brightness_1
Kín ni màá sọ níbi àdúà mi?
Àǹfààní kan: Ẹlòmíràn le béèrè pé: Kín ni màá sọ níbi àdúà mi?
Èsì rẹ̀ ni pé: Tọrọ ohun tí ó bá fẹ́ nínú àwọn nǹkan ayé àti Ọ̀run, sì ṣe ojú kòkòrò láti máa lo àwọn gbólóhùn kékeré, tó kó ìtumọ̀ tó pọ̀ sínú, níbi àdúà rẹ. Èyí ni àwọn àdúà tó wá nínú Tírà Ọlọ́hun àti Sunnah Ànábì. Ìbéèrè nípa oore ayé àti ti Ọ̀run wà níbẹ̀. Tún ronú sí ìbéèrè tí ń bọ̀ yìí, nígbà tí wọ́n ṣẹ́rí rẹ̀ sí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, tí ó sì dáhùn pẹ̀lú àwọn gbólóhùn tó tóbi, èyí tí ó kó oore ayé àti Ọ̀run sínú fún Mùsùlùmí. Irú ìró ìdùnnú wo ni ó tún wá tó èyí, ẹ̀bún wo ni ó tún tóbi jù ú lọ! Nítorí náà dírọ̀ mọ́ wọn, kí ó sì ronú sí wọn.
Abū Mālik Al-’Ashja‘ī gbà á wá láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – pé: Dájúdájú òun gbọ́ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, nígbà tí ọkùnrin kan wá bá a, tí ó sí sọ pé: Ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun! Báwo ni máa ti máa sọ, nígbà tí mo bá ń tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba mi? Ó dáhùn pé: “Máa sọ wí pé: “Allāhummaghfir lī, warḥamnī, wa‘āfinī, warzuqnī (Ìrẹ Ọlọ́hun! Forí jìn mí, kẹ́ mi, wò mí sàn, sì pèsè fún mi)”. Yóò kò àwọn ọmọ ìka ọwọ́ rẹ̀ jọ àyàfi àtàǹpàkò, “dájúdájú èyí yóò kó oore ayé rẹ àti Ọ̀run rẹ jọ papọ̀ fún ọ”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2697).
Nínú ẹ̀gbàwá mìíràn tó gbà wá: Tí ẹnì kan bá gba ẹ̀sìn Islām, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – yóò kọ́ ọ ní ìrun kíkí, lẹ́yìn náà yóò pa á láṣẹ pé kí ó máa bẹ Ọlọ́hun pẹ̀lú àwọn gbólóhùn yìí: “Allāhummaghfir lī, warḥamnī, wahdinī, wa‘āfinī, warzuqnī (Ìrẹ Ọlọ́hun! Forí jìn mí, kẹ́ mi, fi mí mọ̀nà, wò mí sàn, sì pèsè fún mi)”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2697).