Ìrun Sunnah tí a máa ń kí síwájú àti lẹ́yìn ìrun ọ̀ranyàn
Ó ti síwájú, nígbà tí à ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrun àkígbọrẹ tí a máa ń kí síwájú àti lẹ́yìn ìrun ọ̀ranyàn, pé wọ́n ṣe é lófin fún wa, síwájú ìrun ọ̀sán, kí á kí òpó-ìrun mẹ́rin, àti pé dájúdájú wọ́n ṣe é lófin fún wa kí á kí òpó-ìrun méjì lẹ́yìn rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ḥadīth tí ‘Ā’ishah, ’Umm Ḥabībah àti Ibn ‘Umar – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí wọn – lápapọ̀ gbà wá ti tọ́ka sí èyí.
Nínú Sunnah ni kí á fa òpó-ìrun àkọ́kọ́, níbi ìrun ọ̀sán, gún
Nítorí Ḥadīth tí Abū Sa‘īd Al-Khudrī – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ pé: “Wọ́n máa ń gbé ìrun ọ̀sán nàró, èèyàn yóò sì lọ sí Baqī‘, yóò sì gbọ́ bùkáátà rẹ̀ tó fẹ́ gbọ́ (yóò ṣe ìgbọ̀nsẹ̀), lẹ́yìn náà yóò ṣe àlùwàlá, lẹ́yìn náà yóò padà wá, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – yóò sì wà lórí òpó-ìrun àkọ́kọ́, látara bí ó ti máa fà á gùn tó”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (454).
Fún ìdí èyí, Sunnah ni fún Imām kí ó fa òpó-ìrun àkọ́kọ́, níbi ìrun ọ̀sán, gún. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tó ń dá ìrun kí. Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin, nígbà tí ó bá ń kírun ọ̀sán. Èyí jẹ́ ara àwọn Sunnah tó ti ń parun. À ń bẹ Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga, kí Ó jẹ́ kí á le máa lo Sunnah ní ọ̀nà tó pé jùlọ, kí á sì le máa ṣe ojú kòkòrò lórí rẹ̀.
Nígbà tí ooru bá le koko, wọ́n ṣe é ní Sunnah fún wa láti lọ́ ìrun ọ̀sán lára títí tí yóò fi rọlẹ̀
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, tí ó ṣe àfitì rẹ̀ sí Ànábì: “Nígbà tí ooru bá le koko látara gbígbóná janjan, ẹ ṣẹ̀ ẹ́ rọ̀ pẹ̀lú pé kí ẹ lọ́ ìrun (ọ̀sán) lára, nítorí pé dájúdújú lílekoko ooru, ara fífọ́nká jíjò yì ìná Jahannam ni”. Jíjò yì ìná Jahannam ni: Ríru rẹ̀, fífọ́nká jíjò yìyìyì rẹ̀, àti kíkò ó. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (533,534), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (615).
Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ní àpèjúwe, tí a bá wò ó pé òòrùn, ní àsìkò ooru, ń yẹ àtàrí ní agogo méjìlá, àti pé àsìkò ìrun ìrọ̀lẹ́, ní àfojúdá, ń tó ní agogo mẹ́rin-ààbọ̀, a jẹ́ wí pé a ó lọ ìrun ọ̀sàn lára, ní àfojúdá, di agogo mẹ́rin. Wo: Al-Mumti‘ (2/104).
Lílọ́ ìrun ọ̀sán lára yìí kárí gbobo ẹni tó bá ń kírun pẹ̀lú àkójọpọ̀ àwọn Mùsùlùmí, àti ẹni tó ń dá ìrun kí lóun nìkan, ní ìbámu sí ohun tó ni àlááfíà nínú ọ̀rọ̀ àwọ̀n onímímọ̀. Àlùfáà wa àgbà, ọmọ ‘Uthaymīn – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – ṣa èyí lẹ́ṣà. Fún ìdí èyí, àwọn obìnrin bákan náà wọnú rẹ̀. Wọ́n ṣe lílọ́ ìrun ọ̀sán lára nígbà tí ooru bá le koko ní Sunnah fún àwọn náà. Nítorí ìtọ́ka gbogboogbò tó wà níbi Ḥadīth tí Abū Hurayrah–kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá.
Kàn sí wa
Sí wa
Yóò dùn mọ́wa kí á rí àwọn ìpè rẹ àti àwọn ìbéèrè rẹ ní ìgbà kíìbà