languageIcon
search
search
beforeFajronColorIcon Àwọn Sunnah tí kò ní àsìkò/ Àwọn Sunnah tó wà fún yíyán/ ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 3 Àwọn Sunnah )
brightness_1 Nínú Sunnah ni kí á pa yíyán mọ́, tàbí kí á dá padà

Ẹ̀rí rẹ̀ ni :

Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, láti ọ̀dọ̀ Ànábì  – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –  pé ó sọ wí pé:  “Dájúdájú Ọlọ́hun  fẹ́ràn sísín, Ó sì kórìíra yíyán. Nítorí náà nígbà tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá sín, tí ó sì ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun, iwọ̀ ló jẹ́ lórí gbogbo Mùsùlùmí tí ó bá gbọ́ ọ, kí ó kí i. Ṣùgbọ́n yíyán dájúdájú láti ọ̀dọ̀ èṣù ni ó ti máa ń wá, nítorí náà kí ó dá a padà bí ó bá ti lágbara mọ. Nígbà tí ó bá ṣe háà, èṣù yóò máa fi rín ẹ̀rín”. Al-Bukhārī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2663).

Ó wà ní ọ̀dọ̀ Muslim, nínú Ḥadīth tí Abū Sa‘īd – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá pé; Ànábì  – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a –  sọ wí pé: “Tí ẹni kẹ́ni nínú yín bá ń yán, kí ó fi ọwọ́ rẹ̀ bo ẹnú rẹ̀, nítorí èṣù yóò gba ibẹ̀ wọlé”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (2995). Nítorí náà pípa yíyán mọ́ yóò wáyé, bóyá pẹ̀lú bíbò ó láti ìpasẹ̀ lílo ẹnu, èyí yóò wáyé pẹ̀lú kíkọ̀ fún un láti ṣí sílẹ̀, tàbí pẹ̀lú fífi àwọn ẹyín tẹ ètè mọ́lẹ̀, tàbí pẹ̀lú gbígbé ọwọ́ lé ẹnu àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.