ (ohun tí ó fẹ́), wọn yóò fún ọ ní nǹkan náà” Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (524), Ibn Ḥajar – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó dára (Natā’ijul-’Afkār 1/366) àti Al-Albānī (Ṣaḥīḥul-kalimiṭ-ṭayyib, ojú-ewé: 73).
Nítorí Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, gbà wá pé: Dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Wọ́n kì í dá àdúà tí a bá ṣe láàrin pípe ìrun àti gbígbé ìrun nàró padà” An-Nasā’ī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (9895), Ibn Khuzaymah sì kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfìà (1/221/425).
Kàn sí wa
Sí wa
Yóò dùn mọ́wa kí á rí àwọn ìpè rẹ àti àwọn ìbéèrè rẹ ní ìgbà kíìbà