languageIcon
search
search
beforeFajronColorIcon Àwọn Sunnah tí kò ní àsìkò/ Àwọn Sunnah tó wà fún sísín / ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 2 Àwọn Sunnah )
brightness_1 Wọ́n ṣe é ní Sunnah fún ẹni tó bá sín kí ó sọ pé: “Al-ḥamdu lillāh”

Wọ́n ṣe é ní Sunnah fún ẹni tó bá sín kí ó sọ pé: “Al-ḥamdu lillāh (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe)”.

Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, láti  ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ó sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá sín, kí ó sọ pé: Al-ḥamdu lillāh (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe).  Kí ọmọ-ìyá rẹ̀ tàbí ẹni tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ sì sọ fún un pé: Yarḥamukallāh (Ọlọ́hun yóò kẹ́ ọ). ó bá sọ fún un pé: Yarḥamukallāh (Ọlọ́hun yóò kẹ́ ọ), kí ó dáhùn pé: Yahdīkumullāhu wayuṣliḥu bālakum (Ọlọ́hun yóò fi yín mọ̀nà, yóò sì tún ìṣesí yín ṣe)”. Al-Bukhārī  gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6224).

Wọ́n tún ṣe ní Sunnah kí ó máa ṣe àdúà yìí lóníran-ǹran, bíi kí ó sọ nígbà mìíràn pé: Al-ḥamdu lillāh ‘alā kulli ḥāl (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe lórí gbogbo ìṣesí mi)”. Nítorí pé dájúdájú ó wá nínú nínú ẹ̀gbàwá tí Abū Dāwūd gbà á wá pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá sín, kí ó sọ pé: Al-ḥamdu lillāh ‘alā kulli ḥāl (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe lórí gbogbo ìṣesí mi)”.  Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5031). Ibn Al-Qayyim – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – nínú Zādul-Ma’ād, sọ nípa Ḥadīth yìí pé: “Ojúpọ̀nà tó gbà wá ní àlááfíà”.

Ẹni tó bá fẹ́ kí i yóò sọ fún un pé: Yarḥamukallāh (Ọlọ́hun yóò kẹ́ ọ)”.  Wọ́n sì ṣe é ní Sunnah fún ẹni tó bá sín kí ó dá a lóhùn pé: Yahdīkumullāhu wayuṣliḥu bālakum (Ọlọ́hun yóò fi yín mọ̀nà, yóò sì tún ìṣesí yín ṣe)”. Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, èyí tó ti síwájú, tọ́ka sí gbogbo èyí.

brightness_1 Sunnah nígbà tí ẹni tó sín kò bá yin Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – ni kí á má kí i

Tí kò bá ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun  – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga –, kò sí nínú Sunnah kí á kí i. Kódà Sunnah ni kí á má kí i. Nítorí Ḥadīth tí ’Anas – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: “Ọkùnrin méjì sín ní ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ó sì kí ẹnì kan nínú àwọn méjèèjì, kò sì kí ẹnì kejì. Ni ọkùnrin náà bá sọ wí pé: Ìrẹ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun! O kí eléyìí, o kò sì kí mi. Ó sọ pé: “Dájúdájú eléyìí yin Ọlọ́hun, ìwọ kò yin Ọlọ́hunAl-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6225). Èyí jẹ́ ara ohun tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ṣe. Ó sì tún wá nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ohun tí Muslim gbà wá láti ọ̀dọ̀ Abū Mūsā – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá sín, tí ó si ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun, ẹ kí i. Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun, ẹ kò gbọdọ̀ kí i”  Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2992).

Ṣùgbọ́n tí ààyè náà bá jẹ́ ààyè ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, bíi kí bàbá máa kọ́ ọmọ rẹ̀, tàbí kí olùkọ̀ọ́ máa kọ́ àwọn ọmọ àkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́kọ̀ọ́, tàbí ohun tó jọ èyí, nínú ohun tó máa ń wà ní ààyè ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, dájúdájú yóò sọ fún un pé: Sọ wí pé: “Al-ḥamdu lillāh (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe)”. Nítorí kí ó le rè é lórí Sunnah yìí, nítorí pé dájúdájú ó le jẹ́ aláìmọ̀kan nípa jíjẹ́ Sunnah rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ni tó bá jẹ́ ẹni tí ọ̀fìnkìn ń yọ lẹ́nu, dájúdájú a kò ní kí i lẹ́yìn ẹlẹ́ẹ̀kẹta. Ṣùgbọ́n tó bá sín ní ẹ̀ẹ̀mẹta, a ó kí i, lẹ́yìn rẹ̀, a ò ní kí i mọ́.

Ẹ̀rí rẹ̀ ni : Ohun tí Abū Dāwūd gbà wá nínú Sunan rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, tí ó dá a dúró sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nígbà kan, tí ó sì fi tì sí Ànábí nígbà mìíràn, ó sọ wí pé: “Kí ọmọ-ìyá rẹ̀ (nígbà tó bá sín) ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ohun tí ó bá ti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kàtá ni” Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (5034), Al-Albānī – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – sọ wí pé: “Ó jẹ́ ẹ̀gbàwá tó dára, tí ó sì jẹ́  ọ̀rọ̀ sàábé” (Ṣaḥīḥul-Abī Dāwūd 4/308).

Ohun tí yóò tún ràn án lọ́wọ́ ni ohun tí Muslim gbà wá, nínú  Ṣaḥīḥu rẹ̀, nínú Ḥadīth tí Salamah ọmọ Al-’Akwa‘ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; dájúdájú òun gbọ́ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, nígbà tí ọkùnrin kan tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sín, tí ó sì sọ fún un pé: “Yarḥamukallāh (Ọlọ́hun yóò kẹ́ ọ)”. Lẹ́yìn náà ó sín nígbà mìíràn, Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ fún un pé: “Kàtá ń ṣe ọkùnrin yìí”. Muslim  gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2993).

Kókó tí a rí fàyọ nínú ohun tó síwájú ni pé dájúdájú ẹni tó bá sín, a kò ní kí i, nínú ìṣesí méjì:

1. Tí kò bá ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga –.

2. Tí ó bá lékún ju ẹ̀ẹ̀mta lọ; nítorí pé ẹni tí kàtá ń ṣe ni .