Nínú àwọn Sunnah tí á máa ń ṣe ní ojoojúmọ́ ni mímá rántí Ọlọ́hun, Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga.
Èyí tó tóbi jùlọ nínú rẹ̀ ni: Mímáa ké Tírà Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – . Mímáa fi kíké e ṣe ìjọsìn fún Ọlọ́hun, dá oorun mọ́ àwọn asiwájú rere lójú, ó sì gbé wọn jìnnà sí oorun {Wọ́n jẹ́ ẹni tó máa ń sùn díẹ̀ ní òru. Àti pé ní àwọn ìdájí, wọ́n máa ń tọrọ́ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun} (Adh-Dhāriyāt: 17-18).
Nítorí náà, ní òru wọn, wọ́n kó kíké Tírà Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – àti kíka àwọn ìrántí tí wọ́n gbà wá láti ọ̀dọ̀ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – papọ̀. Tí Ọlọ́hun ni, dáadáa òru tí àwọn tó jí nínú rẹ̀ jẹ́ ẹni dáadáa, nítorí jíjí ṣe ìjọsìn fún Ọlọ́hun nínú rẹ̀. Ẹ wo àdánù wa, àìní àkàkún wa àti àṣeètó wa pẹ̀lú òru wa àti ìdájí wa! Ó ṣeé ṣe kí ó là níbi ṣíṣẹ Ọlọ́hun wa, àyàfi ẹni tí Ọlọ́hun Ọba wa – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – bá kẹ́.
Ḥammād ọmọ Zayd gbà á wá: Láti ọ̀dọ̀ ‘Aṭā’u ọmọ As-Sā’ib, pé dájúdájú Abū ‘Abdir-Raḥmān sọ pé: “A kọ́ Al-Qur’ān ní ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn kan tí wọ́n fún wa ní ìró pé dájúdájú tí àwọn bá kọ́ ’āyah mẹ́wàá, wọn kò ní kọ́ mẹ́wàá mìíràn lẹ́yìn rẹ̀ títí wọn yóò fi kọ́ ohun tí wọ́n kó sínú, níorí náà a máa ń kọ́ Al-Qur’ān àti lílò rẹ̀ papọ̀. Àwọn èèyàn kan yóò padà jogún Al-Qur’ān lẹ́yìn wa, wọn yóò máa mu ún bíi mímu omi, kò ní kọjá ọ̀fun wọn”. Wo: Siyaru ’A‘lāmin-Nubalā’ (4/269).
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa, pàápàá jùlọ ní àwọn àsìkò tí a wà yìí, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìrójú, ni ó ń ráhùn nípa dídógùn-ún ọkàn rẹ̀ àti àìní àkàkún rẹ̀. Ìṣẹ̀mí ọkàn sì máa ń wáyé pẹ̀lú ìrántí Ọlọ́hun. Ó wá nínú Ṣaḥīḥul-Bukhārī, nínú Ḥadīth tí Abū Mūsā – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Àpèjúwe ẹni tí ó máa ń rántí Ọlọ́hun Ọba rẹ̀ àti ẹni tí kì í rántí Ọlọ́hun Ọba rẹ̀ dà bíi àpèjúwe alààyè àti òkú”. Nínú gbólóhùn mìíràn tí Muslim gbà wá, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Àpèjúwe ilé tí wọ́n máa ń rántí Ọlọ́hun níbẹ̀ àti èyí tí wọn kì í rántí Ọlọ́hun níbẹ̀ dà bíi àpèjúwe alààyè àti òkú”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6407), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (779).
Ọlọ́hun – Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n – gbà wá níyànjú lórí mímáa rántí Rẹ̀ ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan àwọn ààyè, nínú rẹ̀ ni:
1/ Ọlọ́hun – Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n – gbà àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa rántí Rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – sọ wí pé: {Ẹ̀yin ẹni tó gbàgbọ́ lódodo! Ẹ rántí Ọlọ́hun ní ìrántí tí ó pọ̀. Àti pé ẹ ṣe àfọ̀mọ́ fún Un ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́} (Al-’Aḥzāb: 41-42).
2/ Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – tún ṣe àdéhùn fún àwọn tó máa ń rántí Rẹ̀, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, pẹ̀lú àforíjìn àti ẹ̀san rere àti láádá tó tóbi. Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – sọ wí pé: “Àti àwọn tó máa ń rántí Ọlọ́hun lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, Ọlọ́hun ti pèsè àforíjìn sílẹ̀ fún wọn àti ẹ̀san rere tí ó tóbi” (Al-’Aḥzāb: 35).
