Nínú Sunnah ni kí á pa yíyán mọ́, tàbí kí á dá padà
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pé ó sọ wí pé: “Dájúdájú Ọlọ́hun fẹ́ràn sísín, Ó sì kórìíra yíyán. Nítorí náà nígbà tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá sín, tí ó sì ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun, iwọ̀ ló jẹ́ lórí gbogbo Mùsùlùmí tí ó bá gbọ́ ọ, kí ó kí i. Ṣùgbọ́n yíyán dájúdájú láti ọ̀dọ̀ èṣù ni ó ti máa ń wá, nítorí náà kí ó dá a padà bí ó bá ti lágbara mọ. Nígbà tí ó bá ṣe háà, èṣù yóò máa fi rín ẹ̀rín”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2663).
Ó wà ní ọ̀dọ̀ Muslim, nínú Ḥadīth tí Abū Sa‘īd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá ń yán, kí ó fi ọwọ́ rẹ̀ bo ẹnú rẹ̀, nítorí èṣù yóò gba ibẹ̀ wọlé”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2995). Nítorí náà pípa yíyán mọ́ yóò wáyé, bóyá pẹ̀lú bíbò ó láti ìpasẹ̀ lílo ẹnu, èyí yóò wáyé pẹ̀lú kíkọ̀ fún un láti ṣí sílẹ̀, tàbí pẹ̀lú fífi àwọn ẹyín tẹ ètè mọ́lẹ̀, tàbí pẹ̀lú gbígbé ọwọ́ lé ẹnu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Bákan náà ohun tó lọ́lá jùlọ fún ẹni tó ń yán ni kí ó má gbé ohùn rẹ̀ sókè pẹ̀lú yíyán
– Bákan náà ohun tó lọ́lá jùlọ fún ẹni tó ń yán ni kí ó má gbé ohùn rẹ̀ sókè pẹ̀lú yíyán, bíi kí ó máa sọ pé: (Háà) tàbí (áhà) àti ohun tó jọ èyí nínú àwọn ohùn tí ó máa ń mú jáde, nítorí pé dájúdájú èyí yóò fa kí èṣù máa fi í rín ẹ̀rín.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pé ó sọ wí pé: “Mímáa yán láti ọ̀dọ̀ èṣù ni ó ti máa ń wá, nítorí náà tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá ń yán, kí ó dá a padà bí ó bá ti lágbara mọ. Nígbà tí ó bá ṣe háà, èṣù yóò máa fi í rín ẹ̀rín”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3298), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2994).
Àkíyèsí pàtàkì
Apákan nínú àwọn èèyàn ti bá mímáa wá ìṣọ́ra kúrò lọ́dọ̀ èṣù lẹ́yìn yíyán sáábà. Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí kankan fún èyí, kódà ó jẹ́ ohun tó yapa ìlànà Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, nítorí pé dájúdájú ó ti ṣe ìrántí Ọlọ́hun tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – kò sọ ní irú ààyè yìí.
Kàn sí wa
Sí wa
Yóò dùn mọ́wa kí á rí àwọn ìpè rẹ àti àwọn ìbéèrè rẹ ní ìgbà kíìbà