1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
brightness_1
أَسْتَغْفِرُ الله، أَسْتَغْفِرُ الله، أَسْتَغْفِرُ الله، اللَّهُمَّ أَنْتَ السَّلاَمُ وَمِنْكَ السَّلاَمُ، تَبَارَكْتَ يا ذَا الْجَلاَلِ وَالإِكْرَامِ
Yóò tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – ní ẹ̀ẹ̀mẹta, lẹ́yìn náà yóò sọ wí pé: “Allāhumma ’Antas-Salām waminkas-salām, tabārakta yā dhal-jalāli wal-’ikrām (Ìrẹ Ọlọ́hun! Ìwọ ni Àlááfíà, ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àlááfíà tí ń wá. Ìrẹ Ọba tí Ó ni títóbi àti àpọ́nlé)” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (591), nínú Ḥadīth tí Thawbān – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá.
لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، لاَ حَوْلَ وَلاَ قُوَّةَ إِلاَّ بِاللّهِ، لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ، وَلاَ نَعْبُدُ إِلاَّ إِيَّاهُ، لَهُ النِّعْمَةُ وَلَهُ الْفَضْلُ، وَلَهُ الثَّنَاءُ الْحَسَنُ، لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ، وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ
“Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr. Lā ḥawla walā quwwata ’illa billāh, lā ’ilāha ’illallāh, walā na‘budu ’illā ’iyyah, lahun-ni‘matu walahul-faḍl walahuth-thanā’ul-ḥasan, lā ’ilāha ’illallāh, mukhliṣīna lahud-dīna walaw karihal-kāfirūn (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan. Kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun. Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo. A kò ní jọ́sìn àyàfi fún Òun nìkan. Ti Ẹ̀ ni ìdẹ̀ra, ti Ẹ̀ sì ni ọlá àti pé ti Ẹ̀ ni ẹyìn dáadáa í ṣe. Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan. À ń ṣe àfọ̀mọ́ ìjọsìn fún Un, kódà kí àwọn aláìgbàgbọ́ kórìíra)”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (596).
لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، اللَّهُمَّ لاَ مَانِعَ لِمَا أَعْطَيْتَ، وَلاَ مُعْطِيَ لِمَا مَنَعْتَ، وَلاَ يَنْفَعُ ذَا الْجَدِّ مِنْكَ الْجَدُّ
“Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr. Allāhumma lā māni‘a limā ’a‘ṭayt, walā mu‘ṭiya limā mana‘t, walā yanfa‘u dhal-jaddi minkal-jadd (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni Ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan. Ìrẹ Ọlọ́hun! Kò sí ẹni tó le kọ ohun tí O bá fúnni, kò sì sí ẹni tí ó le fúnni ní ohun tí O bá kọ̀, àti pé ọrọ̀ ọlọ́rọ̀ kò le ṣe é ní àǹfààní ní ọ̀dọ̀ Rẹ)” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (844), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (593).
100 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà
سبحان الله (33)، الحمد لله (33)، الله أكبر (33)، لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Àkọ́kọ́: [Subḥānallāh: (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun) 33, àti Al-ḥamdu lillāh: (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí Ọlọ́hun ní í ṣe) 33, àti Allāhu ’Akbar: (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ) 33. Yóò sì pé ọgọ́rùn-ún pẹ̀lú kí ó wí pé: Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu...: (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo)...].
Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tó bá ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun, lẹ́yìn gbogbo ìrun, nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, tí ó ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, tí ó gbé Ọlọ́hun tóbi nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ìyẹn jẹ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún, tí ó sí pé ọgọ́rùn-ún pẹ̀lú: Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni Ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan), wọn yóò forí àwọn àṣìṣe rẹ̀ jìn ín, kódà kó tó ìfòfó orí òkun” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (597).
سبحان الله (33)، الحمد لله (33)، الله أكبر (34) م
Ìkejì : [Subḥānallāh: (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun) nígbà 33, àti Al-ḥamdu lillāh: (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí Ọlọ́hun ní í ṣe) nígbà 33, àti Allāhu ’Akbar: (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ) nígbà 34]. Nítorí Ḥadīth tí Ka‘b ọmọ ‘Ujrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Àwọn ìrántí Ọlọ́hun kan ń bẹ tó máa ń tẹ̀lé ìrun, ẹni tó bá sọ wọn tàbí ó ṣe wọn lẹ́yìn ìrun ọ̀ranyàn kò le pòfo:
Ṣíṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun, nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ṣíṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, àti gbígbé Ọlọ́hun tóbi nígbà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (596).
