Wọ́n ṣe é ní Sunnah fún ẹni tó bá fẹ́ wọ ààyè ẹ̀gbin, kí ó sọ ohun tó wá nínú Ṣaḥīḥu méjèèjì:
’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà á wá pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – nígbà tó bá fẹ́ wọ ààyè ẹ̀gbin máa ń sọ pé: “Allāhumma ’innī ’a‘ūdhu bika minal-khubuthi wal-khabā’ith (Ìrẹ Ọlọ́hun! Dájúdájú èmi ń wá ìṣọ́ pẹ̀lú Rẹ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin èṣù)”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6322), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (375).
(Al-Khubuth) pẹ̀lú fífún háràfí Bā ni ẹ̀wọ́ ḍammah ni: Àwọn ọkùnrin èṣù, nígbà tí al-khabā’ith sì jẹ́ àwọn obìnrin wọn. A jẹ́ wí pé èyí yóò jẹ́ wíwá ìṣọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin àwọn èṣù àti àwọn obìnrin wọn .
(Al-Khubth) pẹ̀lú fífún háràfí Bā ni ẹ̀wọ́ sukūn ni: Aburú, nígbà tí al-khabā’ith sì jẹ́ àwọn ẹ̀mí burúkú. A jẹ́ wí pé èyí yóò jẹ́ wíwá ìṣọ́ kúrò níbi aburú àti àwọn tó máa ń ṣe é. Fífún un ní sukūn ni ó kún jùlọ.
– Wọ́n ṣe é ní Sunnah fún ẹni tó fẹ́ jáde kúrò ní ààyè ẹ̀gbin kí ó sọ:
Ohun tó wá nínú Musnad Aḥmad, Sunan Abī Dāwūd àti ti At-Tirmidhī, tí Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà: Láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, ó sọ wí pé: “Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – nígbà tó bá fẹ́ jáde kúrò ní ààyè ẹ̀gbin máa ń sọ pé: “ “Ghufrānak (Mò ń tọrọ àforíjìn Rẹ̀)”. Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (25220), Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (30), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (7), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Taḥqīqu Mishkātil-Maṣābīḥ 1/116).
Kíkọ àsọtẹ́lẹ̀ sílẹ̀, Sunnah ni fún gbogbo Mùsùlùmí, nígbà tó bá ń ṣe àìsàn, tàbí ó wà ní àlááfíà, nítorí ọ̀rọ̀ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a sọ pé: “Kò ní ẹ̀tọ́ fún èèyàn tó jẹ́ Mùsùlùmí, tó ní nǹkankan tí ó yẹ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, kí ó sùn fún òru ọjọ́ méjì àyàfi kí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2783), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1626). Nínú Ḥadīth tí Ibn ‘Umar – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá. Sísọ òru ọjọ́ méjì nínú Ḥadīth yìí, kì í ṣe láti fi ààlà sí i. Ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n gbà lérò ni kí àsìkò kékeré kankan má rékọjá pẹ̀lú rẹ̀, àyàfi kí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wà ní kíkọ́ sílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí pé kò mọ ìgbàwo ni yóò kú, èyí jẹ́ Sunnah tó kárí gbogbo èèyàn.
Ṣùgbọ́n kíkọ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó wà lọ́rùn rẹ̀ nínú àwọn iwọ̀ Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga –, bí Zakāh yíyọ, Ḥajj ṣíṣe, sísan ìtanràn, tàbí àwọn iwọ̀ àwọn èèyàn bíi gbèsè àti dída àwọn nǹkan gbà-fi-pamọ́ padà, ọ̀ranyàn ni èyí, kì í ṣe Sunnah, nítorí pé sísan àwọn iwọ̀ tó jẹ́ ọ̀ranyàn so mọ́ ọn, pàápàá jùlọ tí ẹni kankan (lẹ́yìn rẹ̀) kò bá mọ̀ nípa àwọn iwọ̀ yìí [ohun tí ohun tó jẹ́ ọ̀ranyàn kò le pé àyàfi pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀ranyàn ni òun náà] .
Èyí yóò wáyé pẹ̀lú kí kálukú nínú ẹni tó ń tajà àti ẹni tó fẹ́ rà á, ṣọ̀ṣọ́ pẹ̀lú ìwà àmójúkúrò àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣòwò. Kí ẹnì kankan nínú àwọn méjèèjì má le mọ́ ẹnì kejì níbi dídúnàá dúràá nípa iye ọjá àti jíjìyàn nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n kí wọ́n jọjọ ṣe àmójúkúrò fún ara wọn.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Jābir ọmọ ‘Abdil-Lāh – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá pé: Dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Kí Ọlọ́hun kẹ́ ọkùnrin kan, tí ó máa ń ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ nígbà tí ó bá ń tajà, àti nígbà tí ó bá ń rajà, àti nígbà tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹlòmíràn”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2076).
Bẹ́ẹ̀ náà ni, nígbà tó bá fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹlòmíràn, Sunnah ni kí ó béèrè fún un pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí ọ̀rọ̀ tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ pé: “Àti nígbà tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹlòmíràn”.
