brightness_1
Àdúà tí a máa ń ṣe lẹ́yìn àlùwàlá
‘Umar –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i- sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Kò sí ẹnìkankan nínú yín, tí yóò ṣe àlùwàlá, tí yóò sì ṣe àlùwàlá náà dé ògóńgó - tí yóò ṣe é dáadáa-, lẹ́yìn náà tí yóò sọ wí pé: ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illallāh, wa’anna Muḥammadan ‘abduhu warasūluh (Mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kankan tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan, àti pé Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun Muḥammad, níti pàápàá, jẹ́ ẹrúsìn Rẹ̀ àti Ìránṣẹ́ Rẹ̀), àyàfi kí wọ́n ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ọgbà-ìdẹ̀ra Al-Jannah mẹ́jọ̀ọ̀jọ̀ sílẹ̀ fún un, yóò wọlé láti ibi èyí tí ó bá fẹ́ nínú rẹ̀” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (234).
Tàbí: Ohun tí ó wá nínú Ḥadīth tí Abū Sa‘īd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, tí ó ṣe àfitì rẹ̀ sí Ànábì pé: “Ẹni kẹ́ni tí ó bá ṣe àlùwàlá, tí ó parí àlùwàlá rẹ̀, tí ó sì wí pé: Subḥānakallāhumma wabiḥamdika ’ashhadu ’an lā ilāha illā ’Anta astaghfiruka wa’atūbu ’ilayk (Mímọ́ ni fún Ọ, Ìrẹ Ọlọ́hun, mo tún ṣe ọpẹ́ àti ẹyìn fún Ọ; mo jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ìwọ nìkan. Mò ń tọrọ àforíjìn Rẹ̀, mo sì ronúpìwàdà lọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀), Ọlọ́hun yóò fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́ (ṭāba‘u tàbí ṭābi‘u jẹ́ èdè Lárúbáwá méjì tí ó já geere, ohun ni wọ́n tún máa ń pè ní khātim (òǹtẹ̀) nínú èdè Lárúbáwá, ìtumọ̀ ṭaba‘a ni: Ó fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́), lẹ́yìn náà wọ́n yóò gbé e lọ sókè ní abẹ́ Ìtẹ́-Ọlá Ọlọ́hun, wọn kò sì ní kán an títí di ọjọ́ Ìgbéǹde” An-Nasā’ī gbà á wá nínú ‘Amalul-Yawmi wal-Laylah (ojú-ewé147), Al-Ḥākim náà gbà á wá (1/246). Ibn Ḥajar – kí Ọlọ́hun kẹ́ ẹ – ka ojúpọ̀nà tí ó gbà wá sí èyí tí ó ní àlááfíà, wo: Natā’ijul-’Afkār (1/246). Ó tún ṣàlàyé pé kò ní àlááfíà dé ọ̀dọ̀ Ànábì, a jẹ́ wí pé ọ̀rọ̀ sàábé ni. Èyí kò le kó ìpalára bá a, nítorí pé dájúdájú ó ní ìdájọ́ ohun tí wọ́n fi tì sí Ànábì, nítorí pé ara ohun tí a kò le fi làákàyè lásán gbé kalẹ̀ ni.