سبحان الله (25)، الحمد لله (25)، الله أكبر، لا إله إلا الله (25) م
Ìkẹta: [Subḥānallāh: (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun) nígbà 25, àti Al-ḥamdu lillāh: (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí Ọlọ́hun ní í ṣe) nígbà 25, àti Allāhu ’Akbar: (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ) nígbà 25, lā ’ilāha ’illallāhu (kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo) nígbà 25].
Ẹ̀rọ-ọ̀rọ̀ yìí wá lọ́dọ̀ At-Tirmidhī, nínú Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ Zayd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá. At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3413), Al-Albānī sì kà á sí ẹ̀gbàwá tó ní àlááfíà (Taḥqīqu Mishkātil-Maṣābīḥ 1/307).
سبحان الله (10)، الحمد الله (10)، الله أكبر (10) م
Ìkẹrin: [Subḥānallāh: (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun) nígbà 10, àti Al-ḥamdu lillāh: (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí Ọlọ́hun ní í ṣe) nígbà 10, àti Allāhu ’Akbar: (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ) nígbà 10].
Ẹ̀rọ-ọ̀rọ̀ yìí wá lọ́dọ̀ At-Tirmidhī, nínú Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá. At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3410), Al-Albānī sì kà á sí ẹ̀gbàwá tó ní àlááfíà (Taḥqīqu Mishkātil-Maṣābīḥ 2/743).
Òfin ìmọ̀ ẹ̀sìn ti síwájú nípa àwọn ìjọsìn tó bá gba oríṣríṣi ọ̀nà wá pé; a ó ṣe èyí nígbà kan, a ó sì ṣe ìyẹn nígbà mìíràn.
Sunnah ni kí á máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ wa. Nítorí ohun tí Aḥmad àti At-Tirmidhī gbà wá, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹ máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun, ẹ sì máa kà á pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ yín, nítorí pé dájúdájú wọn yóò bi wọ́n léèrè, wọ́n yóò sì pa wọ́n láṣẹ̀ kí wọn sọ̀rọ̀” Aḥmad gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (27089), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3486), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tó dára nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 2/753).
اللَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ
Nítorí Ḥadīth tí Abū ’Umāmah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ pé: Dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni tó bá ké ’Āyatul-Kursiyy lẹ́yìn gbogbo ìrun ọ̀ranyàn, nǹkankan kò ní kọ̀ fún láti wọ ọgbà-ìdẹ̀ra àyàfi ikú” An-Nasā’ī gbà á wá nínú As-Sunanul-Kubrā pẹ̀lú òǹkà (9928), Al-Mundhirī kà á sí ẹ̀gbàwá tí ó ní àlááfíà nínú tírà rẹ̀: At-Tarqību wat-Tarhīb pẹ̀lú òǹkà (2373), àti Ibn ‘Abdil-Hādī (Al-Muḥarrar 1/198), àti Ibnul-Qayyim (Zādul-Ma‘ād 1/303).
Nítorí Ḥadīth tí ‘Uqbah ọmọ ‘Āmir – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – pa mí láṣẹ kí ń máa ké àwọn Sūrah tí a fi máa ń wá ìṣọ́ra lẹ́yìn gbogbo ìrun” Abū Dāwūd gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (1525), Al-Albānī sọ wí pé: “Mo sọ wí pé: Ojúpọ̀nà tó gbà wá ní àlááfíà”. Ibn Khuzaymah àti Ibn Ḥibbān kà á sí ẹ̀gbàwá tó ní àlááfíà (Ṣaḥīḥu Abī Dāwūd, 5/254).
Èyí jẹ́ ọ̀wọ́ kan nínú àwọn Sunnah ìrun, èyí tí a fẹ́ kí akírun mú wá, a ò sì tí ì kúrò lórí àsìkò tí àfẹ̀rẹ̀mọ́júmọ́ ti yọ, ṣùgbọ́n a mẹ́nu ba àwọn ohun tó síwájú nítorí pé a bùkáátà sí mímáa rántí rẹ̀ ní gbogbo ààyè lórí ìrun – Ọlọ́hun ní Ó mọ̀ jùlọ – .