Èyí jẹ́ ara àwọn Sunnah tí á máa ń ṣe ní ojoojúmọ́, èyí tí ọlá tó tóbi yóò wáyé lórí rẹ̀, èyí ni: Wíwọ ọgbà-ìdẹra Al-Jannah. Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà á wá pé: “Dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ fún Bilāl, lẹ́yìn ìrun àárọ̀ pé: “Ìrẹ́ Bilāl, sọ fún mi nípa iṣẹ́ rere kan, èyí tí ó ṣe nínú ẹ̀sìn Islām, tí ó ń rankàn ẹ̀san rere lórí rẹ̀ jùlọ, nítorí pé dájúdájú mo gbọ́ ríró bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì níwájú mi nínú ọgbà-ìdẹra Al-Jannah”. Ó dáhùn pé: Mi ò ṣe iṣẹ́ kankan tí mò ń rankàn ẹ̀san rere lórí rẹ̀ jùlọ, ju wí pé dájúdájú mi ò ní ṣe ìmọ́ra ní àsìkò kankan, ní òru ni tàbí ọ̀sán àyàfi kí ń fi ìmọ́ra náà kí ohun tí Ọlọ́hun bá kọ fún mi láti rí kí nínú ìrun”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1149), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2458). (Ríró bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì) túmọ̀ sí: Gbígbọ̀n bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.
Mímáa retí ìrun jẹ́ ara Sunnah tí ọlá tó tóbi wà lórí rẹ̀ .
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni nínú yín kò ní yé máa bẹ lórí ìrun, ní òpin ìgbà tó bá jẹ́ wí pé ìrun ni ó ń dá a dúró, tí kò sí ohun tó kọ̀ fún un láti padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀ bíkòṣe ìrun”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (659), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (649). Pẹ̀lú mímáa retí ìrun, yóò máa gba ẹ̀san ìrun kíkí.
Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà á wá pé: Dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Àwọn Malā’ikah yóò máa ṣe àdúà fún ẹni kẹ́ni nínú yín, ní òpin ìgbà tó bá sì wà níbi tó ti kírun, tí kò bá ti ṣe ẹ̀gbin níbẹ̀. Ìrẹ Ọlọ́hun! Ṣe àforíjìn fún un. Ìrẹ Ọlọ́hun! Kẹ́ ẹ́. Àti pé ẹni kẹ́ni nínú yín kò ní yé máa bẹ lórí ìrun, ní òpin ìgbà tó bá jẹ́ wí pé ìrun ni ó ń dá a dúró, tí kò sí ohun tó kọ̀ fún un láti padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀ bíkòṣe ìrun”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (659), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (649). Ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Tí kò bá ti ṣe ẹ̀gbin níbẹ̀” túmọ̀ sí: Ní òpin ìgbà tí kò bá ti ṣe ohun tí yóò ba àlùwàlá rẹ̀ jẹ́. Ó tún wá ní ọ̀dọ̀ Muslim pé:
“Ní òpin ìgbà tí kò bá ti ṣe ẹnì kankan ní ṣùtá níbẹ̀, tí kò sì ṣe ẹ̀gbin níbẹ̀”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (649). Ìtumọ̀ èyí ni pé: Májẹ̀mu ẹ̀san dáadáa yìí ni kí ó má fi ṣùtá kan ẹnì kankan níbi tó jókòó sí, kí àlùwàlá rẹ̀ sì má jà á.
Pákò rírìn jẹ́ ara àwọn Sunnah tí wọ́n tú sílẹ̀, èyí tí a máa ń ṣe ní gbogbo àsìkò. Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – máa ń gba àwọn èèyàn níyànjú rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, títí tí ó fi sọ pé: “Mo ti tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ rírin pákò lọ́pọ̀lọpọ̀ fun yín”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (888), nínú Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá. Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – tún sọ wí pé: “Pákò rírìn jẹ́ ohun tó máa ń fọ ẹnu mọ́, ó sì jẹ́ ohun tí Ọlọ́hun yọ́nú sí”. Aḥmad gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (7), An-Nasā’ī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5), nínú Ḥadīth tí ‘Ā’ishah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Al-’Irawā’ 1/105).
Jíjẹ́ Sunnah mímáa rin pákò ní àwọn ààyè kan, a ti sọ apákan nínú rẹ̀ tẹ̀lẹ́, pàápàá èyí tó máa ń pààrà ní ọ̀sán àti òru, bíi dídìde kírun lóru, nígbà tí a bá fẹ́ ṣe àlùwàlá, nígbà tí a bá fẹ́ kí gbogbo ìrun, àti nígbà tí a bá fẹ́ wọlé – Ọlọ́hun ni Ó mọ̀ jùlọ –.
Sunnah ni fún Mùsùlùmí kí ó máa tún àlùwàlá ṣe fún gbogbo ìrun. Ní àpèjúwe, tí ó bá jẹ́ wí pé ó ṣe àlùwàlá fún ìrun àṣálẹ́, lẹ́yìn náà tí ó sì kí ìrun àṣálẹ́, tí ìrun alẹ́ bá dé, wọ́n ṣe é ní Sunnah fún un kí ó ṣe àlùwàlá, kódà kí ó sì wà lórí ìmọ́ra. Sunnah ni kí ó máa ṣe àlùwàlá titun fún gbogbo ìrun kọ̀ọ̀kan.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tó wà lọ́dọ́ Al-Bukhārī, ó sọ wí pé: “Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – máa ń ṣe àlùwàlá níbi gbogbo ìrun”. Al-Bukhārī gbà á wà pẹ̀lú òǹkà (214).
Bákan náà nínú Sunnah ni kí èèyàn máa wà lórí ìmọ́ra ní gbogbo àsìkò ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí Ḥadīth tí Thawbān – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹnì kankan kò ní dúnní mọ́ mímáa ṣe àlùwàlá àyàfi olùgbàgbọ́ òdodo”. Aḥmad gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (22434), Ibn Mājah gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (277), Ad-Dārimī gbà á wá (655), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 1/225).