Èyí jẹ́ ìjọ kan tó ní àkàkún titan ìlànà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – àti Sunnah rẹ̀ ká. Nígbà tó jẹ́ wí pé bùkáátà àwọn Mùsùlùmí, ní gbogbo àgbáyé ìlú Mùsùlùmí, ń gbópọn sí i lóríi rírí iṣẹ́ kan tí yóò máa ṣàlàyé àwọn ìlànà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – àti àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí ó máa ń ṣe ní ojoojúmọ́, pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó ní àlááfíà, àti àwọn àwòrán tí yóò máa ṣe àlàyé rẹ̀, iṣẹ́ àkànṣe “Sunan” wáyé, nítoríi kí ó le fi ṣíṣe àlàyé àwọn ìlànà Ànábì Muḥammad – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – rinlẹ̀ ní ọ̀nà tó rọrùn, tí yóò sì máa ran Mùsùlùmí lọ́wọ́ láti máa ṣe ìjọsìn rẹ̀ ojoojúmọ́ ní ọ̀nà tó ní àlááfíà. Àti nítorí kí ó le ṣọ́ra fún àwọn àdádáálẹ̀ tó ti fọ́nká láàrin àwọn Mùsùlùmí láyé òde-òní. Ohun-èlò yìí tún wáyé láti ṣe iṣẹ́ sin àwọn Mùsùlùmí, ní gbogbo àgbáyé ìlú Mùsùlùmí, pẹ̀lú oríṣríṣi èdè. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé ìjọ (Iqtidā’) ti ṣe tán láti gba èyíkéyìí àkíyèsí tàbí ìgbani níyànjú tàbí ìmọ̀ràn láti ṣe àtúnṣe àti láti mú ìtẹ̀síwájú bá iṣẹ́ yìí, láti ipasẹ̀ àmì ìkàn sí ara ẹni tí a ti pèsè kalẹ̀