languageIcon
search
search
beforeFajronColorIcon Àwọn Sunnah tó ní àsìkò/ Àsìkò ìrun ọ̀sán / ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 3 Àwọn Sunnah )
brightness_1 Nígbà tí ooru bá le koko, wọ́n ṣe é ní Sunnah fún wa láti lọ́ ìrun ọ̀sán lára títí tí yóò fi rọlẹ̀

Ẹ̀rí rẹ̀ ni :

Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, tí ó ṣe àfitì rẹ̀ sí Ànábì: “Nígbà tí ooru bá le koko látara gbígbóná janjan, ẹ ṣẹ̀ ẹ́ rọ̀ pẹ̀lú pé kí ẹ lọ́ ìrun (ọ̀sán) lára, nítorí pé dájúdújú lílekoko ooru, ara fífọ́nká jíjò yì ìná Jahannam ni”. Jíjò yì ìná Jahannam ni: Ríru rẹ̀, fífọ́nká jíjò yìyìyì rẹ̀, àti kíkò ó. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (533,534), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (615).

Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn  ­– kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ní àpèjúwe, tí a bá wò ó pé òòrùn, ní àsìkò ooru, ń yẹ àtàrí ní agogo méjìlá, àti pé àsìkò ìrun ìrọ̀lẹ́, ní àfojúdá, ń tó ní agogo mẹ́rin-ààbọ̀, a jẹ́ wí pé a ó lọ ìrun ọ̀sàn lára, ní àfojúdá, di agogo mẹ́rin. Wo: Al-Mumti‘ (2/104).

Lílọ́ ìrun ọ̀sán lára yìí kárí gbobo ẹni tó bá ń kírun pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn Mùsùlùmí, àti ẹni tó ń dá ìrun kí lóun nìkan, ní ìbámu sí ohun tó ni àlááfíà nínú ọ̀rọ̀ àwọ̀n onímímọ̀. Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn  ­– kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – ṣa èyí lẹ́ṣà. Fún ìdí èyí, àwọn obìnrin bákan náà wọnú rẹ̀. Wọ́n ṣe lílọ́ ìrun ọ̀sán lára nígbà tí ooru bá le koko ní Sunnah fún àwọn náà. Nítorí ìtọ́ka gbogboogbò tó wà níbi Ḥadīth tí Abū Hurayrah–kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá.