languageIcon
search
search
Àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe ní ojoojúmọ́ àti alaalẹ́ Àwọn ìrántí Ọlọ́hun tí a máa ń ṣe ní ojoojúmọ́ àti alaalẹ́ ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 4 Àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ )

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

أَمْسَيْنَا وَأَمْسَى الْمُلْكُ لِلَّهِ، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ لاَ إِلَهَ إِلاَّ اللَّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ مِنْ خَيْرِ هَذِهِ اللَّيْلَةِ وَخَيْرِ مَا فِيهَا، وَأَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّهَا وَشَرِّ مَا فِيهَا، اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنَ الْكَسَلِ، وَالْهَرَمِ، وَسُوءِ الْكِبَرِ، وَفِتْنَةِ الدُّنْيَا، وَعَذَابِ الْقَبْرِ

’Amsaynā wa’amsal-Mulku lillāh,  wal-ḥamdu lillāh lā ’ilāha ’illallāh, waḥdahu lā sharīka lah, Allāhumma ’innī ’as’aluka min khayri hādhihil-laylah, wakhayri mā fīhā, wa’a‘ūdhu bika min sharrihā, washarri mā fīhā, Allāhumma ’innī ’a‘ūdhu bika minal-kasal, wal-haram, wasū’il-kibar, wafitnatid-dunyā, wa‘adhābil-qabr (A ti di ìrọ̀lẹ́, gbogbo ìjọba sì tún jẹ́ ti Ọlọ́hun. Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun nìkan ni í ṣe. Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ìrẹ Ọlọ́hun! Mo ń tọrọ nínú oore òru yìí lọ́dọ̀ Rẹ àti oore ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, mo sì ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú òru yìí àti aburú ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ Ìrẹ Ọlọ́hun! Mo ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi òròjú, ogbó, aburú dídi arúgbó, wàhálà ilé-ayé àti ìyà inú sàréè)” Nígbà tí ó bá jí ní àárọ̀, yóò tún sọ èyí bákan náà pé: ’Aṣbaḥnā wa’aṣbaḥal-mulku lillāh (A ti jí sáyé, gbogbo ìjọba sì tún jẹ́ ti Ọlọ́hun...) ’as’aluka khayra mā fī hādhal-yawm, wakhayra mā ba‘dah, wa’a‘ūdhu bika min sharri mā fī hādhal-yawm, washarri mā ba’dah... (Mo ń tọrọ oore ọjọ́ òni yìí lọ́dọ̀ Rẹ àti oore ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn rẹ̀, mo sì ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú òni yìí àti aburú ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn rẹ̀...). Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2723).

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

اللَّهُمَّ أَنْتَ رَبِّي لَا إِلَهَ إِلَّا أَنْتَ خَلَقْتَنِي، وَأَنَا عَبْدُكَ، وَأَنَا عَلَى عَهْدِكَ وَوَعْدِكَ مَا اسْتَطَعْتُ، أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ مَا صَنَعْتُ، أَبُوءُ لَكَ بِنِعْمَتِكَ عَلَيَّ، وَأَبُوءُ لَكَ بِذَنْبِي فَاغْفِرْ لِي فَإِنَّهُ لَا يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلَّا أَنْتَ

Ọ̀gá àdúà tí a fi máa ń wá àforíjìn: “Allāhumma ’Anta Rabbī lā ’ilāha ’illā ’Ant, khalaqtanī wa’ana ‘abduk, wa’ana ‘alā ‘ahdika wawa‘dika mastaṭa‘t, ’a‘ūdhu bika min sharri mā ṣana‘t, ’abū’u laka bini‘matika ‘alayy, wa’abū’u bidhanbī, faghfir lī fa’innahu lā yaghfirudh-dhunūba ’illā ’Ant (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Ọlọ́hun Ọba mi, kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ nìkan. O dá mi, àti pé èmi jẹ́ ẹrúsìn fún Ọ. Èmi sì ń bẹ lórí ìpínhùn Rẹ àti àdéhùn Rẹ bí mo ti lágbára mọ. Mo wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú ohun tí mo ṣe. Mo gbà fún Ọ pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ tí O se fún mi, mo sì mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ṣe àforíjìn fún mi. Dájúdájú kò sí ẹni tó le ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àyàfi Ìwọ nìkan” Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: Ẹni kẹ́ni tó bá sọ ọ́, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo sí i, ní ọ̀sán, tí ó wá kú ní ọjọ́ náà, síwájú kí ó tó di ìrọ̀lẹ́, ó ti wà nínú àwọn ara ọgbà-ìdẹ̀ra Àlùjánńnà. Ẹni kẹ́ni tó bá sọ ọ́, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ òdodo sí i, ní òru, tí ó wá kú síwájú kí ó tó jí dìde ní àárọ̀, ó ti wà nínú àwọn ara ọgbà-ìdẹ̀ra Àlùjánńnà”  Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6306).

