Nítorí Hadīth tí Abū Barzah Al-’Aslamī – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i –, èyí tí ó ti síwájú, ó wà nínú rẹ̀ pé: “Ó sì máa ń kórìíra sísùn síwájú rẹ̀, àti ọ̀rọ̀ sísọ lẹ́yìn rẹ̀”. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ wí pé ọ̀rọ̀ tó bùkáátà sí ni ó ń sọ, kò sí ìkórííra kankan níbẹ̀.
Ohun tó fa kíkórìíra rẹ̀ – Ọlọ́hun ni Ó mọ̀ jùlọ – : Ni pé dájúdájú sísùn yóò máa pẹ́, nítorí náa à ń páyà kí ìrun àárọ̀ bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́ kúrò ní àsìkò rẹ̀, tàbí kúrò ní àkọ́kọ́ àsìkò rẹ̀, tàbí kí dídìde kírun lóru bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́, fún ẹni tó bá ti bá kíkí i sáábà.
Ohun tó lọ́lá jùlọ, níbi ìrun alẹ́, ni kí á lọ ọ́ lára, ní òpin ìgbà tí kò bá ti sí ìnira kankan níbẹ̀ fún àwọn tí yóò kírun lẹ́yìn Imām.
Ẹ̀rí rẹ̀ ni :
Ḥadīth tí ‘Ā’ishah –kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Alẹ́ lẹ́ bá Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ní òru ọjọ́ kan, títí tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òru fi rékọjá, títí tí àwọn tó wà ní Mọṣáláṣí fi sùn lọ, lẹ́yìn náà ó jade, ó kírun, ó sì sọ pé: “Dájúdájú èyí gan-an ni àsìkò rẹ̀, tí kì í bá ṣe wí pé nítorí kí n má kó ìnira bá ìjọ mi” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (638).
Fún ìdí èyí, Sunnah ni fún obìnrin, nígbà tó jẹ́ wí pé ìrun rẹ̀ kò so mọ́ ìrun àkójọpọ̀ àwọn Mùsùlùmí ní Mọṣáláṣí, kí ó lọ́ ìrun alẹ́ lára, ní òpin ìgbà tí kò bá ti sí ìnira kankan níbẹ̀ fún un. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọkùnrin, nígbà tí ìrun rẹ̀ kò bá so mọ́ ìrun àkójọpọ̀ àwọn Mùsùlùmí, bíi kí ó wà lórí ìrìn-àjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.