3/ Ọlọ́hun – Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n – kìlọ̀ fún wa nípa ìwà àwọn alágàbàgebè, àwọn náà máa ń rántí Ọlọ́hun – Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n –. Ṣùgbọ́n ìwọ náà ronú sí bí wọ́n ti máa ń rántí Ọlọ́hun mọ. Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – sọ wí pé: “Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹṣèlu ń tan Ọlọ́hun jẹ, Òun gan-an náà sì ń tàn wọ́n jẹ, àti pé nígbà tí wọ́n bá dìde láti lọ sibi ìrun, wọn yóò dìde ni òròjú, wọn yóò máa ṣe káríni sí àwọn ènìyàn, wọn kò sì ní rántí Ọlọ́hun àyàfi díẹ̀”. (An-Nisā’: 142).
Ọlọ́hun – Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n – kìlọ̀ fún wa nípa níní àìrójú pẹ̀lú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ kúrò níbi mímáa rántí Rẹ̀ – Ọba Abiyì, tí Ó gbọn-n-gbọ́n –. Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – sọ wí pé: “Ẹ̀yin ẹni tó gbàgbọ́ lódodo! Ẹ má ṣe jẹ kí àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín kó àìrójú ba yín kúrò níbi Ìrántí Ọlọ́hun. Àti pé ẹni kẹ́ni tó ba ṣe ìyẹn, nígbà náà àwọn wọ̀nyẹn ni ẹni òfò”. (Al-Munāfiqūn: 9).
5/ Tún ronú, pẹ̀lú mi, sí ọlá tí ó tóbi yìí àti iyì tó ga yìí, Ọlọ́hun – Ọba tí Ọlá Rẹ̀ ga – sọ wí pé: { Fún ìdí èyí ẹ rántí Mi, Èmi náà yóò rántí yín}. Ó tún sọ nínú Al-Ḥadīthil-Qudusī (ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun tí ó yàtọ̀ sí Al-Qur’ān) pé: “Èmi ń bẹ pẹ̀lú ẹrúsìn Mi nígbà tí ó bá ronú kàn Mi, àti pé Èmi ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tí ó bá rántí Mi. Nítorí náà, tí ó bá rántí Mi nínú ẹ̀mí rẹ̀, máa rántí rẹ̀ nínú ẹ̀mí Mi; tí ó bá sì rántí Mi láàrin àwọn ìjọ kan, máa rántí rẹ̀ nínú ìjọ kan tí ó lóore jù wọ́n lọ”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (7405), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2675), nínú Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá.
Nínú ohun tó wá nínú Sunnah Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ni àwọn ìran ìrántí Ọlọ́hun tó pọ̀, nínú rẹ̀ ni ohun tó ń bọ̀ yìí:
1. Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà á wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ pé: “Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan)”, ní ìgbà ọgọ́rùn-ún, ní ọjọ́ kan, ẹ̀san dáadáa tí yóò gbà yóò ṣe déédé ẹ̀san dáadáa ẹni tó bọ́kùn ẹrú mẹ́wàá, wọn yóò kọ ọgọ́rùn-ún dáadáa sílẹ̀ fún un, wọn yóò pa ọgọ́rùn-ún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ fún un. Yóò tún jẹ́ ìṣọ́ fún un lọ́wọ́ èṣù ní ọjọ́ rẹ̀ náà títí tí yóò fi di ìrọ̀lẹ́, ẹnì kankan kò sì ní ṣe ohun tó lọ́lá ju ohun tó ṣe lọ, àyàfi ẹni tó ṣe ohun tó ju èyí lọ. Ẹni kẹ́ni tí ó bá sì sọ pé: Subḥānallāhi wabiḥamdih (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun, kí gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn sì máa jẹ́ ti Ẹ̀), ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ní ojúmọ́, wọn yóò pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ rẹ́, kódà kí ó tó ìfòfó òkun” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3293), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2691).
2. Abū ’Ayyūb – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà á wá pé; Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ pé: “Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan)”, ní ẹ̀ẹ̀mẹwàá, ẹ̀san dáadáa tí yóò gbà yóò dà bíi ẹ̀san dáadáa ẹni tó bọ́kùn ẹrú mẹ́rin nínú àwọn ọmọ Ànábì Ismā‘īl (nínú àwọn ọmọ Lárúbáwá)”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6404), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2693).
Nínú ohun tó wá nínú Sunnah Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ni àwọn ìran ìrántí Ọlọ́hun tó pọ̀, nínú rẹ̀ ni ohun tó ń bọ̀ yìí:
3. Sa‘d ọmọ Abī Waqqāṣ – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: A wà ní ọ̀dọ̀ Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –, ni ó bá sọ wí pé: “Ṣé ẹnì kan nínú yín yóò kágara láti máa ṣe ẹgbẹ̀rún dáadáa ní ojoojúmọ́ bí?” Ni oníbéèrè kan nínú àwọn tó jókòó pẹ̀lú rẹ̀ bá sọ wí pé: Báwo ni ẹnì kan nínú wa yóò ṣe ṣe ẹgbẹ̀rún dáadáa? Ó dáhùn pé: “Yóò ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun ní ìgbà ọgọ́rùn-ún kan, wọn yóò sì kọ ẹgbẹ̀rún kan dáadáa sílẹ̀ fún tàbí kí wọ́n pa ẹgbẹ̀rún kan ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ fún un”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2698).
4. Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà á wá pé; dájúdájú Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tí ó bá sọ pé: Subḥānallāhi wabiḥamdih (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun, kí gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn sì máa jẹ́ ti Ẹ̀), ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ní ojúmọ́, wọn yóò pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ rẹ́, kódà kí ó tó ìfòfó òkun” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6405), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2692). “Ẹni kẹ́ni tí ó bá sì sọ, nígbà tó bá jí ní àárọ̀, àti nígbà tó bá di ìrọ̀lẹ́, pé: Subḥānallāhi wabiḥamdih (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun, kí gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn sì máa jẹ́ ti Ẹ̀), ní ìgbà ọgọ́rùn-ún, ẹnì kankan kò ní wá ní ọjọ́ Ìgbéǹde pẹ̀lú ohun tó lọ́lá ju ohun tó ṣe lọ, àyàfi ẹni tó bá ṣọ irú ohun tó sọ tàbí ó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2692).
Àwọn Ḥadīth tó wá nípa àwọn ìran ìrántí Ọlọ́hun àti ọlá rẹ̀ pọ̀. Èyí tó síwájú yìí jẹ́ ara ohun tó gbajúmọ̀ jùlọ, tó sì ní àlááfíà jùlọ nínú àwọn ìrántí Ọlọ́hun tó wá, tó sì lọ́lá. Àwọn mìíràn tó pọ̀ náà tún wá. Abū Mūsā Al-’Ash‘arī – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ fún mi pé: “Ṣé kí ń tọ́ka rẹ sí ọ̀kan nínú àwọn pẹpẹ ọrọ̀ Àlùjánńnà? Mo dáhùn pé: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ wí pé: Lā ḥawla walā quwwata illā billāh (kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun)”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (4202), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2704).
Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú kí ń máa sọ wí pé: Subḥānallāh, wal-ḥamdu lillāh, walā ’ilāha ’illallāhu wallāhu ’Akbar (Mímọ́ fún Ọlọ́hun, gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe. Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh. Ọlọ́hun ni Ó tóbi júlọ), wù mí ju gbogbo ohun tí òòrùn yọ lé lórí lọ”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2695).
Nínú ohun tó wá nínú Sunnah Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ni àwọn ìran ìrántí Ọlọ́hun tó pọ̀, nínú rẹ̀ ni ohun tó ń bọ̀ yìí:
Mímáa tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun bákan náà jẹ́ ara àwọn ìran ìrántí Ọlọ́hun. Al-’Agharr Al-Muzanī – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Dájúdájú ìgbàgbé a máa bá mi, ṣùgbọ́n dájúdájú mo máa ń tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun, ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ní ojúmọ́”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2702).
Èyí jẹ́ ara ìṣe rẹ̀ – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –. Dájúdájú ó gbà wá níyànjú nípa mímáa tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Ṣaḥīḥu Muslim, láti ọ̀dọ̀ Al-’Agharr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – bákan náà. Ó sọ wí pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ ronú pìwàdà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, dájúdájú èmí máa ń ronú pìwàdà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́hun, ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ní ojúmọ́”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2702).
Ó wà ní ọ̀dọ̀ Al-Bukhārī, nínú Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Mo gbọ́ tí Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – ń sọ wí pé: “Mo fi Ọlọ́hun búra, dájúdájú èmí máa ń tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun, mo sì máa ń ronú pìwàdà lọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ní ojúmọ́, ní ìgbà tó lé ní àádọ́rin”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6307). Fún ìdí èyí, ó pàtàkì fún ẹrúsìn Ọlọ́hun kí ó má gbàgbéra nípa mímáa tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun.
Máà parí Sunnah tó wà fún ìrántí Ọlọ́hun – bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn Sunnah tí á máa ń ṣe ní ojoojúmọ́ – pẹ̀lú ìrántí Ọlọ́hun tó tóbi, èyí tó wá nínú Ṣaḥīḥu méjèèjì. Èyí ni Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Gbólóhùn méjì tó fúyẹ́ lórí ahọ́n, tó wúwo lórí òsùnwọ̀, tí Ọlọ́hun, Ọba Àjọkẹ́ ayé sì fẹ́ràn méjèèjì ni: Subḥānallāhi wabiḥamdih (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun, kí gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn sì máa jẹ́ ti Ẹ̀), Subḥānallāhil-‘Aẓīm” Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (6406), Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2694).
Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn ti Ọlọ́hun ni í ṣe, Ẹni tó jẹ́ wí pé pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ̀ ni gbogbo dáadáa fi máa ń pé