languageIcon
search
search
beforeFajronColorIcon Àwọn Sunnah tí kò ní àsìkò/ Àwọn Sunnah orí ìrun ( Iye òǹkà òpó-ìrun (rak‘ah) rẹ̀ 8 Àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ )

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، لاَ حَوْلَ وَلاَ قُوَّةَ إِلاَّ بِاللّهِ، لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ، وَلاَ نَعْبُدُ إِلاَّ إِيَّاهُ، لَهُ النِّعْمَةُ وَلَهُ الْفَضْلُ، وَلَهُ الثَّنَاءُ الْحَسَنُ، لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ، وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ

Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr. Lā ḥawla walā quwwata ’illa billāh, lā ’ilāha ’illallāh, walā na‘budu ’illā ’iyyah, lahun-ni‘matu walahul-faḍl walahuth-thanā’ul-ḥasan, lā ’ilāha ’illallāh, mukhliṣīna lahud-dīna walaw karihal-kāfirūn (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan. Kò sí ọgbọ́n kankan, kò sì sí agbára kankan àyàfi pẹ̀lú Ọlọ́hun. Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo. A kò ní jọ́sìn àyàfi fún Òun nìkan. Ti Ẹ̀ ni ìdẹ̀ra, ti Ẹ̀ sì ni ọlá àti pé ti Ẹ̀ ni ẹyìn dáadáa í ṣe.  Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan. À ń ṣe àfọ̀mọ́ ìjọsìn fún Un, kódà kí àwọn aláìgbàgbọ́ kórìíra)”. Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (596).

.......

100 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

سبحان الله (33)، الحمد لله (33)، الله أكبر (33)، لاَ إِلهَ إِلاَّ اللّهُ وَحْدَهُ لاَ شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ

Àkọ́kọ́: [Subḥānallāh: (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun) 33, àti Al-ḥamdu lillāh: (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí  Ọlọ́hun  ní í ṣe) 33, àti Allāhu ’Akbar:  (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ) 33. Yóò sì pé ọgọ́rùn-ún pẹ̀lú kí ó wí pé: Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu...:  (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo)...].

Nítorí Ḥadīth tí Abū Hurayrah – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i – gbà wá, ó sọ wí pé: Ìránṣẹ́ Ọlọ́hun – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹni kẹ́ni tó bá ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun, lẹ́yìn gbogbo ìrun, nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, tí ó ṣe ẹyìn fún Ọlọ́hun nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, tí ó gbé Ọlọ́hun tóbi nígbà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ìyẹn jẹ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún, tí ó sí pé ọgọ́rùn-ún pẹ̀lú: Lā ’ilāha ’illallāhu waḥdahu lā sharīka lah, lahul-mulku walahul-ḥamd, wahuwa ‘alā kulli shay’in Qadīr (Kò sí ọlọ́hun kankan tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àyàfi Ọlọ́hun Allāh nìkan ṣoṣo, kò sí orogún fún Un. Ti Ẹ̀ ni Ìjọba, ti Ẹ̀ sì ni gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn í ṣe, àti pé Òun ni Alágbára lórí gbogbo nǹkan), wọn yóò forí àwọn àṣìṣe rẹ̀ jìn ín, kódà kó tó ìfòfó orí òkun” Muslim gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (597).

.......

1 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà

brightness_1

سبحان الله (10)، الحمد الله (10)، الله أكبر (10) م

Ìkẹrin: [Subḥānallāh: (Mímọ́ ni fún Ọlọ́hun) nígbà 10, àti Al-ḥamdu lillāh: (Gbogbo ọpẹ́ àti ẹyìn tí  Ọlọ́hun  ní í ṣe) nígbà 10, àti Allāhu ’Akbar:  (Ọlọ́hun ni Ó tóbi jùlọ) nígbà 10].

Ẹ̀rọ-ọ̀rọ̀ yìí wá lọ́dọ̀ At-Tirmidhī, nínú Ḥadīth tí ‘Abdullāh ọmọ ‘Amr – kí Ọlọ́hun yọ́nú sí àwọn méjèèjì – gbà wá. At-Tirmidhī  gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3410), Al-Albānī sì kà á sí ẹ̀gbàwá tó ní àlááfíà (Taḥqīqu Mishkātil-Maṣābīḥ 2/743).

Òfin ìmọ̀ ẹ̀sìn ti síwájú nípa àwọn ìjọsìn tó bá gba oríṣríṣi ọ̀nà wá pé; a ó ṣe èyí nígbà kan, a ó sì ṣe ìyẹn nígbà mìíràn.

Sunnah ni kí á máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ wa. Nítorí ohun tí Aḥmad àti At-Tirmidhī gbà wá, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọ́hun máa bá a – sọ wí pé: “Ẹ máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọlọ́hun, ẹ sì máa kà á pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ yín, nítorí pé dájúdájú wọn yóò bi wọ́n léèrè, wọ́n yóò sì pa wọ́n láṣẹ̀ kí wọn sọ̀rọ̀” Aḥmad gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (27089), At-Tirmidhī gbà á wá pẹ̀lú òǹkà (3486), Al-Albānī kà á sí ẹ̀gbàwá tó dára nínú (Ṣaḥīḥul-Jāmi‘ 2/753).

.......