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

اللَّهُمَّ فَاطِرَ السَّمَوَاتِ وَالْأَرْضِ، عَالِمَ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ، لَا إِلَهَ إِلَّا أَنْتَ رَبَّ كُلِّ شَيْءٍ وَمَلِيكَهُ، أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ نَفْسِي وَمِنْ شَرِّ الشَّيْطَانِ وَشِرْكِهِ، وَأَنْ أَقْتَرِفَ عَلَى نَفْسِي سُوءًا، أَوْ أَجُرَّهُ إِلَى مُسْلِمٍ

Allāhumma Fāṭiras-samāwāti wal-’arḍ, ‘Ālimal-ghaybi wash-shahādah, lā ’ilāha ’illā ’Ant, Rabba kulli shay’in waMalīkah, ’a‘ūdhu bika min sharri nafsī wamin sharrish-shaytāni washirkih, wa’an ’aqtarifa ‘alā nafsī sū’an ’aw ajurrahu ’ilā muslim (Ìrẹ Ọlọ́hun! Aṣẹ̀dá àwọn sánmà àti ilẹ̀ láìní àfijọ, Olùmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gbangba, kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ nìkan, Ọlọ́hun Ọba gbogbo nǹkan àti Olúwa Rẹ̀. Mo wá ìṣọ́ra pẹ̀lú Rẹ kúrò níbi aburú ẹ̀mí mi, àti kúrò níbi aburú èṣù àti ẹbọ tó ń pèpè sí (tàbí àti àwọn ète rẹ̀), àti kúrò níbi kí n ṣe aburú fún ẹ̀mí ara mi tàbí kí n ṣe é sí Mùsùlùmí kankan”. Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Sọ ọ́ nígbà tí ó bá jí ní àárọ̀, àti nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ̀ àti nígbà tí ó bá fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ lórí ìbùsùn rẹAl-Imām Aḥmad gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6597), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5076), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3529), An-Nasā’ī  gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (7699), Ibn Bāz – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ́ – kà ojúpọ̀nà rẹ̀ sí èyí tí ó ní àlááfíà.

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ الْعَافِيَةَ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ، اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ الْعَفْوَ وَالْعَافِيَةَ فِي دِينِي وَدُنْيَايَ، وَأَهْلِي وَمَالِي، اللَّهُمَّ اسْتُرْ عَوْرَاتِي، وَآمِنْ رَوْعَاتِي، اللَّهُمَّ احْفَظْنِي مِنْ بَيْنِ يَدَيَّ وَمِنْ خَلْفِي، وَعَنْ يَمِينِي وَعَنْ شِمَالِي، وَمِنْ فَوْقِي، وَأَعُوذُ بِعَظَمَتِكَ أَنْ أُغْتَالَ مِنْ تَحْتِي

Allāhumma ’innī ’as’alukal-‘afwa wal-‘āfiyah, fid-dunyā wal-’ākhirah, Allāhumma ’innī ’as’alukal-‘afwa wal-‘āfiyah fī dīnī, wadunyāya wa-’ahlī, wamālī, Allāhummas-tur ‘awrātī, wa’āmin raw‘ātī, Allāhummaḥfaẓnī min bayni yadayy, wamin khalfī, wa‘an yamīnī, wa‘an shimālī, wamin fawqī, wa’a‘ūdhu bi‘aẓamatika ’an ’ughtāla min taḥtī (Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń tọrọ àmójúkúrò lọ́dọ̀ Rẹ, àti àlááfíà ní ayé àti ní Ọ̀run. Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń tọrọ àmójúkúrò lọ́dọ̀ Rẹ; àti àlááfíà nínú ẹ̀sìn mi, ìṣẹ̀mí ayé mi, lára àwọn ẹbí mi, àti nínú dúkìá mi. Ìrẹ Ọlọ́hun! Pa ìhòhò mi mọ́, sì fi mí lọ́kàn balẹ̀ níbi àwọn ìpayà mi. Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣọ́ mi láti iwájú mi, láti ẹ̀yìn mi, láti ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi, láti ẹ̀gbẹ́ òsì mi, àti láti òké mi.  Mo sì wá ìṣọ́ra pẹ̀lú Rẹ́ kúrò níbi kí wọ́n tàn mí gbé pa láti abẹ́ mi)”. Al-Imām Aḥmad gbà á wá, nínú Musnad, pẹ̀lú òǹkà (4785), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5074), An-Nasā’īAl-Kubrā – gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (10401), Ibn Mājah gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3871), Al-Ḥākim kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà.

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà