brightness_1
Kíkí òpó-ìrun méjì síwájú ìrun àṣálẹ́
Nítorí Hadīth tí ‘Abdullāh ọmọ Mughaffal Al-Muzanī – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, láti ọ̀dọ̀ Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, pé ó sọ wí pé: “Ẹ máa kírun síwájú ìrun àṣálẹ́”, ó sọ ní ẹ̀ẹ̀kẹta pé: Fún ẹni tó bá fẹ́, nítorí pé ó kórìíra kí àwọn èèyàn mú un (ní ìlànà tí wọn kò ní fi sílẹ̀)”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1183).
– Bákan náà wọ́n ṣe kíkí òpó-ìrun méjì, láàrin pípe ìrun àti gbígbé ìrun dìde, ní Sunnah
Bóyá òpó-ìrun méjèèjì yìí jẹ́ èyí tí a máa ń kí síwájú tàbí lẹ́yìn ìrun ọ̀ranyàn bíi èyí tí a máa ń kí síwájú ìrun àárọ̀ àti ọ̀sán, dájúdájú ìrun àkígbọrẹ tí a máa ń kí síwájú tàbí lẹ́yìn ìrun, tí ó bá kí i, yóò tó o kúrò níbi òpó-ìrun méjèèjì yìí. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wí pé ó jókòó sí Mọṣáláṣí, lẹ́yìn náà tí apèrun wá pèrun fún ìrun ìrọ̀lẹ̀ tàbí ìrun alẹ́, dájúdájú nínú Sunnah ni kí ó dìde, kí ó sì kí òpó-ìrun méjì.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Hadīth tí ‘Abdullāh ọmọ Mughaffal Al-Muzanī – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, sọ wí pé: “Ìrun ń bẹ láàrin pípe ìrun àti gbígbé ìrun dìde”, ó sọ ọ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sọ níbi ìkẹta pé: “Fún ẹni tó bá fẹ́”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (624), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (838).
Kò sí ìyeméjì níbi pé dájúdájú kíkí òpó-ìrun méjì síwájú ìrun àṣálẹ̀ tàbí láàrin pípe ìrun àti gbígbé ìrun dìde, kì í ṣe ohun tó kanpá bíi kíkanpá àwọn ìrun àkígbọrẹ tí a máa ń kí síwájú tàbí lẹ́yìn ìrun ọ̀ranyàn, ṣùgbọ́n a máa ń pa á tì ní ẹ̀ẹ́kọ̀ọ̀kan. Ìdí níyí, tí Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – fi sọ níbi ẹ̀ẹ̀kẹta pé: “Fún ẹni tó bá fẹ́”, nítorí pé ó kórìíra kí àwọn èèyàn mú un (tí ìlànà tí wọn kò fi sílẹ̀).